Ugali ní Malawi àti Zambia
Nsima jẹ́ oúnjẹ kan tí a ṣe láti ara ìyẹ̀fun àgbàdo funfun àti omi, ó sì jẹ́ oúnjẹ tí ó rọrùn láti jẹ ní Zambia (nsima/ubwali) àti ní Malawi (nsima).[1]
Ìyẹ̀fun àgbàdo ni a máa kọ́kọ́ sè pẹ̀lú omi gbígbóná láti sọ ọ́ di àsáró,[2] àti, ní Zambia, wọ́n máa fi sílẹ̀ fún ìsẹ̀jú díẹ̀ láti sè kí wọ́n ó tó rò ó papọ̀, láti le jẹ́ kí ó le pẹ̀lú fífi ìyẹ̀fun sí i. Ìgbésẹ̀ yìí ni yóò fún ẹni tí ó fẹ́ ṣe oúnjẹ yìí ní àǹfààní láti ro káàkiri inú kòkò ìdáná pẹ̀lú ṣíbí (nthiko ní Malawi, m'tiko/umwiko ní Zambia) kánmọ́kánmọ́ bí ó ṣe wà ní orí iná. Lẹ́yìn tí wọ́n bá sè é tán ni wọ́n máa kọ nshima/nsima pẹ̀lú ìgbákọ èyí tí a ṣe pẹ̀lú igi/ike èyí tí a tì bọ inú omi tàbí òróró tí à ń pè ní chipande (Malawi), àti chipampa (Zambia). Ní Malawi ọ̀kọ̀ọ̀kan òkèlè yìí ni à ń pè ní ntanda.[2]
A sáábà máa ń jẹ Nsima pẹ̀lú àwọn oúnjẹ kéékèèké mìíràn. Èyí lè jẹ́ mushroom bíi kabansa, tente, chitondo, àti ichikolowa; àti àwọn ẹran bíi, màálù, adìẹ, ẹja, ẹ̀pà, chikanda, t[ẹ̀wà]]; àti àwọn ẹ̀fọ́ bíi ewé pumpkin, ewé ẹ̀wà, ìgbá funfun èyí tí a mọ̀ sí impwa ní Zambia, ewé amaranth, ewé Mustard, cabbage, abbl. Ní Zambia, àwọn oúnjẹ tí a lè jẹ mọ́ ọ̀n ni à ń pè ní ndiyo ní Nyanja/Chewa àti umunani ní èdè Bemba. Ndiwo ní Malawi túmọ̀ sí àwọn oúnjẹ a-ṣe-ara-lóore àti ẹ̀fọ́ tí ó túmọ̀ sí masamba. Àwọn oúnjẹ a-ṣe-ara-lóore yìí máa ń wà ní ipò ọbẹ̀.Ní orílẹ̀-èdè Malawi àti Zambia, wọ́n sáábà máa ń jẹ nsima pẹ̀lú ẹja gbígbẹ (utaka, Malawi) tàbí àwọn ẹ̀fọ́ gbígbẹ. Bẹ́ẹ̀ ni a máa ń lo oríṣiríṣi ata láti jẹ nshima.
Oúnjẹ yìí jẹ́ èyí tí wọ́n máa ń fi ọwọ́ jẹ, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n máa ń jókòó yí oúnjẹ yìí ká lórí tábìlì tàbí ní orí ẹni ní ilẹ̀ẹ́lẹ̀ láti jẹ.
Nsima jẹ́ oúnjẹ tí owó rẹ̀ kò wọ́n bẹ́ẹ̀ sì ni kò gun ni lápá rárá, bí ó tilẹ̀ jẹ́ iye tí wọ́n ń ta oúnjẹ yìí máa ń yí padà látàrí ètò ọrọ̀ ajé tí kò fi ẹsẹ̀ múlẹ̀.
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Nsima". CooksInfo (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-05-29.
- ↑ 2.0 2.1 "Nsima: The staple food of Malawi". experiencemalawi.com. Archived from the original on 6 May 2015. Retrieved 7 May 2015. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help)