Àkójọpọ̀ awon ayẹyẹ ọdún ìbílẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà

ojúewé àtojọ Wikimedia

Àwọn ayẹyẹ ọdún ìbílẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, nínú èyí tí ọ̀pọ̀ nínú wọn máa ń tọ́ka sí àkókò tí ó ṣáájú kí àwọn ẹ̀sìn tí wọ́n gbajúgbajà ní àwùjọ wa lákòókò yìí ó tó dé. Ayẹyẹ ọdún àwọn ọmọlẹ́yìn Kírísítì [1][2] àti ayẹyẹ ọdún àwọn Mùsùlùmí jẹ́ èyí tí wọ́n máa ń ṣe lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tàbí ọ̀nà tí ó jọjú sí àwọn ènìyàn ibẹ́.[3] Àjọ tí ó ń rí sí ìdàgbàsókè ètò ìrìnàjò afẹ́ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà (Nigerian Tourism Development Corporation) ti ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn Ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti jẹ́ kí wọn ó mọ ìwúlò àti ipa pàtàkì tí àwọn ayẹyẹ ọdún ìbílẹ̀ máa ń kó, tí ó sì le jẹ́ ọ̀nà kan pàtàkì tí wọn á fi máa rówó láti ara ètò irinajo afẹ́.[4] Ayẹyẹ ọdún ìbílẹ̀ tí ó ń bẹ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lé ní ọ̀tà-lé-márùn-ún lélọ́ọ̀ọ́dúnrún (365), gẹ́gẹ́ bí Mínísítà tí ó ń rí sí ètò ìròyìn àti àṣà, ọ̀gbẹ́ni Lai Mohammed ti sọ, àti pé ìjọba ń ṣa apá wọ́n làti mú kí ìdàgbàsókè ó bá àwọn àṣà wa láti jẹ́ kí àwọn àgbáyé ó mọ bí a ṣe ní àwọn onírúurú àṣà ìbílẹ̀. [5][6]

Àtòjọ àwọn àjọ̀dún ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà

àtúnṣe
 
Adekunle Gold Performing at Felabration

Àjọ̀dún Ìwé

àtúnṣe

Àjọ̀dún Fíìmù ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà

àtúnṣe


Àjọ̀dún Orin ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà

àtúnṣe


Àjọ̀dún àṣà ìbílẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà

àtúnṣe


Àwọn mìíràn

àtúnṣe

Ayẹyẹ ọdún àwọn ọmọlẹ́yìn Kírísítì

àtúnṣe

Christians jẹ́ ìdá àádọ́ta àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, tí wọ́n ń gbé káàkiri gbogbo ìlú ṣùgbọ́n tí wọ́n pọ̀ sí ẹkùn gúúsù orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[19] Àwọn ọdún àwọn ọmọlẹ́yìn Kirisiti ni ọdún Kérésìmesì (Christmas) àti ọdún àjíǹde (Easter).[20][21] Ọ̀nà tí wọ́n máa ń gbà ṣe ọdún yìí máa ń ṣe àkósínú àwọn ìlànà ẹ̀sìn ìṣàájú.[3]

Wọ́n máa ń ṣe ọdún Kérésìmesì ni gbogbo ọjọ́ kẹẹ̀dọ́gbọ̀n, oṣù kejìlá gbogbo ọdún, láti fi ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí Jésù (Jesus Christ).[22] It is a public holiday in Nigeria.[23][24] Ní ilẹ̀ àwọn Igbo, sí àfikún ètò ìjọsìn àti ẹ̀bùn híhá, ọdún náà máa ń ṣe àfihàn Mmo ijó egúngún, níbi tí àwọn ọ̀dọ́ á ti wọ aṣọ aláràǹbarà àti àwọ̀sójú. Ijó yìí máa ń tọ́ka sí ìgbà tí ẹ̀sìn kìrìsìtẹ́nì wọlé dé àti láti fi yẹ́ ẹ̀mí àwọn baba-ńlá wọn sí.[25] Ní àwọn àgbègbè kan, wọ́n máa ń lo ìmọ̀ ọ̀pẹ láti fi kọ́ gbogbo inú ilé, èyí jẹ́ àmì fún àlàáfíà àti àmì ọdún Kérésìmesì. [26] Wọ́n máa ń ṣe ọdún àjíǹde láti fi bí wọ́n ṣe kan [Jésù]] mọ́ àgbélébùú ní ọjọ́ Ẹtì àti bí ó ṣe jí dìde ní ọjọ́ Àìkú. Ọjọ́ tí ó bá bọ́ sí máa ń jẹ́ ọjọ́ ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[23] Wọ́n sáábà máa ń ṣe ọdún Àjíǹde nínú oṣù kẹrin ọdún.[27] Ayẹyẹ ọdún àjíǹde jẹ́ ọdún àjọyọ̀ àti alárinrin, tí wọ́n máa ń ṣe pẹ̀lú ijó jíjó àti ìlú lílù.[28] Àwẹ̀dá gbígbà máa ń ṣáájú àjọyọ̀ èyí tí a mọ̀ sí àwẹ̀ Lẹ́ǹtì. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo àwọn ẹlésìn yìí ni wọ́n máa ń ṣe ọdún yìí, ṣùgbọ́n àwọn kan a máa ṣe é tọkàntọkàn.

