Ojúewé Àkọ́kọ́

(Àtúnjúwe láti Main Page)
Adeniran Ogunsanya, amòfin àti olóṣèlú ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà
Adeniran Ogunsanya, amòfin àti olóṣèlú ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà

Adeniran Ogunsanya QC, SAN (31 January 1918 – 22 November 1996) jẹ́ amòfin àti olóṣèlú ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, tí ó sì tún jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára àwọn olùdásílẹ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú Ibadan Peoples Party (IPP). Ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí Kọmíṣọ́nà fún ètò ìdájọ́ ati ètò ẹ̀kọ́ fún Ìpínlẹ̀ Èkó ní àsìkò ìṣèjọba alágbádá ẹlẹ́kejì. Òun náà tún ni alága pátá pátá fún ẹgbẹ́ òṣèlú Nigerian People's Party nígbà ayé rẹ̀. Wọ́n bí Adéníran ní ọjọ́ Kọkànlélógún oṣù Kíní ọdún 1918 ní agbègbè ÌkòròdúÌpínlẹ̀ Èkó sí agboolé ọmọ Ọba Sùbérù Ògúnsànyà Ògúntádé tí ó jẹ́ Ọdọ̀fin ti ìlú Ìkòròdú nígbà náà. Adéníran lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ti Hope Waddell Training Institute ní ìlú Calabar nígbà tí ó ń gbé pẹ̀lú àbúrò bàbá rẹ̀ tí ó jẹ́ òṣìṣẹ́ ìjọba ní ìlú Calaba. Ìjọba fi ẹ̀bùn ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ dá Adéníra lọ̀lá láti kàwé síwájú si ní ilé-ẹ̀kọ́ King's College tí ó wà ní Ìpínlẹ̀ Èkó látàrí bí ó ṣe peregedé jùlọ pẹ̀lú máàkì tí ó ga jùlọ nínú ìdánwò àṣekágbá ti Standard VI (6) ní ọdún 1937. Ó tẹ̀ siwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀, tí ó sì kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ òfin ní ilé-ẹ̀kọ́ fásitì ti University of Manchester àti Gray's Inn tí ó jẹ́ ilé-ẹ̀kọ́ ìmọ̀ òfin.

(ìtẹ̀síwájú...)

Iṣẹ́ọnà Onídẹ Benin


Ẹ tún wo ÌròyìnWiki ní èdè Gẹ̀ẹ́sì
Èdè