Àwọn Amino acid

(Àtúnjúwe láti Amino acids)

Àwọn amino acid jẹ́ àwọn ohun tí ó ní carbon tí ó wúlò fún ara tí ó sì ní amine (-NH2) àti carboxylic acid (-COOH) gẹ́gẹ́ bíi àwọn akójọpọ̀ fún iṣẹ́ ṣiṣe, tí ó sábà maa ń ní ìsomọ́ lẹ́gbẹ́ pàtó fún amino acid kọ̀ọ̀kan.[1][2][3] Àwọn ìdá ìpilẹ̀ amino acid tó ṣe kókọ́ ni carbon, hydrogen, oxygen, àti nitrogen, bípótilẹ̀jẹ́wípé a maa ń rí àwọn ìdá ìpilẹ̀ tókù nínú àwọn  ìsomọ́ lẹ́gbẹ́ àwọn amino acid kọ̀ọ̀kan. Àwọn amino acid tí a mọ̀ fẹ́ẹ tó bíi ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta tí a sì lè pín sí ìsọ̀rí lóríṣiríṣi ọ̀nà.[4] A lè pín wọn gẹ́gẹ́  bi ìrísi àti àyè tí àwọn ẹgbẹ́ oníṣé wọn wà, bíi alpha- (α-), beta- (β-), gamma- (γ-) or delta- (δ-) amino acid; àwọn ẹ̀ka tókù ní lati ṣe pẹ̀lú òpó, ìwọn pH àti oníṣé irú ìsomọ́ ẹ́gbẹ́ (aliphatic, acyclic, aromatic, tí ó ní hydroxyl àti sulfur, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.). Ní bíi protein amino acid jẹ́ ẹ̀yà kejì tí ó tóbi jùlọ nínú iṣan (omi ni o poju) ninu isan, sẹ́ẹ̀lì àti tíṣ́ù.[5] Tí kò bá sí ní protein, ó maa ń ṣe àwọn iṣẹ́ pàtàkì bíi nuerotransmitter àti ìṣẹ̀dá ní ara.

 Ìrísí alpha amino acid ní ìdúrósinsin rẹ̀
Table of Amino Acids.
Àwọn ọ̀kànlélógún proteinogenic α-amino acids tí á ń rí ní eukaryotes, tí a kójọ nípasẹ̀ àkójọpọ̀ ẹ̀gbẹ́ wọn' pKa

biochemistry, àwọn amino acid tí ó ní amine àti àkójọpọ̀  carboxylic acid so mọ́ carbon átọ́mù àkọ́kọ́ (alpha-)  ń ní iṣẹ̀ pàtàkì kan pàtó. A mọ̀ wọ́n sí 2-, alpha-, tàbí α-amino acids (àgbékalè wọn maa ní H2NCHRCOOH,[6]  R jẹ́ àwọn ohun tí ó ní carbon tí ó dìrọ̀ mọ́ọ tí a mọ̀ sí "ìsomọ́-ẹ̀gbẹ́");[7] a sì maa sábà pè wọ́n ní "amino acid". Mẹ́tàlélógún ni àwọn proteinogenic ("ìṣẹ̀dá-protein") amino acid náà [8][9][10]  tí wọ́n maa ń sopọ̀ mọ́ peptide ("polypeptides") lati ṣètò ìpilẹ̀ fún àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ protein. [11] Gbogbo àwọn wònyí ni L-stereoisomers (isomer "lápá-òsì"), bótilèjépé awon D-amino acid ("alapa-otun") díẹ̀ wà  nínú ẹ̀yà ìdáàbòbò ara bacteria, wọ́n lè jẹ́ neuromodulator (D-serine), wón tún wà nínú àwọn egbògi kànkàn.[12] Ogún nínú àwọn proteinogenic amino acid naa ní ó ń kóòdù tààrà nípasè kóòdù onímẹta nínú kóòdù jiini a si mo won si "standard" amino acid.

Àwọn ìrísí àtúnṣe

Àwọn eléyìí ṣe àfihàn ìrísí àti àgékúrú àwọn ọ̀kànlélógún amino acid tí wọ́n ń kóòdù tààrà fún ìṣẹ̀dá protein nípasẹ̀ àwọn kóòdù gene nínú ara. Àwọn ìrísí wọ̀yí jẹ́ ti kẹ́míka tí wà bíi zwitterion nínú àdàpọ̀.

 
Tábìlì fún àwọn ìrísí, orúkọ àti iye pKa àsomọ́ ẹ̀gbẹ́ àwọn ọ̀kànlélógún amino acid

IUPAC/IUBMB tún ti sọ àwọn orúkọ àgékúrú amino acid mẹ́jì wọ̀nyí..

Àwọn ìtọ́kasí àti àkíyèsí àtúnṣe

  1. "Amino".
  2. "amino acid".
  3. "amino".
  4. "New Naturally Occurring Amino Acids". Angewandte Chemie International Edition in English 22 (11): 816–28. November 1983. doi:10.1002/anie.198308161. 
  5. Latham, Michael C. (1997). "Chapter 8. Body composition, the functions of food, metabolism and energy". Human nutrition in the developing world. Food and Nutrition Series - No. 29. Rome: Food and Agriculture Organization of the United Nations. http://www.fao.org/docrep/W0073E/w0073e04.htm#P1625_217364. 
  6. Proline is an exception to this general formula.
  7. Clark, Jim (August 2007). "an introduction to amino acids". chemguide.
  8. Jakubke, Hans-Dieter; Sewald, Norbert (2008).
  9. Pollegioni, Loredano; Servi, Stefano, eds (2012). Unnatural Amino Acids: Methods and Protocols. Methods in Molecular Biology - Volume 794. Humana Press. p. v. ISBN 978-1-61779-331-8. OCLC 756512314. http://link.springer.com/book/10.1007%2F978-1-61779-331-8. 
  10. "Biosynthesis and Charging of Pyrrolysine, the 22nd Genetically Encoded Amino Acid". Angewandte Chemie International Edition 50 (41): 9540–1. 2011. doi:10.1002/anie.201103769. PMID 21796749. 
  11. "Chapter 1: Proteins are the Body's Worker Molecules" Archived 2014-06-07 at the Wayback Machine..
  12. Michal, Gerhard, ed (2012). Biochemical Pathways: An Atlas of Biochemistry and Molecular Biology (2nd ed.). Wiley. p. 5.