Microlophus  jẹ́ ti ìdílé àwọn alángbá Tropidurid ní Gúúsù Amẹ́ríkà. Ogún ẹ̀yà alángbá yìí ni a dámọ̀ tí mẹ́fà sì wọ́pọ̀ ní erúkùṣú Galápagos ní ibi tí wọ́n ti mọ̀ wọ́n sí àwọn alángbá àpáta[1][2] (nígbà míràn wọ́n máa ń kówọn sí àye Tropidurus). Wọ́n má ń rí àwọn tókù tí wọ́n ń pè ní Pacific iguanas, ní Andes lọ́na òkun Chile, Peru, àti Ecuador. Ìrí àwọn alángbá yìí káàkiri àti ìrísí, àwọ̀, àti ìwà tí ó yàtọ̀ ṣe àfihàn nkan tí àwọn olóyìnbo ń pè ní adaptive radiation tí ó ní ṣe pẹ̀lú àwọn tí ó ń gbé ní archipelago yìí. A ma ń rí àwọn ẹ̀yà kan ní gbogbo àárín àtí ìwọ oòrùn àwọn erékuỳṣù tí ó ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àkókó òkun lọlẹ̀ díẹ̀, tí ó sì jẹ́ pé a maa ń rí àwọn ẹ̀yà mẹ́fà kan ní eteetí àwọn erékùṣù. Ó Ṣeéṣe kó jẹ́ wípé ìran kan ní gbogbo àwọn ẹ̀yà wọ̀nyí ti wá. Síbẹ̀síbẹ̀, Tropiduridae lè pàwọdà, àwọn ẹ̀yà kan náà sí ma ń ní àwọ̀ ọ̀tọ̀tọ̀ ní ibùgbé ọ̀tọ̀tọ̀, tí wọn a sì maa ṣe àfihan àwọ̀ ọ̀tọ̀tọ̀. Àwọn ẹranko tí ó ń gbé ní àpáta dúdú maa n ní àwọ̀ dúdú ju àwọn tó ń gbe ní orí iyẹ̀pẹ̀ tí ó mọ́.

Microlophus
Microlophus albemarlensis, abo tí ó wọ́pọ̀ ní Galápagos
Ìṣètò onísáyẹ́nsì
Ìjọba:
Ará:
Ẹgbẹ́:
Ìtò:
Ìdílé:
Ìbátan:
Microlophus

Duméril & Bibron, 1837
Àwọn ẹ̀yà

bíi ogún

Àwọn ẹ̀yà

àtúnṣe
 
Akọ Microlophus delanonis tí ó wọ́pọ̀ ní Española Island
 
Microlophus occipitalis, Peru

Wọ́n tòwọ́n bí ábídí.[3] (* wọ́n wọ́pọ̀ ní àwọn erékùṣù Galapágos).

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. Fitter, J.;Fitter, D; and Hosking, D. (2000) Wildlife of the Galalpagos.
  2. Benavides,E; Baum, R.; Snell, H. M.; Snell, H. L.; and Sites, Jr., J. W. (2009) "Island Biogeography of Galápagos Lava Lizards (Tropiduridae: Microlophus): Species Diversity and Colonization of the Archipelago." Archived 2013-09-21 at the Wayback Machine. (.pdf) Evolution, 63 (6): 1606–1626.
  3. Microlophus, Reptile Database