Ayẹyẹ ọdún Kérésìmesì àti Àjíǹde le jẹ́ ìgbà tí ó lọ́ jàì láàárín àwọn ẹlésìn kìrìsìtẹ́nì àti àwọn Mùsùlùmí ní àwọn agbègbè kan. Ní ọjọ́ ọdún Kérésìmesì ti ọdún 2010, àwọn ènìyàn bíi méjìdínlógójì ni wọ́n rán lọ́run. Àwọn oníjà ẹ̀sìn Boko Haram ni wọ́n di ẹ̀bi àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà rù.[29] Àwọn ìròyìn kan jábọ̀ ikú àwọn ènìyàn tó tó Ọgọ́rin. [30] Ní ọdún 2011, ayẹyẹ Àjíǹde wáyé lẹ́yìn ètò ìdìbò Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà níbi tí Goodluck Jonathan ti jáwé olúborí. Onírúurú àwọn ilé-ìjọsìn àwọn ọmọlẹ́yìn Kirisiti ni wọ́n dáná sun ní ẹkùn Àríwá orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, tí wọ́n sì pa àwọn ẹlésìn kìrìsìtẹ́nì nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó sẹ̀ lẹ́yìn ètò ìdìbò. [31][32]

Àjọ̀dún àwọn Mùsùlùmí

àtúnṣe

Bíi ìdá sí méjì àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní wọ́n jẹ́ Mùsùlùmí, tí wọ́n ń gbé káàkiri àwọn ìletò tó ń bẹ nínú ìlú náà,pàápàá jùlọ ní ẹkùn Àríwá orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ìdá mọ́kàndínlógójì ni wọ́n jẹ́ Mùsùlùmí, ìdá àádọ́ta jẹ́ kìrìsìtẹ́nì, tí ìdá tó kú ń ṣe ẹ̀sìn mìíràn. [33] Ayẹyẹ ọdún méjì ni àwọn Mùsùlùmí máa ń ṣe; ọdún ìtúnu àwẹ̀ àti ọdún iléyá. Tí àwọn àkókò méjèèjì yìí jẹ́ àkókò ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. [34][23] Onírúurú àwọn ẹ̀yà ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni wọ́n máa ń ṣe àwọn ọdún yìí bákan náà. [3]

Ayẹyẹ ọlọ́jọ́ mẹ́ta ti ìtúnu àwẹ̀ jẹ́ àjọyọ̀ fún píparí àwẹ̀, èyí tí wọ́n máa ń gbà láti ìgbà tí àlìfájàrí bá ti yọ títí tí Òòrùn yóò fi wọ̀. Àkókò yìí jẹ́ ìgbà tí wọ́n máa ń fún àwọn aláìní àti ọmọ òrukàn ní nǹkan, tí wọ́n sì máa ń ṣe àjọyọ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́, ẹbí àti ará. [35]

 
Bida Emirate durbar festival, 2001

Ọdún iléyá jẹ́ ọdún tí wọ́n máa ń ṣe káàkiri àgbáyé, èyí tí ó sọ ìtàn bí Ànọ́bì Abraham (ʾIbrāhīm) ṣe fẹ́ fi ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo Íṣímáẹ́lì jọ́sìn fún Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bíi ìbọ̀wọ̀ àti ìgbàgbọ́ tí ó ní sí Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n tí Ọlọ́run padà bá a fi àgbò dìrọ̀ ẹ̀mí ọmọ rẹ̀. Àwọn Mùsùlùmí a máa pa àgbò, ewúrẹ́, àgùntàn, màálù, tàbí ràkúnmí fún ọdún iléyá tí wọ́n á sì pín àwọn ẹran yìí fún àwọn aláìní láwùjọ. Wọ́n máa ń ṣe ọdún yìí ní ọjọ́ kẹwàá, oṣù Kejìlá kọ́jọ́dá àwọn Mùsùlùmí.[36][37]

