Majek Fashek
Majekodunmi Fasheke, tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Majek Fashek jẹ́ olùkọ orin, atajìtá àti olórin ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1][2] Ó di ìlú-mọ̀ọ́ká olòlórin ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní àsìkò ọdún 1988, fún àwo orin rẹ̀ tí ó gbé jáde lásìkò yí tí ó pè ní _Onígbèkùn ọkàn (Prisoner of Conscience), àti àwọn orín rẹ̀ ọlọ́kan ò jọ̀kan bíi : Send down the rain àti bẹ̀è bẹ̀è lọ tí ó gha àwọn àmì ẹ̀yẹ òmìdáni lọ́lá oríṣríṣi. [3] Ẹ̀wẹ̀, Majek ti ṣeré pọ̀ pẹ̀lú àwọn òṣèré olórin oríṣríṣi ìlú mọ̀ọ́ká bíi: Tracy Chapman, Jimmy Cliff, Michael Jackson, Snoop Dogg, àti Beyoncé.[4][5]
Majek Folabee Shamsudeen | |
---|---|
Orúkọ àbísọ | Majekodunmi Fasheke |
Ọjọ́ìbí | February 1949 Benin Edo State, Nigeria |
Irú orin | Reggae, roots reggae, rock |
Occupation(s) | singer, songwriter, actor |
Years active | early 90s—present |
Labels | Interscope Records |
Associated acts | Jastix Monicazation |
Ìbẹ̀rẹ̀ Ayé rẹ̀
àtúnṣeWọ́n bí Fashek ní ìlú Benin tí ó jẹ́ olú ìlú fún to an Ìpínlẹ̀ Edo níbi tí ìyá rẹ̀ ti wá, tí bàbá rẹ̀ sì jẹ́ ọmọ ìlú Ìjẹ̀ṣà.[1][2] Fashek yan ìlú Benin láàyò lọ́dọ̀ ìyá rẹ̀ lẹ́yìn ìgbà tí bàbá àti ìyá rẹ̀ kọ ara wọn sílẹ̀, tí ó sì dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ akọrin ìjọ Aládùúrà kan, níbintí ó kọ́ bí wọ́n ṣebń lu ìlú àti àwọn ohun èlò orin mìíràn, tí ó sì ń hun orin fún àwọn akọrin ìjọ náà.[6]
Iṣẹ́ orin rẹ̀
àtúnṣeNípa torin, a lè sọ wípé Majek ni àrólé fún olóògbé Bob Marley, nítorí gbogbo ìwọ́hùn olóògbé náà ni Fashek mú pátá.[7][8] Ó wà lára ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn ọmọ bíbí ilẹ̀ [Nàìjíríà]] tí gbé orin Reggae tí ó ti ilẹ̀ Caribbean wá. Àmọ́, kàkà kí Majek ó gbàgbé ilé àti orin ìbílẹ̀ wa pátá, ń ṣe ló mú ọnà orin bíi Fújì àti Jùjú mọ́ orin reggae tí ó sì tibẹ̀ fa ọnà orin tirẹ̀ tí ó pè ní ''Kpangolo'' yọ lọ́nà arà.[9][10]
Ikú rẹ̀
àtúnṣeMajek kú sí ojú orun rẹ̀ ní ọjọ́ kejì oṣù Kẹfà ọdún 2020 sí ìlú New York.
Àwọn Ìtọ́ka sí
àtúnṣe- ↑ 1.0 1.1 Harris, Craig. [[[:Àdàkọ:Allmusic]] "Biography – Majek Fashek"] Check
|url=
value (help). AllMusic. Retrieved 1 October 2010. - ↑ 2.0 2.1 Faosheke, John Olu (11 February 2007). "Majek Fashek's Ijeshaedo Roots Revealed". AllAfrica.com (AllAfrica Global Media). http://allafrica.com/stories/200702120313.html. Retrieved 1 October 2010.
- ↑ "Nigeria: Rainmaker, Majek Fashek Re-Ignites Hope for a Comeback". allAfrica.com.
- ↑ 40 Minutes with the Rainmaker Archived 1 October 2015 at the Wayback Machine.
- ↑ "Rainmaker, Majek Fashek Re-ignites Hope for a Comeback". Nigerian News from Leadership News.
- ↑ "Majek Fashek Tragedy: The Inside Story No One Told You #SavingMajek". Entertainment Express. 18 April 2015.
- ↑ Loder, Kurt. Rolling Stone. "Fashek's vocal and lyrical resemblance to the late Bob Marley is both eerie and earned...."
- ↑ Farber, Jim. Daily News|location=New York, 19 January 1992. "Ziggy may be Bob Marley's biological son, but Majek Fashek is his spiritual heir. In terms of vocal tone, Fashek is Marley's spitting image...."
- ↑ Pareles, Jon. The New York Times, 5 December 1990. "...a promising hybrid style, one that started in standard reggae but has added the bustling cross-rhythms of Nigerian juju and a touch of hard rock."
- ↑ "Joseph Edgar: Majek Fashek, a national tragedy". DailyPost Nigeria. 12 June 2015.