Tafa Balogun
Mustafa Adebayo Balogun tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Tafa Bologun ni wọ́n bí ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n oṣù kájọ, ọeún 1947 ni ó jẹ́ Ọlọ́pá, ó sì di adarí pátá pátá ìkọkanlá fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá Nàìjíríà ní inú oṣù kẹta ọdún 2002. Àmọ́ wọ́n fi ẹ̀yìn rẹ̀ ti ní tipá tipá ní inú oṣù kínní ọdún 2005 látàrí ìwà ẹ̀sùn àjẹbánu tó gogò. Ó ṣaláìsí ní ọjọ́ kẹrin oṣù kẹjọ 2022.
Mustafa Adebayo Balogun | |
---|---|
11th Inspector General of Police | |
In office March 2002 – January 2005 | |
Asíwájú | Musiliu Smith |
Arọ́pò | Sunday Ehindero |
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | Ila Orangun, Colony and Protectorate of Nigeria | 25 Oṣù Kẹjọ 1947
Aláìsí | 4 August 2022 | (ọmọ ọdún 74)
Occupation | Police officer |
Ìtàn rẹ̀ ní ṣókí
àtúnṣeBalógun lọ sílé ẹ̀kọ́ University of Lagos, Ó kàwé gboyè nínú ìmọ̀ ìṣèlú ní ọdún 1972. Ó darapọ̀ mọ́ ilé iṣẹ́ Nigeria Police Force ní oṣù Karùn-ún ọdún 1973, ó tẹ̀ síwájú láti kẹkọ̀ọ́ gboyè nínú ìmọ̀ òfin nílé ẹ̀kọ́ in University of Ibadan ní ọdún 2973. Lẹ́yìn tí ó ti ṣiṣẹ́ káàkiri ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ó di igbákejì ọ̀gá àgbà àti adarí àwọn ọlọ́pá pátá pátá ní Muhammadu Gambo, kí ó tó di igbákejì fún adarí àgbà fún àwọn ọlópá ní Ìpínlẹ̀ Edo. Lẹ́yìn èyí ni ó di adarí àgbà yányán fún àwọn ọlópá ní Ìpínlẹ̀ Delta, Ìpínlẹ̀ Rivers àti Ìpínlẹ̀ Abia. Ó di igbákejì adari àgbà yányán fún àwọn ọlópá ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà(A.I.G) ní ọjọ́ kẹfà oṣù kọkànlá ọdún 2005. nígbà tí ó wà ní Ìpínlẹ̀ Kano.[1][2] Ní inú oṣù kọkànlá ọdún 2001 lẹ́yìn tí Tafa di A.I.G tán ni Balógun kéde rẹ̀ wípé ààbò àrà -ọ̀tọ̀ yóò wà fún àwọn alówólódù bí ìyèré tí wọ́n jẹ́ oníṣòwò jànkàn-jànkàn ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà pẹ̀lú àgbékalẹ̀ àwọn ọlọ́pá tí wọ́n pe ní Diplomatic Corp and Foreign National Protection Unit.[3]
Gẹ́gẹ́ bí ọ̀gá àgbà Ọlọ́pá (IGP)
àtúnṣeBalógun di rìpẹ́tọ̀ àgbà fún àjọ ọlọ́pá IGP nínú oṣù kẹta ọdún 2002, lẹ́yìn tí ó gbapò lọ́wọ́ ọ̀gá rẹ̀ Musiliu Smith.[4] Tàfá ni ó ṣe akóso ètò ààbò fún orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní abala tọ̀dọ̀ ọlọ́pá, ó sì pèsè àbò fún ètò ìdìbò nínú oṣù kẹrin ọdún 2003 tí wọ́n jábọ̀ ìhùwà burúkú àwọn ọlọ́pá tó gbojikan.