Clement Nyong Isong
Clement Nyong Isong, CFR tí wọ́n bí ní ogúnjọ́ oṣù kẹrin ọdún 1920, ó sìn kú ní ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù karùn-ún ọdún 2000 (20 April 1920 – 29 May 2000). O jẹ́ gbajúmọ̀ olóṣèlú àti onímọ̀ ilé-ìfowópamọ́ tí ó jẹ́ Gómìnà Ilé Ìfowópamọ́-àgbà tí Nàìjíríà lọ́dún 1967 sí 1975[1] nígbà ìṣèjọba ológun Ọ̀gágun Yakubu Gowon. Wọ́n wá padà dìbò yàn án gẹ́gẹ́ bí gómìnà ìpínlẹ̀ Cross River lọ́dún 1979 sí 1983.[2]
Clement Nyong Isong | |
---|---|
Gómìnà ilé ìfówópamọ́ àpapọ̀ tí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà | |
In office Ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù kẹjọ ọdún 1967 – Ọjọ́ kejìlélógún oṣù kẹsàn-án ọdún 1975 | |
Asíwájú | Alhaji Aliyu Mai-Bornu |
Arọ́pò | Mallam Adamu Ciroma |
Gómìnà Ìpínlẹ̀ Cross River | |
In office oṣù kẹwàá ọdún 1979 – oṣù kẹwàá ọdún 1983 | |
Asíwájú | Babatunde Elegbede |
Arọ́pò | Donald Etiebet |
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | 20 April 1920 Eket, Akwa Ibom State, Nigeria |
Aláìsí | 29 May 2000 |
Ọmọorílẹ̀-èdè | Naijiria |
(Àwọn) olólùfẹ́ | Nne Clementine Isong |
Àwọn ọmọ |
|
Alma mater | Iowa Wesleyan University(B.A), Harvard Graduate School of Arts and Sciences(AM) |
ìgbé ayé rẹ̀
àtúnṣeA bí Isong ní ọjọ́ ogún oṣù kẹrin ọdún 1920 ní Eket, Ipinle Akwa Ibom. Ó kẹ́kọ̀ọ́ ní Fásìtì kọ́lẹ́ẹ̀jì Ibadan, lowa Wesleyan College, Mount Pleasant, Iowa, àti Havard Graduate School of Arts and Sciences, nibi ti o ti gba Ph.D. ni Iṣowo. O jẹ olukọni nipa ọrọ -aje ni University of Ibadan ṣaaju ki o to darapọ mọ Central Bank of Nigeria (CBN) gẹgẹbi akọwe, titi ti o fi di oludari iwadii. Otun wa pẹlu International Monetary Fund gẹgẹbi onimọran ni Ẹka Afirika
Àsìkò rẹ gẹgẹ bí Gómìnà banki CBN
àtúnṣeYakubu Gowon yan Isong gomina CBN ni Oṣu Kẹjọ ọdun 1967, ọfiisi ti o wa titi di Oṣu Kẹsan ọdun 1975. Ohun kan na lo je Gomina banki Naijiria ni àsìkò ogún abele ti Biafra (1967-1970) àti nígbà tí èpò robi burẹkẹ ni orile-ede Naijiria. Ní akoko rẹ Naijiria yago fun jíjẹ gbèsè.O takò bi orile-ede Naijiria ṣe n ṣe ikojọpọ isura jọ sí òkè okun lai fi se idoko owo sí bí to yẹ, bi ọ tile je wipe iyato wa ni eto amayederun ni orílẹ̀-èdè Nàìjíríà[3]
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Events & Facts". Central Bank of Nigeria | Home. 2006-02-20. Retrieved 2021-10-14.
- ↑ 2.0 2.1 "Dr. Clement Isong". Central Bank of Nigeria. Retrieved 2010-02-28.
- ↑ Àdàkọ:Toka iwe
Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |