Loyola College, Ibadan
(Àtúnjúwe láti Loyola college, Ibadan)
Loyola College, Ibadan (LCI) jẹ́ Ilé-ẹ̀kọ́ ìjọba èyí tí ó wà fún àwọn àwọn ọmọkùnrin ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ Oyo State, ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà Nigeria. Èyí tí àwọn òjíṣẹ́ ìsìn Kátólíìkì Catholic Missionary dá sílẹ̀ ní ọdún 1954. Ó wà láàárín òpópónà Ifẹ̀ àtijọ́, agbègbè Agodi ní Ìbàdàn Ibadan. Láti ìdásílẹ̀ rẹ̀, Ilé-ẹ̀kọ́ náà tí pèsè àwọn onímọ̀ tí wọ́n dáńtọ ní àwọn ààyè bíi ti ìmọ̀ ìṣègùn àwọn òyìnbó,
Loyola College, Ibadan | |
Veritas (Truth)
| |
Location | |
---|---|
Ibadan, Oyo State, Nàìjíríà | |
Information | |
Type | Public |
Established | 1954 |
Gender | Boys |
Website | loyolacollegeibadan.org |
mọ̀ìẹ̀
iòọ-ẹrọìṣèlún,ìròyìnuìkàn-sárá-ìlú à meàia aàyè ńlá-ńlá ọn oojọ mìíràn. [1]
Àwọn ènìyàn jà-ǹ-kàn jà-ǹ-kàn tí wọ́n jáde níbẹ̀
àtúnṣeIlé-ẹ̀kọ́ Loyola College ti pèsè àwọn onírúurú ènìyàn tí wọ́n jẹ́ jà-ǹ-kàn jà-ǹ-kàn ní àwọn ààyè oríṣiríṣi, lára wọn ni a ti rí :
- Lam Adesina, ẹni tí ó ti fi ìgbà kan rí jẹ́ gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ Oyo State
- Oluwarotimi Odunayo Akeredolu, ẹni tí ó jẹ́ àgbà agbẹjọ́rò ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà Senior Advocate of Nigeria (SAN) tí ó sì tún jẹ gómìnà ní Ìpínlẹ̀ Òǹdó Ondo State.
- Dele Bakare, onímọ̀ ẹ̀rọ ayélujára àti olókoowò
- Raymond Dokpesi, oníṣòwò ètò ayélujára ìkàn-sárá-ìlú
- Akin Fayomi, aṣojú ìjọba
- Oluseun Onigbinde, olókoowò
- Lawson Oyekan, (ceramic sculptor)
- Professor Patrick Utomi, ògbóǹtarìgì ọrọ̀-ajé àti ẹni tí ó ti fi ìgbà kan díje dupò Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà
- Oba Adeyeye Enitan Ogunwusi, Ọba Ilé-Ifẹ̀
- Ekpo Una Owo Nta, Amòfin, alága àjọ olómìnira tó ń rí sí ìwà ìbàjẹ́ àti àwọn ìwà tí ó jọ mọ́ ọn mìíràn (ICPC)
- Olumide Oyedeji, agbábọ́ọ̀lù aláfọwọ́ jù sáwọ̀n (basketballer) tí ó sì ṣe takuntakun nínú eré bọ́ọ̀lù ti NBA ní US, tí ó sì tún jẹ́ olórí fún àwọn agbábọ́ọ̀lù aláfọwọ́ jù sáwọ̀n ti orílẹ̀ èdè Nàìjíríà (D'Tigers) nínú eré Olympics ọdún 2012.
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Admin. "Ooni of Ife in attendance to celebrate Loyola College's 62nd Anniversary". Ibadan City Ng. Retrieved 24 June 2017.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]