Reloaded (fíìmù ọdún 2009)
Reloaded jẹ́ fíìmù ọdún 2009 ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó jẹ́ mọ́ eré-ìfẹ́, èyí tí Lancelot Oduwa Imasuen àti Ikechukwu Onyeka darí. Lára àwọn akópa fíìmù náà ni Ramsey Nouah, Rita Dominic, Desmond Elliot, Stephanie Okereke, Ini Edo àti Nse Ikpe-Etim.[1][2] Wọ́n yàn án fún àmì-ẹ̀yẹ mẹ́ta ní ayẹyẹ Africa Movie Academy Awards ẹlẹ́ẹ̀karùn-ún.[3]
Reloaded | |
---|---|
Fáìlì:Reloaded poster.jpg | |
Adarí |
|
Olùgbékalẹ̀ | Emem Isong |
Àwọn òṣèré | |
Orílẹ̀-èdè | Nigeria |
Èdè | English |
Àwọn akópa
àtúnṣe- Ramsey Nouah bí i Femi
- Desmond Elliot bí i Osita
- Rita Dominic bí i Chelsea
- Stephanie Okereke bí i Weyinmi
- Ini Edo bí i Tayo
- Van Vicker bí i Bube
- Uche Jombo bí i Tracy
- Nse Ikpe-Etim bí i Omoze
- Monalisa Chinda bí i Abbey
- Enyinna Nwigwe bí i Edwin
- Mbong Amata (née Odungide) bí i Nira
- Temisan Isioma Etsede bí i Otis
- Emeka Duru bí i Gabriel
- Princess Anazodo bí i ìyá Bube
- Ahmed Aitity bí i Shola
- Martha Iwoo bí i Ifeyinwa
- Ikechukwu Onyeka bí i Doctor
Ìgbàwọlé
àtúnṣeNollywood Reinvented fún fíìmù yìí ní ìṣèdára mẹ́ta nínú márùn-ún. Àwọn tó ṣe àríwísí sí fíìmù yìí sọ ọ́ di mímọ̀ pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ti wo fíìmù náà lọ́pọ̀lọpọ̀ ìgbà, kò ì sú àwọn.[4] NollywoodForever fún ní ìgbóríyìn 93%. Wọ́n ṣe ìgbóríyìn púpọ̀ fún fíìmù yìí nítorí àhúnpọ̀ ìtàn àti ijó tí wọ́n jó kẹ́yìn nínú rẹ̀.[5]
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Nollywood starts gets Reloaded". bellanaija.com. Retrieved 15 April 2014.
- ↑ "Emem and Lancelot again in Reloaded". nigeriafilms.com. Retrieved 15 April 2014.
- ↑ "Film Review: Reloaded". Retrieved 15 April 2014.
- ↑ "Reloaded on NR". nollywoodreinvented.com. Retrieved 15 April 2014.
- ↑ "Reloaded Review". nollywoodforever.com. Archived from the original on 16 April 2014. Retrieved 15 April 2014.