Kunle Afod
Kúnlé Afod tí a bí ní ọjọ́ Kẹrìnlélógún oṣù Kẹwàá, [1] ọdún 1973 (24-10-1973) jẹ́ òṣèré Sinimá àgbéléwò Yorùbá tí wọ́n bí ní ìpínlẹ̀ Èkó, [2] àmọ́ tí òṣẹ̀ wá láti ìlú Ìbàdàn ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, tí ó sì jẹ́ akọ́bí nínú ọmọ mẹ́rin tí àwọn òbí rẹ̀ bí. [3]
Ètò ẹ́kọ́ rẹ̀
àtúnṣeKúnlé bẹ̀rẹ̀ ẹ́kọ́ rẹ̀ ní Ilé-ẹ́kọ́ alákọ́bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ ní ìlú Festac ní ìpínlẹ̀ Èkó tí ó sì parí rẹ̀ ní ìlú Ọ̀wọ̀ ní ìpínlẹ̀ Òndó , kí ó tó lọ sì Ilé-ẹ́kọ́ oníwé mẹ́wá ti Command tí ó wà ní ìlú Jos.[4]
Iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ òṣèré
àtúnṣeÓ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tíátà rẹ̀ lábẹ́ àwọn ọ̀gá rẹ̀ Tọmọlójù Jídé Ògúngbadé àti Jàgan Aníkúlápó , kí ó tó dara pọ̀ mọ́ ikọ̀ Àwàdà Kẹríkẹrì lábẹ́ àkóso Adébáyọ̀ Sàlámì, tí wọ́n ń pè ní Ọ̀gá Bello.
Àwọn ẹbí rẹ̀
àtúnṣeKúnlé ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú Désọ́lá, tí wọ́n sì bímọ.
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Kunle Afod Biography: Age & Movies". 360dopes. 2018-07-17. Retrieved 2020-01-04.
- ↑ Published (2015-12-15). "I turned down romantic roles because of my wife - Kunle Afod". Punch Newspapers. Retrieved 2020-01-04.
- ↑ "Kunle Afod, His Wife And Their 4 Sons In Adorable Family Photo". Within Nigeria. 2018-06-12. Retrieved 2020-01-04.
- ↑ "Kunle Afod Reveals his First Child Many People Do Not Know (Photos)". Daily Family NG. 2018-12-31. Retrieved 2020-01-04.