Ayẹyẹ ọdún Durbar jẹ́ èyí tí wọ́n máa ń ṣe ní àkókò ọdún ìtúnu àwẹ̀ àti ọdún iléyá.[38] ayẹyẹ Durbar ni wọ́n ti ṣe ní àìmọye ọdún ní àwọn Ìpínlẹ̀ tí wọ́n wà ní Àríwá orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí a mọ̀ wọ́n sí Daura Emirate, ó máa fún àwọn ọmọ ológun láàyè láti pidàn oríṣiríṣi. Ní àwọn ìgbà kan sẹ́yìn wọ́n máa ń ṣe ọdún yìí nípa lílọ sí ọ̀dọ̀ àwọn olórí ìlú tí àwọn ẹlẹ́ṣin yóò sì fi ẹṣin wọn pitu oríṣiríṣi.[4] Modern Durbar festivals include prayers at the start of the day, followed by parades in town squares or in front of the local emir's palace. Horsemanship is still the main focus. Each group must gallop at full tilt past the Emir, then halt and salute him with raised swords.[39] Durbar festivals are being developed as important tourist attractions.[40] Ní àsìkò àjàkâlẹ̀ ààrùn COVID-19 ní àwọn ìlú, àwọn Ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan ní Àríwá orílẹ̀-èdè Nàìjíríà pinu láti fi ètò náà rọ̀ sí ibìkan láti bọ̀wọ́ fún òfin àti ìlànà kíkó ara ẹni jọ, bí a ti mọ̀ pé ọdún yìí máa ń fa èrò káàkiri àgbáyé wá.[41][42][43][44]

Ọdún Káyó-Káyó

àtúnṣe

Ayẹyẹ ọdún yìí jẹ́ ọdún àṣà àti ẹ̀sìn èyí tí wọ́n máa ń ṣe ní ọdọọdún. Àwọn àrọ́mọdọ́mọ Ọba Kòsọ́kọ́ ni wọ́n máa ń ṣe ọdún yìí fún ìrántí bí ọba yìí ṣe tẹ̀dó sí Epe ní ọdún 1851.[45][46] Wọ́n mọ àwọn ará Ẹ̀pẹ́Ìpínlẹ̀ Ékó (Lagos State) fún ọdún Káyó-Káyó, èyí tí ó túmọ̀ sí pé "kí á jẹun tí a fi máa yó." Wọ́n máa ń ṣe ọdún yìí ní ọjọ́ kẹwàá oṣù kìíní kọ́jọ́dá àwọn Mùsùlùmí, èyí tí ó jẹ́ oṣù kan lẹ́yìn ọdún iléyá àwọn Mùsùlùmí.[47][48][49]

 
2021 Parade

Ayẹyẹ ọdún Ojúde Ọba

àtúnṣe

Ojúde Ọba jẹ́ ayẹyẹ ìsẹ̀m̀báyé, tí àwọn Mùsùlùmí tí wọ́n ń bẹ ní Ijebu Ode, agbègbè kan ní Ìpínlẹ̀ Ògùn (Ogun State), ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà máa ń ṣe. Wọ́n máa ń ṣe ọdún yìí ní ọdọọdún ní ọjọ́ kẹta ọdún iléyá àwọn Mùsùlùmí, láti ṣe ìbọ̀wọ̀ fún Ọba Awujalẹ tí ìlú Ijebul. Ó jẹ́ ọdún tó lààmìlaaka tí ó sì gbajúmọ̀ ní ìlú Ìjẹ̀bú àti jnní gbogbo Ìpínlẹ̀ Ògùn (Ogun State) pátá.[50][51]

Ó jẹ́ ayẹyẹ ọlọ́jọ́ kan, níbi tí àwọn onírúurú ẹgbẹ́ àṣà ìbílẹ̀ tí a mọ̀ sí (regberegbe), àwọn ọmọ ìlú, àwọn ọ̀rẹ́ àti ojúlùmọ̀ nítòsí àti ibi tí ó jìnnà yóò ti wá ṣe eré ní ojúde ọba ní ọjọ́ kẹta ọdún àwọn Mùsùlùmí tí a mọ̀ sí ọdún iléyá.[52][53] Ọba Adétọ̀nà ni ó kó àwọn ẹlẹ́gbẹ́ àṣà padà wá ní sẹ́ńtúrì kejìdínlógún (18th century).[51]

