Clement Nyong Isong

Olóṣèlú
(Àtúnjúwe láti Clement Isong)

Clement Nyong Isong, CFR tí wọ́n bí ní ogúnjọ́ oṣù kẹrin ọdún 1920, ó sìn kú ní ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù karùn-ún ọdún 2000 (20 April 1920 – 29 May 2000). O jẹ́ gbajúmọ̀ olóṣèlú àti onímọ̀ ilé-ìfowópamọ́ tí ó jẹ́ Gómìnà Ilé Ìfowópamọ́-àgbà tí Nàìjíríà lọ́dún 1967 sí 1975[1] nígbà ìṣèjọba ológun Ọ̀gágun Yakubu Gowon. Wọ́n wá padà dìbò yàn án gẹ́gẹ́ bí gómìnà ìpínlẹ̀ Cross River lọ́dún 1979 sí 1983.[2]

Clement Nyong Isong
Gómìnà ilé ìfówópamọ́ àpapọ̀ tí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà
In office
Ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù kẹjọ ọdún 1967 – Ọjọ́ kejìlélógún oṣù kẹsàn-án ọdún 1975
AsíwájúAlhaji Aliyu Mai-Bornu
Arọ́pòMallam Adamu Ciroma
Gómìnà Ìpínlẹ̀ Cross River
In office
oṣù kẹwàá ọdún 1979 – oṣù kẹwàá ọdún 1983
AsíwájúBabatunde Elegbede
Arọ́pòDonald Etiebet
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí20 April 1920
Eket, Akwa Ibom State, Nigeria
Aláìsí29 May 2000
Ọmọorílẹ̀-èdèNaijiria
(Àwọn) olólùfẹ́Nne Clementine Isong
Àwọn ọmọ
  • Ekaete Etuk
  • Clement Isong Jr.
  • Umo Isong Deceased
  • Eno Obi
  • Inyang Isong
  • Ubong Isong


Alma materIowa Wesleyan University(B.A), Harvard Graduate School of Arts and Sciences(AM)

ìgbé ayé rẹ̀

àtúnṣe

A bí Isong ní ọjọ́ ogún oṣù kẹrin ọdún 1920 ní Eket, Ipinle Akwa Ibom. Ó kẹ́kọ̀ọ́ ní Fásìtì kọ́lẹ́ẹ̀jì Ibadan, lowa Wesleyan College, Mount Pleasant, Iowa, àti Havard Graduate School of Arts and Sciences, nibi ti o ti gba Ph.D. ni Iṣowo. O jẹ olukọni nipa ọrọ -aje ni University of Ibadan ṣaaju ki o to darapọ mọ Central Bank of Nigeria (CBN) gẹgẹbi akọwe, titi ti o fi di oludari iwadii. Otun wa pẹlu International Monetary Fund gẹgẹbi onimọran ni Ẹka Afirika

Àsìkò rẹ gẹgẹ bí Gómìnà banki CBN

àtúnṣe

Yakubu Gowon yan Isong gomina CBN ni Oṣu Kẹjọ ọdun 1967, ọfiisi ti o wa titi di Oṣu Kẹsan ọdun 1975. Ohun kan na lo je Gomina banki Naijiria ni àsìkò ogún abele ti Biafra (1967-1970) àti nígbà tí èpò robi burẹkẹ ni orile-ede Naijiria. Ní akoko rẹ Naijiria yago fun jíjẹ gbèsè.O takò bi orile-ede Naijiria ṣe n ṣe ikojọpọ isura jọ sí òkè okun lai fi se idoko owo sí bí to yẹ, bi ọ tile je wipe iyato wa ni eto amayederun ni orílẹ̀-èdè Nàìjíríà[3]


[2]

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "Events & Facts". Central Bank of Nigeria | Home. 2006-02-20. Retrieved 2021-10-14. 
  2. 2.0 2.1 "Dr. Clement Isong". Central Bank of Nigeria. Retrieved 2010-02-28. 
  3. Àdàkọ:Toka iwe