The CEO (fíìmù 2016)

The CEO jẹ́ fíìmù ilẹ̀ Nàìjíríà ti ọdún 2016, èyí tí Kunle Afolayan darí, tí àwọn òṣèré bí i Kemi Lala Akindoju, Hilda Dokubo, Jimmy Jean-Louis, Angélique Kidjo àti Wale Ojo kópa nínú. Ìṣàfihàn àkọ́kọ́ ti fíìmù naà wáyé ní Eko Hotels and Suites, ní ọjọ́ kẹwàá oṣù keje ọdún 2016.[1] Wọ́n ṣàfihàn fíìmù náà ní Toronto International Film Festival. Ìṣàfihàn àkọ́kọ́ ti London wáyé ní oṣù kẹwàá ọdún 2016, ní Leicester Square Vue Cinema.[2]

The CEO
Fáìlì:The CEO movie poster.jpg
Theatrical poster
AdaríKunle Afolayan
Àwọn òṣèré
OrinKulanen Ikyo
Ìyàwòrán sinimáDawid Pietkiewicz
OlóòtúLaja Adebayo
Ilé-iṣẹ́ fíìmùGolden Effects
Déètì àgbéjáde
  • Oṣù Kàrún 4, 2016 (2016-05-04)
Àkókò105 minutes
Orílẹ̀-èdèNigeria

Àwọn akópa

àtúnṣe

Àhunpọ̀ ìtàn

àtúnṣe

Àwọn òṣìṣẹ́ márùn-ún tó dára jù lọ ni wọ́n rán láti lọ fún ọlúde kan, wọ́n sì sọ ọ́ di mímọ̀ pé wọ́n máa yan ẹnìkan láti jẹ́ CEO tuntun láàárín wọn. Ìbáṣepọ̀ tó dán mọ́rán tẹ́lẹ̀ wá di èyí tó soríkodo, wọ́n sì ri gẹ́gẹ́ bí ìdíje láti ṣe ju ohun ti ẹnìkejì wọn bá ṣe lọ.

Ìgbàwọlé

àtúnṣe

Chioma Nwanna ti BellaNaija ṣe ìgbóríyìn fún fíìmù náà, àwọn akópa àti agbègbè tí wọ́n ti ya fíìmù náà. Ó sọ ọ́ nínú àfikún rè pé èdè tí wọ́n sọ lẹ́nu gan-an kúnjú òṣùwọ̀n, èyí tí ó ti ọwọ́ Tade Ogidan wá. Ó tẹ̀síwájú láti sọ wípé Wale Ojo àti Nico Panagio tí wọ́n ṣe ẹ̀dá-ìtàn "Kola Alabi" àti Riikard Van Outen ṣe àgbéjáde ẹ̀dá-ìtàn tí wọ́n fún wọn. Ó sì tún ṣàkíyèsi pé bí Afolayan ṣe ń lo èdè púpọ̀ níń fíìmù náà tún bu ẹwà kún un.[3]

Chidumga Izuzu ti Pulse Nigeria ṣe àfikún tirẹ̀ pé "... ó jẹ́ fíìmù tó le gan-an tí ò fún ọ̀pọ̀lọp òǹwòran ní ohun tí wọ́n ń fé". Ó sì parí rẹ̀ pé fíìmù yìí lè má jẹ́ iṣẹ́ Afolayan tó dára jù lọ àmọ́ ó ṣe fíìmu náà dáadáa.[4][5]

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. Adedayo, Showemimo (July 10, 2016). "Kunle Afolayan’s ‘CEO’ movie to premiere in Lagos today". TheNet.ng. 
  2. Soars, Tonia (October 29, 2016). "Kunle Afolayan, Angelique Kidijo, Wale Ojo And More At The CEO Movie London Premiere". 360nobs.com. Archived from the original on August 13, 2020. Retrieved February 15, 2024. 
  3. Nnanna, Chioma (July 31, 2016). "Chioma Nnanna Reviews Kunle Afolayan’s New Movie ‘The C.E.O". Bellanaija. 
  4. Izuzu, Chidumga (July 25, 2016). "Kunle Afolayan's "The CEO" isn't a conventional Nollywood movie". Pulse.ng. 
  5. admin (March 5, 2017). "THE FILM BLOG: THE CEO AND A TRIP TO JAMAICA WERE SHUT OUT FROM THE AMVCAS AND WE COULDN’T BE MORE PLEASED". YNaija.com.