Command and Staff College, Jaji
Armed Forces Command and Staff College, Jaji jẹ́ ilé-ìgbẹ̀kọ́ fún àwọn Nigerian Armed Forces pẹ̀lú àwọn ajagun orí òfurufú àti abẹ́-omi. Ó súnmọ́ ìlú Jaji, ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní apá àríwá ilẹ̀ Kàdúná lábẹ́ ìjọba ìpínlẹ Igabi. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, Air Vice Marshal Ebenezer Olayinka Alade ló ń darí ilé-ìwé náà.[1]
Armed Forces Command and Staff College | |
---|---|
Established | 1976 |
Type | Staff college |
Parent institution | National Defence College, Nigeria |
Religious affiliation | Nigerian Armed Forces |
Commandant | Air vice-marshal Ebenezer Olayinka Alade |
Location | Igabi, Kaduna StateJaji, Naijiria, Naijiria |
Campus | Rural |
Website | afcsc.mil.ng |
Ìtàn
àtúnṣeThe Armed Forces Command and Staff College jẹ́ ilé-ìwé tí wọ́n dá sílẹ̀ ní oṣù karùn-ún, ọdún 1976, pẹ̀lú iṣẹ́ akọ́ni àgbà méjì. Ní oṣù kẹrin, ọdún 1978, ilé-ìwé náà gbòrò si nígbà tí wọ́n dá ẹ̀ka àwọn ọ̀jẹ̀ wẹ́wẹ́ kalẹ̀.[1] Oṣù kẹjọ, ọdún 1981 ni wọ́n fi ẹ̀kọ́ àwọn ológun ti abẹ́-omi kún ètò-ẹ̀kọ́ ilé-ìwé náà.[2]
Ètò-ẹ̀kọ́ àwọn adarí àgbà dálé lórí àwọn ẹ̀kọ́ tí wọ́n rí nínú ètò-ẹ̀kọ́ àwọn Britain, ti British Army Staff College, ní Camberley.[2]
Ní oṣù kẹjọ, ọdún 2005, adarí àwọn ọmọ-ológun ti òkè-òkun, Adams Ingram yọjú sí Jaji, ó sì gbé owó tó tó bíi 200,000 pounds kalẹ̀ láti fi ran ilé-ìwé náà lọ́wọh.[3] Ní oṣù kọkànlá ọdún 2006, ọmọọba ti ìlú Wales láti ìlú United Kingdom wá sí Nàìjíríà láti wá ṣe àbẹ̀wò sí àwọn ológun tó wà ní Jaji.[4]
Àwọn òṣìṣẹ́ tó lààmìlaka
àtúnṣe- Abdulmumini Aminu gómìnà Ipinle Borno
- Azubuike Ihejirika, adarí àwọn ọmọ ogun nígbà kan rí
- Dan Archibong, gómìnà Ipinle Cross River lábẹ́ ìjọba ológun
- Dele Joseph Ezeoba, olórí àwọn ológun lábẹ́ omi nígbà kan rí
- Emmanuel Acholonu, adarí Ipinle Katsina nígbà kan rí
- Gideon Orkar, darí ogun ti oṣù kẹrin, ọdún 1990
- John Mark Inienger, adarí ECOMOG ní Liberia
- John Nanzip Shagaya, later a Senator John Nanzip Shagaya, tó padà di Sẹ́nátọ̀
- Plateau State Joshua Anaja, olórí ìpílẹ̀ Plateau
- Martin Luther Agwali, adarí àwọn ọmọ ogun nígbà kan rí
- Tukur Yusuf Buratai, adarí àwọn ọmọ ogun nígbà kan rí
- Sanni Bello, gohmìnà Ipinle Kano
- Suraj Abdurrahman, adarí àwọn ọmọ ogun ti Liberia
- Alwali Kazir, adarí àwọn ọmọ ogun nígbà kan rí
- Oladipo Phillips Ayeni, gómínà Ipinle Bayelsa lábẹ́ ìjọba ológun
Àwọn tó ti ṣetán tó ti lààmìlaka
àtúnṣe- Azubuike Ihejirika, Ọ̀gá àwọn Ọmọṣẹ́ Agbógun Nàìjíríà nígbà kan rí
- Ibrahim Babangida, olórí ìlú Naijiria lábẹ́ ìjọba ológun
- Owoye Andrew Azazi, Ọ̀gá àwọn Ọmọṣẹ́ Agbógun Nàìjíríà àti Chief of the Defence Staff (Nigeria)
- Emmanuel Ukaegbu olórí ìlú Ìpínlẹ̀ Anámbra lábẹ́ ìjọba ológun
- Jonah Wuyep, adári àwọn ológun ti orí òfurufú
- Femi John Femi adarí àwọn ológun ti orí òfurufú
- Ọlágúnsóyè Oyinlọlá, gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun
- Paul Obi, adarí Ìpínlẹ̀ Bàyélsà
- Abubakar Tanko Ayuba, gómìnà Ìpínlẹ̀ Kàtsínà
- Dominic Oneya, adarí Ipinle Kano àti Ìpínlẹ̀ Bẹ́núé
- Amadi Ikwechegh, gómìnà Ìpínlẹ̀ Ímò
- Tunji Olurin, gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ àti Ìpínlẹ̀ Èkìtì
- Lawan Gwadabe, gómìnà Ìpínlẹ̀ Niger
- Oladipo Phillips Ayeni, adarí Ìpínlẹ̀ Bàyélsà àkọ́kọ́ lásìkò ìjọba ológun
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ 1.0 1.1 "Armed Forces Command and Staff College (AFCSC) Jaji". Armed Forces Command and Staff College (AFCSC) Jaji. Retrieved 2021-05-02.
- ↑ 2.0 2.1 "Nigeria - Training". Federal Research Division of the Library of Congress. Retrieved 2009-11-18.
- ↑ "PRESS NOTICE: UK trains an extra 17,000 Nigerian peacekeepers". UK Ministry of Defence. 20 September 2005. Archived from the original on 24 March 2010. Retrieved 2009-11-18.
- ↑ "The Prince of Wales visits Nigeria". Prince of Wales. 29 November 2006. Retrieved 2009-11-18.