Irú (oúnjẹ)
Ẹ̀wà eéṣú tí wọ́n jóná tí wọ́n fi ń se oúnjẹ.
Irú Èdè Yorùbátàbú Dawadawa (Hausa) tàbí Eware (Edo) tàbí Sumbala (Bambara) tàbí Narghi (Fula) jẹ́ Irú tó ti fermentí wọ́n sì máa ń lò láti fi dáná.[1] Ó jọ ogiri àti douchi. Bẹ́ẹ̀ sì ni ó gbajúmọ̀ káàkiri apá Ìwọ̀-oòrùn ilẹ̀ Africa, pàápàá nínú àwọn oúnjẹ wọn. Wọ́n máa ń lò ó láti se àwọn ọbẹ̀ ìbílẹ̀ bí i egusi, ilá, ewédú àti ọ̀gbọ̀nọ̀.[2]
Ṣíṣe irú
àtúnṣewọ́n máa ń bọ̀ ọ́, tí wọ́n á sì nù ún kí wọ́n tó gbe sí ẹ̀gbé kan kó ferment - tó bá ti ferment, ó máa ń ní òórùn kan tó máa ń rùn bọ̀ǹbọ̀nọ̀. Wọ́n lè fi iyọ̀ sí kó ba lè pẹ̀ nílè dáadáa.
Wọ́n máa ń dì í róbóróbó tàbí kí wọ́n tọ́jú rẹ̀ pamọ́ fún ìgbà díẹ̀ láti rí èsì gidi.
Àwọn Yorùbá ni oríṣi irú méjì:
- Irú Wooro ni wọ́n máa ń lò láti se ọbẹ̀ bí i ẹ̀gúsí, ẹ̀fọ́ rírò, ọbẹ̀ ọ̀fadà, ayamase, omi ọbẹ̀, ọbẹ̀ ata, ilá alásèpọ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
- Irú pẹ̀tẹ̀ ni wọ́n máa ń lò láti se ewédú àti ọbẹ̀ ègúsí.[3]
Orúkọ àti ìyàtọ̀
àtúnṣeÀwọn orúkọ mìíràn tí wọ́n ń pe irú ni agbègbè mìíràn:
- Èdè Manding: sunbala, sumbala, sungala, sumara Sumbala (or in French transcription soumbala) is a loan from Manding.
- Èdè Haúsá: dawadawa, daddawa
- Èdè Pulaar/Pular: ojji
- Èdè Yorùbá: iru
- Èdè Serer, Saafi, Wolof: netetou
- Èdè Krio: kainda
- Èdè Susu: Kenda
- Èdè Zarma: doso mari
- Èdè Dagbanli: Kpalgu
- Èdè Mooré: Colgo
- Èdè Konkomba: tijun, tijon
Tún wo
àtúnṣeÀwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Dawadawa: The Magical Food Ingredient". LivingTheAncestralWay (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2024-10-23.
- ↑ Petrikova, Ivica; Bhattacharjee, Ranjana; Fraser, Paul D. (Jan 2023). "The 'Nigerian Diet' and Its Evolution: Review of the Existing Literature and Household Survey Data". Foods 12 (3): 443. doi:10.3390/foods12030443. PMC 9914143. PMID 36765972. //www.pubmedcentral.nih.gov/articlerender.fcgi?tool=pmcentrez&artid=9914143.
- ↑ Abaelu, Adela M.; Olukoya, Daniel K.; Okochi, Veronica I.; Akinrimisi, Ezekiel O. (1990). "Biochemical changes in fermented melon (egusi) seeds (Citrullis vulgaris)". Journal of Industrial Microbiology 6 (3): 211–214. doi:10.1007/BF01577698.