Moi-Moi
Mọ́i-mọ́i tàbí mọ́ín-mọ́ín jẹ́ ẹ̀wà lílọ̀ sísè tí ó jẹ́ pé àwọn èròjà rẹ̀ ni ẹ̀wà bíbó, tí wọ́n sáábà sè pẹ̀lú àlùbọ̀sà, tàtàṣé (rodo,ata gígún), òróró, edé abbl.[1][2]
Alternative names | Mọin-Mọin, Mai-Mai, Olele |
---|---|
Place of origin | Yoruba (Nigeria,Benin and Togo) |
Region or state | Ìwọ̀-oòrùn. |
Àdàkọ:Wikibooks-inline
|
A tún mọ mọ́í-mọ́í sí "àlẹ̀lẹ̀" tàbí "ọ̀lẹ̀lẹ̀” ní àwọn ẹ̀ka-èdè Yorùbá mìíràn, bẹ́ẹ̀ bí àwọn ènìyàn ṣe mọ̀ ọ́ sí ní Siẹrra Léònè àti Gánà. Wọ́n sábà máa ń jẹ́ mọ́í-mọ́í pẹ̀lú ògì/kókó.[3] Tubaani (tàbí Tubani) jẹ́ irúfẹ́ oúnjẹ yìí( mọ́í-mọ́í) ní apá Àríwá ilẹ̀ Gánà.[4] Wọ́n máa ń fi gàárì, kókó, tàbí kọ́sítádì jẹ mọ́í-mọ́í náà. Ó tún jé oúnjẹ-àfikẹ́ẹ̀gbẹ́ ní àwọn ìnáwó Nàìjíríà, tí wọ́n ń fi kún ìrẹsì alésèpọ̀ àti irúfẹ́ àwọn oúnjẹ mìíràn.
Àwọn Ohun-èlò
àtúnṣeẸwà, tàtàṣé, ata rodo, òróró, tọ̀màtì (fún pípọ́n èyí kì í ṣe dandan), èdè lílọ̀ (bí ó bá ṣe tẹ́ ọ lọ́rùn), àlùbọ̀sà tó bá tó, ẹyin tàbí àwọn ẹran wẹ́wẹ́, tàbí irúfẹ́ ẹran tó bá wù yín, tàbí ẹja yíyan, tàbí ẹja aláìlégungun bíbọ̀, ìsebẹ̀/iyọ̀ àti magí, omi náà ní ìwọ̀nba.
Ìlànà Sísè
àtúnṣeNí àkọ́kọ́ ni láti rẹ ẹwà sínú omi tútù, kí èpò ara rẹ̀ lè rọrùn láti ṣí kúrò pátápátá títí tó ma fi funfun.[5] Kí o sì lọ̀ tí kò fi ní ẹ̀wà líle kankan mọ́ pẹ̀lú ẹ̀rọ-ìlọta. Nínú abọ́ fífẹ̀ tí ẹ̀wà lílọ̀ náà wá à ṣe àfikún iyọ̀, magí, edé gbígbẹ, òróró, àti àwọn ohun-èlò ìdáná mìíràn láti fun ládùn. Àwọn mìíràn máa ń fi oríṣi ẹja tàbí ẹyin, tàbí ẹran wẹ́wẹ́ sínú rẹ̀ náà.[6] Èròjà rẹ tó máa ń pọ̀ yìí, máa ń mu ki tí ó sì máa ń mu kún inú èèyàn ní ìjẹ ìtẹ́lọ́rùn. Eyi ló tún fà á tí àwọn ènìyàn ṣe máa ń pè é ní Mọ́ín-Mọ́ín ẹlẹ́ẹ̀mí méje.[7]
Moin-Moin usually comes in a slanted pyramid shape, cylindrical shape, cone shape and any targeted shape Oríṣiríṣi ìrísí tó bá wuni ni èèyàn le gé mọ́í-mọ́í sí, pẹ̀lú ohun-èlò tó tọ́ [8] ìrísí tó wọ́pọ̀ jù ni èyí tí a máa ń fi ewé ẹran[9] tàbí ewé ọ̀gẹ̀dẹ̀ yọ[10] tí wọ́n máa ń fi ewé náà sínú ihò tí wọ́n ṣù pẹ̀lú àtẹ́lẹ́ ọwọ́, tí wọ́n ma wá bú ẹwà lílọ̀ tí wọ́n ti fi èròjà pò pọ̀ sí, wọ́n sì ma pọn. Àwọn ìrísí mìíràn láti ara pípọ́n sínú àwọn agolo olóríṣi ìrísí ni wọ́n ti máa ń yọ wọn. Lẹ́yìn pípọ́n sínú àwọn ewé tàbí àwọn agolo wọ̀nyí, wọ́n ma tò wọ́n sí inú abọ́-ìdáná pẹ̀lú omi ìdá ìlàjì abọ́-ìdáná náà, láti se mọ́í-mọ́í náà jìnà pẹ̀lú oru omi náà. Wọ́n máa ń jẹ́ mọ́í-mọ́í lásán tàbí pẹ̀lú búrẹ́dì, pẹ̀lú ìrẹsì tàbí ògì fún oúnjẹ àárọ̀ tàbí oúnjẹ alẹ́. Wọ́n tún lè lò ó pẹ̀lú gàárì gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ ọ̀sán. Wọ́n ti sọ mọ́í-mọ́í di ìrọ̀rùn nípa títa ẹwà gbẹrẹfu ní àwọn ilé ìtajà, tí ó jẹ́ pé a kò ní ma rẹ ẹ̀wà ṣókí mọ́ tàbí lo agbára láti ma bo, kí a ti yí pọ̀ mọ́ omi àti àwọn èròjà rẹ̀ tí a ti dárúkọ ṣáájú.
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "The thriving 'Moi-moi' business in Nigeria". 22 March 2022.
- ↑ "Nigeria", The World Factbook (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì), Central Intelligence Agency, 2022-08-23, retrieved 2022-08-28
- ↑ "NEWS". miczd.gov.gh. Archived from the original on 2020-06-06. Retrieved 2020-06-07.
- ↑ Osseo-Asare, Fran; Baeta, Barbara (2015). The Ghana Cookbook. New York: Hippocrene Books. ISBN 978-0-7818-1343-3. OCLC 896840053.
- ↑ "Best Moi-moi recipe". 11 November 2020.
- ↑ "Moin-Moin". 13 April 2010.
- ↑ "Moin-Moin". 13 April 2010.
- ↑ "The Nigerian Moi-Moi". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2017-07-21. Archived from the original on 2022-07-23. Retrieved 2022-07-23.
- ↑ Iwalaiye, Temi (2021-12-17). "What should you use to wrap moi-moi?". Pulse Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-07-23.
- ↑ "Moi Moi Wrapped In Banana leaves Recipe by UmmiAbdull". Cookpad (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-07-23.