Lamidi Onaolapo Adeshina
Lamidi Ona-Olapo Adesina CON (ọjọ́ ogún oṣù Kínní ọdún 1939 – ọjọ́ kọkànlá oṣù kọkànlá ọdún 2012) ó jẹ́ ọmọ bíbí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, olùkọ́ àti olóṣèlú tí ó ṣe gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ láàárín ọdún 1999 sí ọdún 2003, gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú Alliance for Democracy (AD). [1]
Lam Adesina | |
---|---|
Governor of Oyo State | |
In office 29 May 1999 – 29 May 2003 | |
Deputy | Iyiola Oladokun |
Asíwájú | Amen Edore Oyakhire |
Arọ́pò | Rasheed Ladoja |
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | Lamidi Ona-Olapo Adesina 20 January 1939 Ibadan, Southern Region, British Nigeria (now in Oyo State, Nigeria) |
Aláìsí | 11 November 2012 Ibeju-Lekki, Lagos State, Nigeria | (ọmọ ọdún 73)
Ẹgbẹ́ olóṣèlú |
|
(Àwọn) olólùfẹ́ | Saratu Lam Adesina |
Àwọn ọmọ |
|
Alma mater | |
Occupation |
|
Ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀
àtúnṣeWọ́n bí Adesina ní ogúnjọ́, oṣù kìíní, ọdún 1939.[2] Ó kẹ́kọ̀ọ́ jáde ní ilé ẹ̀kọ́ gíga ti Loyola College, Ibadan, lẹ́yìn náà ni ó tẹ̀síwájú láti kẹ́kọ̀ọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ gíga ti University of Nigeria, Nsukka láàrin ọdún 1961 sí ọdún 1965 níbẹ̀ ni ó ti gboyè ìmọ̀ àkọ́kọ́ nínú ẹ̀kọ́ nípa ìtàn (History). Lẹ́yìn èyí ni ó tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ gíga ti ilẹ̀ Ìbàdàn University of Ibadan ní ọdún 1971 níbi tí ó ti gboyè PGDE. [3]
Iṣẹ́ rẹ̀
àtúnṣeLam Adesina jẹ́ olùkọ́ nígbà ayé rẹ̀. Ó ṣiṣẹ́ olùkọ́ni ní ilé ẹ̀kọ́ girama ti Lagelu Grammar School tí ó wà nílùú Ìbàdàn níbi tí ó ti kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní ẹ̀kọ́ nípa ìtàn (History), èdè Gẹ̀ẹ́sì àti lítírésọ̀. Lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ nígbà náà ni Abiola Ajimobi, ẹni tí ó padà di gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́. [4] Ó gbá ìgbéga títí tí ó fi di ọ̀gá àgbà ilé ẹ̀kọ́ girama. Lam padà ṣiṣẹ́ ní ilé ẹ̀kọ́ tí ó jẹ́ ti aládàáni tí ó sì dá ilé ìràwé sílẹ̀ kí ó tó wọ inú òṣèlú. [5] Lam Adesina tún jẹ́ gbajúmọ̀ akàwéròyìn. Àwọn ohun tí ó máa ń kọ lábẹ́ " ọ̀wọ́n ìwádìí tẹ̀síwájú" ní Nigerian Tribune jẹ́ èyí tí kò bá àwọn ìjọba ológun ìgbà náà láramu, tí ó sì ti ti ara èyí di ẹni ìtìmọ́lé ní ọ̀pọ̀ ìgbà. [6]
Nípa ayé òṣèlú rẹ̀
àtúnṣeWọ́n dìbò fún Lam Adesina láti jẹ́ aṣojú ní ilé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin ti ẹkùn ìdìbò gúúsù ti ilẹ̀ Ìbàdàn ní ọdún 1979 lábẹ́ àbùradà ẹgbẹ́ òṣèlú Unity Party of Nigeria èyí tí olóògbé olóyè Obafemi Awolowo dá sílẹ̀. [citation needed] Ó padà sí ẹnu iṣẹ́ àdáni lẹ́yìn tí àwọn ológun gba ètò ìṣàkóso ní ọdún 1983.[citation needed] wọ́n dìbò fún Lam gẹ́gẹ́ bí aṣojú ilé ìgbìmọ̀ ní ọdún 1988. Lam Adesina jẹ́ aṣáájú National Democratic Coalition popularly èyí tí a tún mọ̀ sí NADECO ní Ìpínlẹ̀ Oyo, orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. [citation needed] Wọ́n dá ẹgbẹ́ yìí sílẹ̀ láti rẹ́yìn ètò ìṣèjọba ológun ti ìjọba Sani Abacha, kí ètò ìṣèjọba náà ó le fi ọwọ́ sí ìbò tí ó gbé MKO Abiola wọlé, ẹni tí ó jáwé olúborí níbi ìdìbò fún ipò Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ẹni tí wọ́n padà tì mọ́ àtìmọ́lé ní ọdún 1998. Ìṣàkóso ìjọba ológun Abacha mú Lam Adesina àti àwọn Ajàfẹ́tọ̀ó ọmọnìyàn mìíràn, tí wọ́n sì sọ wọ́n sí àtìmọ́lé pẹ̀lú àkọlé pé wọ́n jẹ́ "ẹlẹ́wọ̀n tí wọ́n mú lójú ogun".[7]
