Adegoke Adelabu

Oníwé-Ìròyín

Gbàdàmọ́sí Adégòkè Adélabú tí a bí ní ọjọ́ Kẹta osù Kẹsàn an ọdún 1915 ní ìlú Ìbàdàn ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà jẹ́ olóṣèlú àti Mínísítà tẹ́lẹ̀ ohun àlùmọ́nì ati ìgbáyé-gbádùn fún orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láàrín osù Kínní ọdún 1955 sí oṣù Kínní ọdún 1956, tí ó sì padà di olórí alátakò ní ilé ìgbìmọ̀ọ̀ aṣòfin ní ẹkún ìjọba Ìwọ̀ Oòrùn nígbà ayé rẹ̀. Ó di ìlú-mòọ́ká látàrí akitiyan ati ipa malegbagbe tí ó kò nínú ìṣèlú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Adélabú lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ Government College, Ibadan ó sì di oníṣòwò lẹ́yìn ẹ̀kọ́ rẹ̀. Ó pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ sínú ìjàmbá ọkọ̀ lẹ́yìn ìgbà diẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà gba òmìnira lọ́wọ́ ìjọba àmúnisìn Brítènì. [1]

Adegoke Adelabu
Adelabu.jpg
Opposition Leader Western House of Assembly
In office
1956–1958
Chairman of Ibadan District Council
In office
1954–1956
Federal Minister of Natural Resources and Social Services
In office
January 1955 - January 1956
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí3rd september 1915
Ibadan
AláìsíMarch 25, 1958(Age 42)
Ẹgbẹ́ olóṣèlúNCNC


Ibẹ̀rẹ̀ ayé rẹ̀Àtúnṣe

Adélabú tí a bí sínú ẹbí ọ̀gbẹ́ni Sanusi Aṣiyanbí ati abilékọ Awujola Adélabú.[2] ní ọdún 1915. Ìyá Adélabú ni ó jẹ́ ìyàwó kejì nílé ọmọ rẹ̀ tí ó sì ṣílẹ̀ wọ̀ lẹ́yìn ìgbà diẹ̀ tí ó bí Adégòkè tan, èyí ni ó mú kí ẹ̀gbọ́n Ìyá rẹ̀ ó gbà á tọ́. Ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ alàkalẹ̀ọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ti C.M.S. ní Kúdẹtì nígboro ìlú Ìbàdàn láàrín ọdún 1925-1929, tí ó sì kàwé gba Standard IV àti V ní C.M.S. Central school, Mapo. Lóòtọ́ Musulumi ni oun àti ẹbí rẹ̀, amọ́ ọ̀dọ̀ Àbúrò bàbá rẹ̀ tí ó gbé lọ́dọ̀ rẹ̀ mu lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ tí ó jẹ́ ilé-ẹ̀kọ́ ẹlẹ́sì Kìrìstẹ́nì ní ìlú Ìbàdàn, tí ó sì gba ìwé-ẹ̀rí ilé-ẹ̀kó náà tí fi lè wọ ilé-ẹ̀kọ́ CMS. Ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ Government College ti ìlú Ìbàdàn láàrín ọdún [3] 1931 sí ọdún 1936 gẹ́gẹ́ bí aṣojú akẹ́kọ̀ọ́ inú ọgbà. Ní ọdún 1936, Adélabú wọ ilé-ẹ̀kọ́ Yaba Higher College, lẹ́yìn èyí, ó rí ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ gbà lọ́wọ́ ilé-iṣẹ́ UAC láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa imọ̀ okòwò.[4] Láìpẹ́, Adélabú kúrò nílé ẹ̀kọ́ lẹ́yìn oṣù mẹ́fà tí wọ́n fun ní ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́. Ọkàn nínú àwọn akọ́ṣẹ́-mọṣẹ́ tí ó ti mọ̀ ri ní ilé-iṣẹ́ kòkó tí ó tún jẹ́ ọ̀gá àgbà ní ilé-iṣẹ́ UAC fun ní iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí amúgbá-lẹ́gbẹ̀ẹ́ adarí àgbà ilé-iṣẹ́ wọn ní ìlú Ìbàdàn . Lẹ́yìn tí ó de ibẹ̀, Adélabú gbé ìgbésẹ̀ bí ilé-iṣẹ́ ṣe lè máa to kókó lọ́nà ará ọ̀tọ̀, ìgbésẹ̀ yí sì ni ó jẹ́ kí ó ri ìgbéga sípò igbákejì adarí lẹ́ka ìtajà. Adélabú kúrò ní ilé-iṣẹ́ UAC ní ọdún 1937 láti dara pọ̀ mọ́ iṣẹ́ owó kòkó títà fúnra rẹ̀, láìpẹ́, ó di lààmì-laaka nínú iṣẹ́ òwò kòkó rẹ̀. Lẹ́yìn tí ó di gbajúmọ̀ níbi iṣẹ́ rẹ̀ tán ni ó bẹ̀rẹ̀ ní ń wá iṣẹ́ ìjọba. [5] Ó di olùbẹ̀wò agbà fún ohun ọ̀gbìn ní ọsún 1939. Ó ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ilé-iṣẹ́ UAC títí di ọdún 1945, Adélabú sì kúrò ní ilé-iṣẹ́ náà nígbà tí Richardson kúrò ní ilé-iṣẹ́ UAC. [6]. Lẹ́yìn èyí, Adélabú pa gbogbo owó tí ó ti rí kó jọ ní ó papọ̀ tí ó fi da òwò òwú sílẹ̀ pẹ̀lú Levantine ní ilẹ̀ Ìbàdàn.

Àwọn itọ́ka síÀtúnṣe

  1. Sklar, p. 303.
  2. Post & Jenkins 1973, p. 33.
  3. Post & Jenkins 1973, p. 36.
  4. Post & Jenkins 1973, p. 37.
  5. Post & Jenkins 1973, p. 46.
  6. Post & Jenkins 1973, p. 51.