Oúnjẹ Funge
Funge tàbí fúngi ní orílẹ̀-èdè (Angola) tàbí mfundi (Congo - DCR àti Congo Republic) jẹ́ oúnjẹ ìbílẹ̀ àwọn ará ilẹ̀ Áfíríkà, ó jẹ́ òkèlè èyí tí a ṣe láti ara ìyẹ̀fun ẹ̀gẹ́, a máa ń sè é nípa fífi omi gbígbóná rò ó papọ̀. Bákan náà ni a le ṣe é láti ara sorghum, àgbàdo, tàbí Jéró. A le jẹ ẹ́ pẹ̀lú àwọn ẹ̀fọ́, ẹja, tàbí ẹran. Funge jẹ́ oúnjẹ kan tí ó gbajúgbajà nínú àwọn oúnjẹ ilẹ̀ Áfíríkà. Bẹ́ẹ̀ ni a le pè é ní bidia (èyí tí túmò sí "oúnjẹ ").[1]
Funge jẹ́ oúnjẹ tí a máa ń fi ọwọ́ jẹ́, bẹ́ẹ̀ ni òkèlè kan oúnjẹ yìí sì le bá onírúurú ọbẹ̀ lọ.
Funge jẹ́ oúnjẹ ìbílẹ̀ àwọn ará orílẹ̀ èdè Angola. Ní Lesser Antilles, irúfẹ́ oúnjẹ yìí kan jẹ́ èyí tí à ń pè ní fungi tàbí cou-cou.
Ní orílẹ̀ èdè Ghana, oríṣi ẹ̀yà oúnjẹ yìí méjì ni ó wà, èyí tí a máa ń ṣe láti ara àgbàdo, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn oúnjẹ yìí tí a mọ̀ sí banku èyí jẹ́ ohun tí a máa ń pèsè láti ara ẹ̀gẹ́ àti àgbàdo. A máa jẹ́ kí àgbàdo tí a fẹ lò ó rọ̀ díẹ̀ kí á tó sè é, láti se banku àwọn èlò tí a ti fi sílẹ̀ kí wọ́n ó rọ̀ ni a máa sè nínú kòkò ìdáná, ṣùgbọ́n láti se ẹ̀yà kejì tí a mọ̀ sí kenkey, a máa ń bọ̀ ọ́ ni kí á tó yí i mọ ewé ọ̀gẹ̀dẹ̀ tí a fi máa pọ́n ọn.
Ní orílẹ̀ èdè Brazil, oúnjẹ kan fara pẹ́ oúnjẹ yìí, èyí tí a máa ń ṣe pẹ̀lú ìyẹ̀fun ẹ̀gẹ́ àti ẹja, oúnjẹ yìí ni a mọ̀ sí pirão.[2]
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Ashkenazi, Michael; Jacob, Jeanne (2006). The World Cookbook for Students. Greenwood. p. 24.
- ↑ "Pirão | Traditional Porridge From Brazil". TasteAtlas. Retrieved 2022-10-04.