Lẹ́yìn iṣẹ́ rẹ̀
àtúnṣeLam Adesina jẹ́ onígbọ̀wọ́ fún Abiola Ajimobi nínú ìlà kàkà rẹ̀ láti di sẹ́nítọ̀ gúúsù ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní ọdún 2003. [8] Lẹ́yìn ọdún díẹ̀ ni àwọn méjèèjì pínyà, tí Ajimobi sì lọ sí inú ẹgbẹ́ òṣèlú All Nigeria Peoples Party (ANPP), ṣùgbọ́n nínú oṣù kẹwàá, ọdún 2009, Ajimobi padà sínú ẹgbẹ́ òṣèlú Action Congress of Nigeria ní abẹ́ ìṣàkóso olùdarí ẹgbẹ́ Lam Adesina, ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ni àwọn méjèèjì ti di ọ̀kan náà padà. [9] Lam Adesina ṣe àtìlẹ́yìn Abiola Ajimobi tí ó sì ṣe ìpolongo fún un gẹ́gẹ́ bí olùdíje dupò gomina Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní abẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú Action Congress of Nigeria in 2011. [10]
Ìpapòdà
àtúnṣeLam Adesina dágbére fún ayé ní ọjọ́ kọkànlá, oṣù kọkànlá, ọdún 2012 ní ilé ìwòsàn ti St. Nicholas Hospital nílùú Èkó Lagos state. Èrò nípa ìpapòdà rẹ̀ ni pé ó ní ohun ṣe pẹ̀lú àìsàn àtọ̀gbe tí ó bá a fínra fún ọjọ́ pípẹ́. [11]
Wọ́n sin ín sí ilé rẹ̀ tí ó wà ní agbègbè Felele nílùú Ibadan ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà àwọn ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí. [12]
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Nigeria States". World Statesmen. Retrieved 2 May 2010.
- ↑ "Homepage". The Nation. Retrieved 8 March 2022.
- ↑ Kayode-Adedeji, Dimeji (11 November 2012). "Updated: Lam Adesina, former Oyo governor, dies at 73". Premium Times. https://www.premiumtimesng.com/news/106616-former-oyo-governor-lam-adeshina-dead.html.
- ↑ Ajibade, Kunle (28 May 2019). "Abiola Ajimobi: A Portrait". P.M. News. https://pmnewsnigeria.com/2019/05/28/abiola-ajimobi-a-portrait/.
- ↑ "Their Excellencies, What next?". This Day. 24 May 2003. http://news.biafranigeriaworld.com/archive/2003/may/24/047.html.
- ↑ "Learn From Great Lam's Selfless Politics For Democracy To Thrive – Lanlehin". Nigerian Tribune. 11 November 2018. Retrieved 27 January 2019.
- ↑ "8 Years After: Untold Story of How Ladoja Was Impeached as Oyo State Governor Revealed". Abusidiqu. Archived from the original on 27 January 2019. Retrieved 27 January 2019. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ Sodeeq, Wale (29 July 2017). "The Many 'Wrongs' Of Ajimobi". Nigerian Tribune. https://www.tribuneonlineng.com/104580/.
- ↑ "Tinubu reconciles Lam Adesina, Ajimobi". The Nation. 24 October 2009. Archived from the original on 27 October 2009. Retrieved 2 May 2010. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ Sodeeq, Wale (29 July 2017). "The Many 'Wrongs' Of Ajimobi". Nigerian Tribune. https://www.tribuneonlineng.com/104580/.
- ↑ "Former Oyo Governor Lam Adesina Dead". The Will. 11 November 2012. Archived from the original on 14 November 2012. https://web.archive.org/web/20121114180247/http://thewillnigeria.com/breaking/17030.html.
- ↑ Alonge, Osagie (11 November 2012). "Lam Adesina Dies At 73, To Be Buried Today". Nigerian Entertainment Today. Archived from the original on 13 November 2012. Retrieved 11 November 2012. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help)