[5] Nínú oṣù kẹjọ ọdún 2003, Balógun sọ̀rọ̀ ìta gbangba lórí Rògbòdìyàn inú ètò ìdìbò àti ààbò orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ibí yìí ni ó ti sọ̀rọ̀ nípa bí ó ṣe yẹ kí ẹnìkọ̀ọ̀kan óní káàdì ìdánimọ̀, ìdánilẹ́kọ̀ọ́ gbogbo gbòò, ìṣàtúntò sí òfin ìdìbò, ìkópa aráàlú nínú ìṣèlú àti ìjọba tó dúró o re àti agbékalẹ̀ ilé ẹjọ́ tí ó ń bójú tó òfin.[6] Balógun tún ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn ọlópá akẹgbẹ́ rẹ̀ lórí bí wọn yóò ṣe mú ètò lele lásìkò ìpàdé ìgbìmọ̀ọ̀ Commonwealth of Nations. [7] Ní ọdú́n 2004, Tàfá tọrọ àforíjìn lọ́wọ́ àwọn oníròyìn tí àwọn ọlọ́pá hùwà àbùkù sí pẹ̀lú bí wọ́n ṣe lu àwọn oníròyìn tí wọ́n si ba irinṣẹ́ àkáàlẹ̀ fọ́rán iṣẹ̀lẹ̀ oríṣiríṣi, ó sì ṣèlérí wípé irú ìhùwàsí bẹ́ẹ́ kòní ṣọmọ lọ́wọ́ àwọn mọ́. [8] Nígbà tí ọdún 2004 yóò fi parí, onírúurú ìwé-ìròyìn ni ó gbé àpilẹ̀kọ oríṣiríṣi nípa ìwà àjẹ̀bánu nípa gbígba owó-ẹ̀yìn lọ́wọ́ àwọn olóṣèlú àti àwọn ọ̀bàlújẹ́ tí Balógun ń hù àti àwọn tí ó ti hù sẹ́yìn. Àwọn ẹ̀sùn wọ̀nyí ni ó ṣokùnfàá tí wọ́n fi fi ẹ̀yìn rẹ̀ tì ní tipá tipá nínú oṣù kínní ọdún 2005.[2]
Ìfi kélé òfin gbé e
àtúnṣeNí ọjọ́ kẹrin oṣù kẹrin ọdún 2005,wọ́n fi ṣìnkún òfin gbé Tàfá Balógun lọ siwájú ilé-ẹjọ́ tí ó ga jùlọ nílú Àbújá fún ẹ̀sùn ìfẹ̀yìn pín owó ìlú tí ó tó bílíọ́nù mẹ́tàlá lọ sílẹ̀ òkèrè.[9] Àjọ Economic and Financial Crimes Commission lábẹ́ àkóso Nuhu Ribadu tún fi ẹ̀sùn àádọ́rin mìíràn kan Balógun fún ìwà ìbàjẹ́ rẹ̀ tó hù láàrín ọdún 2002 sí ọdún 2004.[10] Ó bẹ̀bẹ̀ fún ifojú àánú woni kí wọ́n jẹ́ kí òun fi gbogbo dúkìá òun jìn fún ìjìyà òun.[11] Ilé-ẹjọ́ sọ Tàfá sí ẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́fà.[12] Wọ́n da sílẹ̀ ní ọjọ́ kẹsàn án oṣù kejì ọdún 2006lẹ́yìn tí ó pari ẹ̀wọn rẹ̀ tí ó ṣe púpọ̀ rẹ̀ ní ilé ìwòsàn ti Àbújá. [13] Ní inú oṣù kọkànlá ọdún 2008 àti oṣù kejì ọdún 2009, Alága tó ń rí sí ayédáádé àwọn ọlópáọ́pá fún ilé-ìgbìmọ̀ aṣojú ṣòfin àgbà, ìyẹn Abdul Ahmed Ningi, bèèrè lọ́wọ́ ọ̀gá agbà yányán fún àwọn ọlópá Mike Okiro, wípé kí ó wá sọ bí owó tí wọ́n gbà lọ́wọ́ Tàfá Balógun jà sí gẹ́gẹ́ bí Alága tuntun fún àjọ EFCC , Abilékọ Farida Waziri. Nítorí wípé àwọn EFCC fi léde wípé àwọn kò rí owó náà gbà sọ́wọ́ lẹ́yìn tí wọ́n sọ wípé wọ́n ti gbowó náà lọ́wọ́ Balógun.[11] Ọ̀Rọ̀ tún jẹ jáde wípé wọ́n ti ta àwọn dúkìá tí wọ́n gbà ní gbanjo lábẹ́nú fún púpọ̀ nínú àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà.[14] Bákan náà ní ọdún 2009, Alága tó ń rí sí ayédáádé àwọn ọlọ́pá fún ilé-ìgbìmọ̀ aṣojú ṣòfin àgbà, tún ránṣẹ́ pe Tàfá Balógun,Mike Okiro àti Abilékọ Farida Waziri kí wọ́n wá tẹnu jẹ́wọ́ ṣàlàyé ohun tí wọ́n mọ̀ nípa bílíọ́nù mẹ́rìdínlógún tí wọ́n gbà lọ́wọ́ Tàfá Balógun ṣe pòórá.[15] Tàfá Balógun kú ní ọjọ́ kẹrin oṣù kẹjọ ọdún 2022.[16]
