Kẹ́ṣhiró Ọlọ́ládẹ́ ( bí ní Oṣù kẹ́ta Ọjọ́ Kẹtàdínlógún, Ọdún 1995), tí àwọn ènìyàn mọ sí Lil Kesh, jẹ́ Olórin, Rápà àti Akọ-Orin Nàìjíríà. Ó di ìlú-mọ̀-ọ́-ká lẹ́yìn tó kọ orin "Shoki".[1][2]

Lil Kesh
Background information
Orúkọ àbísọKẹ́shinró Ọlọ́ládé
Wọ́n tún mọ̀ọ́ bíiLil kesh
Ọjọ́ìbí17 Oṣù Kẹta 1995 (1995-03-17) (ọmọ ọdún 29)
Ìpínlẹ̀ Èkó , Nàìjíríà
Ìbẹ̀rẹ̀Ìpínlẹ̀ Ọ̀sun, Nàìjíríà
Irú orin
Occupation(s)
  • Rapper
  • Musician
  • Songwriter
InstrumentsDrums and Vocals
Years active2014- di àsìkò yìí
Labels
Associated acts


Ìbẹ̀rẹ̀ ayé rẹ̀

àtúnṣe

Kẹ́shinró Ọlọ́láde jẹ́ bíbí àti dàgbà sí Bàrígà, agbègbè kan ní Ìpínlẹ̀ Èkó ní Nàìjíríà.


Ẹ̀kọ́ rẹ̀

àtúnṣe

Ó lọ sí Stockbridge College fún ẹ̀kọ́ pámárìlì àti ṣẹ́kọ́ndàrì, lẹ́yìn náà ó lọ sí Fáṣítì Èkó. Níbi tó tí kọ́ ẹ̀kọ́ ìmọ̀-ẹ̀dá-èdè. Lẹ́yìn náà, Ó lọ sí National Open University, Nàìjíríà níbi tó ti kọ́ ẹ̀kọ́ Mass Communication lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì.


Ìṣe Ààjò

àtúnṣe

Ó bẹ̀rẹ̀ orin kíkọ gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́-ààjò rẹ̀ ní ọdún 2012. Nígbà tó ń rápà láàárín àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ ní Bàrígà. Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, ó kọ orin àkọ́kọ́ rẹ̀ "Lyrically", orin àkọ́kọ́ rẹ̀ yìí gbajúmọ̀ láàárín àwọn Fáṣítì Nàìjíríà. Àbábọ̀ rẹ̀, jẹ́ kí Lil Kesh Tọwọbọ̀wẹ́ pẹ̀lú Yahoo Boy No Laptop Nation tí àwọn ènìyàn mọ̀ sí YBNL Nation (YBNL) tó jẹ́ ilé-iṣẹ́ Olórin Aládàání tí Olùdálè rẹ̀ jẹ́ Ọlámìídé Adédèjì ní ọdún 2012. Lábẹ́ YBNL, ó kọ Shoki, Efejoku, Gbèsè àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ó fi álíbọ̀mù àkọ́kọ́ rẹ̀ náà lẹ̀ tí ó jẹ' YAGI".

Álíbọ̀mù rẹ̀

àtúnṣe
Year Title Album details
2016 Y.A.G.I


Lára àwọn orin rẹ̀

àtúnṣe
Year Title Album
2014 "Lyrically" Y.A.G.I
"Shoki" Non-album single
"Shoki (Remix)" (featuring Olamide & Davido)
2015 "Shoki (Female Version)" (featuring Cynthia Morgan, Chidinma, Eva Alordiah)
"Gbese"
"Efejoku" Y.A.G.I
"Is It Because I Love You?" (featuring Patoranking)
2016 "Ibile"
"Bend Down Select" Non-album single
2018 "Again O"
2018 "Flenjor"(featuring Duncan Mighty)
2019 "Undertaker"[3]
2020 "All The Way"[4]
2020 "Too Sweet"[5]

Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. Abimboye, Micheal (24 December 2014). "Kiss Daniel, Lil Kesh others to rule 2015". Premium Times. http://www.premiumtimesng.com/arts-entertainment/173847-kiss-daniel-lil-kesh-others-rule-2015.html. 
  2. "MUST WATCH! AMBER ROSE Dances To Lil Kesh’s ‘SHOKI’ At D’banj’s Concert". Information Nigeria. 1 February 2015. http://www.informationng.com/2015/02/must-watch-amber-rose-dances-to-lil-keshs-shoki-at-dbanjs-concert.html. 
  3. "Audio: Lil Kesh Releases "Undertaker"". PM News. 19 February 2019. Retrieved 21 February 2019. 
  4. "Audio: Lil Kesh Releases "All The Way"". PulseDigi. 24 September 2020. Archived from the original on 25 September 2020. Retrieved 24 September 2020. 
  5. "Lil Kesh – Too Sweet ft Chike". legitbaze. 24 September 2020. Archived from the original on 19 October 2021. Retrieved 24 September 2020.