Olóyè Raymond Anthony Aleogho Dokpesi (tí wọ́n bí ní 25 October 1951 tó sì ṣaláìsí ní 29 May 2023) jẹ́ oníṣòwò ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Àwọn òbí rẹ̀ wá láti Agenebode, ní Ìpínlẹ̀ Ẹdó, sínú ìdílé tó ní àbúròbìnrin mẹ́fà. Ó wọ inú ilé-iṣẹ́ agbéròyìnjáde pẹ̀lú ilé-iṣẹ́ rẹ̀ DAAR Communications, ó sì ṣèdásílẹ̀ ìkànni orí ẹ̀rọ̀-amóhùnmáwòrán ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, èyí tí ń ṣe Africa Independent Television (AIT).[1] Òun ni alága ìgbìmọ̀ tó ń ṣètò ìpérò àgbáyé ti People's Democratic Party ní ọdún 2015.[2] Ní oṣù kẹta ọdún 2020, ó ń kojú àwọn ẹ̀sùn jìbìtì tí wọn fi sùn ún.[3] Ní oṣù karùn-ún ọdún 2020, Dokpesi làlùyọ nínú àrùn COVID-19.[4] Ó ṣàìsàn ìrọlápá-ìrọlẹ́sẹ̀ ní ọdún 2023, lẹ́yìn àwẹ̀ Ràmàdáànì wọn. Ó ṣaláìsí ní ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù karùn-ún ọdún 2023.[5]


Raymond Dokpesi
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí
Raymond Anthony Aleogho Dokpesi

(1951-10-25)25 Oṣù Kẹ̀wá 1951
Ibadan, Nigeria
Aláìsí29 May 2023(2023-05-29) (ọmọ ọdún 71)
Abuja, Nigeria
Ẹgbẹ́ olóṣèlú
Alma mater
Websiteraymonddokpesi.com

Ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀ àtúnṣe

Dokpesi bẹ̀rẹ̀ ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní Loyola college, Ibadan. Lẹ́yìn èyí, ó darapọ̀ mọ́ Immaculate Conception College (ICC) ní Ìlú Benin, níbi tí ó ti jẹ́ ọmọ-ẹgbé Ozolua Play house, èyí tó jẹ́ ẹgbẹ́ onítíátà àti ijó. Ó kẹ́kọ̀ó gboyè ní University of Benin Edo State, ó sì parí ẹ̀kọ́ rè ní University of Gdansk, ní Poland, níbi tí ó ti gba oyè Doctorate degree, nínú ẹ̀kọ́ Marine Engineering. Alhaji Bamanga Tukur ló san owó ilé-ìwé rẹ̀, láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin.

Àwọn ìtọ́kasí àtúnṣe