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "The Rise And Fall of Tafa Balogun". Segun Toyin Dawodu. 26 November 2005. Retrieved 27 September 2009.
- ↑ 2.0 2.1 "TAFA BALOGUN A DIFFERENT SUPER 'SPECIAL' COP". Nigeria World. 9 February 2005. Archived from the original on 17 December 2007. Retrieved 27 September 2009.
- ↑ "Nigerian police bid to reassure investors". BBC News. 14 November 2001. Retrieved 27 September 2009.
- ↑ Mobolaji E. Aluko, PhD (31 January 2005). "IGP Sunday Ehindero and My 7-Task Challenge". DAWODU. Retrieved 1 November 2009.
- ↑ "Patterns of election violence". Human Rights Watch. June 2004. Retrieved 29 September 2009.
- ↑ Tafa Balogun (6 August 2003). "Nigeria: Electoral Violence and National Security". ACE Electoral Knowledge Network. Retrieved 27 September 2009.
- ↑ "Nigeria on high alert over summit". BBC News. 4 December 2003. Retrieved 27 September 2009.
- ↑ "Reporters Without Borders Annual Report 2004 – Nigeria". UNHCR. Retrieved 27 September 2009.
- ↑ "Tafa Balogun in cuffs, faces 70 fraud charges". Guardian. 4 April 2005. Retrieved 27 September 2009.
- ↑ Ekundayo, Kayode; Lagos (31 December 2017). "Where is Tafa Balogun?". Daily Trust (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 22 January 2020.
- ↑ 11.0 11.1 "Uncertainty over Tafa Balogun's loot". The News Planetario. 24 May 2009. Archived from the original on 14 July 2011. Retrieved 27 September 2009. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "CORRUPTION: DPS ALAMIEYESEIGHA AND TAFA BALOGUN SAGA". Democratic Socialist Movement (DSM). Nov–Dec 2005. Retrieved 27 September 2009.
- ↑ "So Tafa Balogun is a free man?". OnlineNigeria. 16 February 2006. Retrieved 27 September 2009.
- ↑ "EFCC, Police in dilemma over Tafa Balogun's loot Our hands are clean – EFCC Spokesman". National daily. 22 May 2009. Archived from the original on 4 October 2009. Retrieved 27 September 2009. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "Tafa, Okiro, Waziri to Face House C'ttee". Office of the Speaker, House of Representatives. 24 April 2009. Archived from the original on 24 July 2011. Retrieved 27 September 2009.
- ↑ "Obituary: Tafa Balogun, ex-IGP dies, aged 74". 4 August 2022. https://sundiatapost.com/obituary-tafa-balogun-ex-igp-dies-aged-74/.