Agogo Eewo
Agogo Eewo jẹ́ fíìmù Yorùbá ti ọdún 2002, tó jáde lẹ́yìn Saworoide ti ọdún 1999.[1][2] Akínwùmí Iṣọ̀lá, ló kọ fíìmù yìí, tí olùdarí àti aṣagbátẹrù rẹ̀ jẹ́ Tunde Kelani. Lára àwọn ọ̀ṣèré tó kópa nínú rẹ̀ ni Dejumo Lewis, Deola Faleye, Lere Paimo àti Larinde Akinleye.[3]
Agogo Eewo | |
---|---|
Adarí | Tunde Kelani |
Olùgbékalẹ̀ | Tunde Kelani |
Àwọn òṣèré | Dejumo Lewis Deola Faleye Lere Paimo Larinde Akinleye |
Orin | Biodun Oni |
Ìyàwòrán sinimá | Tunde Kelani |
Olóòtú | Mumin Wale Kelani |
Ilé-iṣẹ́ fíìmù | Mainframe Films and Television Productions |
Àkókò | 106 minutes |
Orílẹ̀-èdè | Nigeria |
Èdè | Yoruba-language |
Àhunpọ̀ ìtàn
àtúnṣeLẹ́yìn ikú Lapite àti Lagata, àwọn olóyè ìlú Jogbo gbìyànjú láti fi Oníjogbo tó jẹ́ ẹni tó wùn wọ́n sórí oyè kí wọ́n ba lè tẹ̀síwájú nínú ìwà kíkó owó ìlú jẹ àti àwọn ìwà àìtọ́. Wọ́n yan ọ̀gá ọlọ́pàá afẹ̀yìntì kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Adebosipo, tí wọ́n rò pé ó máa ṣe tiwọn. Lẹ́yìn tí ó gorí oyè, Adebosipo yí padà sí oníwà rere, ó sì jáwọ́ kúrò nínú kíkó owó ìlú jẹ àti àwọn ìwà ìbàjẹ́. Ó sì ń kéde àlàáfíà àti ìtẹ̀síwájú. Ó rọ àwọn olóyè rẹ̀ láti jáwọ́ kúrò nínú àwọn ìwà búburú yẹn. Balogun, Seriki, Bada àti Iyalaje ò jáwọ́, wọ́n tẹ̀síwájú nínú àwọn ìwà burúkú wọn. Àwọn ọ̀dọ́ ìlú kéde fún ìyọkúrò àwọn olóyè oníwà burúkú. Ọba sì yan àjọ kan tó máa yẹ ìṣe àwọn olóyè náà wò, àti láti ṣàkọsílẹ̀ ètò owó ìṣúná wọn. Wọ́n ní kí àwọn tí ó jẹ̀bi ó dá àwọn owó náà padà. Ọba sì pe olúwo, ìyẹn Amawomárò, tí ó sọ pé kí wọ́n ó búra kí wọ́n ba lè máa ṣe òótọ́. Wọ́n ṣe ayẹyẹ ìbúra ìta gbangba, níbi tí àwọn olóyè náà sì jẹ́wọ́ àṣìṣe tí wọ́n ti ṣe sẹ́yìn kí wọ́n tó búra. Méjì nínú àwọn olóyè yìí kọ̀, ìyẹn Balogun àti Seriki, wọ́n sì kú lójú ẹsẹ̀ nígbà tí wọ́n lu agogo eèwọ̀ ní ẹ̀ẹ̀meje.
Àwọn Akópa
àtúnṣe- Dejumo Lewis bíi Adebosipo
- Kunle Afolayan
- Khabirat Kafidipe
- Deola Faleye
- Lere Paimo
- Larinde Akinleye
Àgbéjáde
àtúnṣeWọ́n to fíìmù yìí pọ̀ mọ́ ọkàn lára àwọn fíìmù Yorùbá mẹ́wàá tó ń tà jù lọ.[4] Wọ́n sì sọ pé kí Nigerian Film and Video Censors Board (NFVCB) má kéde rẹ, torí ìṣe awo, ìwà ipá tó wà nínú rẹ̀.[5]
Wọ́n ṣe lámèyító fíìmù yìí ní African Film ní New York ní oṣù kẹrin ọdún 2004.[3]
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "The Day of TK: Ten of the best Tunde Kelani Movies". Sodas 'N' Popcorn (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2021-02-26. Archived from the original on 2021-09-03. Retrieved 2021-09-03.
- ↑ Adetayo, Waheed Taofeeq (2020-06-16). "ESTABLISHING AND SUSTAINING GOOD GOVERNANCE IN NIGERIA: APPRAISAL OF SAWORO IDE AND AGOGO EEWO FILMS AS CASE STUDY" (in en). Interdisciplinary Journal of African & Asian Studies 4 (1). ISSN 2504-8694. https://www.nigerianjournalsonline.com/index.php/ijaas/article/view/1010.
- ↑ 3.0 3.1 Scheib, Ronnie (2004-04-14). "Agogo Eewo". Variety (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2021-09-05.
- ↑ Ogundipe, Ayodele (2004). Gender and Culture in Indigenous Films in Nigeria. pp. 93–94. Archived from the original on 2022-03-05. https://web.archive.org/web/20220305174322/https://codesria.org/IMG/pdf/GA_Chapter-6_ogundipe.pdf. Retrieved 2021-08-29.
- ↑ Haynes, Jonathan (2007). "TK in NYC: An Interview with Tunde Kelani". Postcolonial Text 3. https://www.postcolonial.org/index.php/pct/article/viewFile/659/409.