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "Christian Festivals and Holy Days | University of Bolton". www.bolton.ac.uk. Archived from the original on 2022-12-10. Retrieved 2022-12-10.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  2. "THE MAJOR FESTIVALS OF CHRISTIANITY". academic.brooklyn.cuny.edu. Retrieved 2022-12-14. 
  3. 3.0 3.1 3.2 "Festivals in Nigeria". Online Nigeria. Retrieved 2011-04-26. 
  4. 4.0 4.1 Oxford Business Group. "Patchwork of Celebration". The Report: Nigeria 2010. Oxford Business Group. p. 243. ISBN 1-907065-14-8. https://books.google.com/books?id=VFONkYzHco8C&pg=PA243. 
  5. Jeremiah (2018-12-04). "FG To Produce Compendium Of Cultural Festivals – Minister". Leadership News - Nigeria News, Breaking News, Politics and more (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2021-08-03. 
  6. "Nigeria Compiling List of Festivals Nationwide To Boost Tourism – Minister". Independent Newspaper Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 4 December 2018. Retrieved 2021-08-03. 
  7. vanguard (2012-10-24). "Port Harcourt: Festival of book from World Book Capital". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-12-14. 
  8. "Lagos Book & Art Festival | LABAF | .....Dubbed Africa' Largest Culture Picnic." (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2022-12-14. Retrieved 2022-12-14. 
  9. "Kaduna Book & Arts Festival" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-12-14. 
  10. "Ake Arts & Book Festival – Ake Arts & Book Festival" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-12-14. 
  11. Okondo, 0odwin (23 August 2020). "Nigeria international book fair goes virtual". The Guardian. https://guardian.ng/art/nigeria-international-book-fair-goes-virtual/. 
  12. "Obi lauds young writers for preserving Achebe's literary legacies". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2023-11-19. Retrieved 2024-05-12. 
  13. "ABUJA INTERNATIONAL FILM FESTIVAL". FilmFreeway (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-12-14. 
  14. "Home". Afriff (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-12-14. 
  15. "EKOIFF". EKOIFF (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-12-14. 
  16. "Home". African Smartphone International Film Festival (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-12-14. 
  17. "Home". Village Arts & Film Festival (VILLAFFEST) (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-10-24. 
  18. "Dallas-based filmmaker, Kelechi Eke brings VILLAFFEST to Owerri". Vanguard (Nigeria). October 24, 2020. https://www.vanguardngr.com/2020/10/dallas-based-film-maker-kelechi-eke-brings-villaffest-to-owerri/. 
  19. "Nigeria: People: Religions". CIA World Factbook. CIA. Retrieved 2011-05-27. 
  20. "Easter: FG declares Friday, Monday April 2, 5 public holidays". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2021-03-31. Retrieved 2021-08-03. 
  21. "Yuletide: FG declares December 25, 28; January 1 public holidays". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2020-12-23. Retrieved 2021-08-03. 
  22. "FG declares public holidays for Christmas, New Year". Punch Newspapers (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2020-12-23. Retrieved 2021-08-03. 
  23. 23.0 23.1 23.2 "Nigeria Public Holidays 2018". Q++ Studio. Retrieved 2018-07-22.  Note: the url changes every year
  24. "Public Holidays in Nigeria". NigeriaCalendar.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 
  25. Ifeoma Onyefulu (2007). An African Christmas. frances lincoln ltd. p. 7. ISBN 978-1-84507-421-0. https://books.google.com/books?id=NQPi_hy8YTIC&pg=PT7. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
  26. Arlene Erlbach; Herb Erlbach; Sharon Lane Holm (2002). Merry Christmas, Everywhere!. Lerner Publications. p. 38. ISBN 0-7613-1699-X. https://books.google.com/books?id=N3ucntTNcvMC&pg=PA38. 
  27. "Easter Sunday Dates". GM Arts. Retrieved 2011-04-27. 
  28. "Holidays". Motherland Nigeria. Retrieved 2011-04-26. 
  29. "Christmas Eve Attacks in Nigeria Kill at Least 38". Voice of America. 25 December 2010. Retrieved 2011-04-26. 
  30. Ethan Cole (December 29, 2010). "Nigeria Christmas violence death toll rises to 80". Christian Post. Retrieved 2011-04-26. 
  31. OPEYEMI AGBAJE (27 April 2011). "Innocent blood at Easter". BusinessDay. Archived from the original on 28 September 2011. Retrieved 2011-04-27.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  32. Safiya Akau (8 April 2012). "25 killed in Easter Sunday bombing in northern Nigeria". CNN. Retrieved 2021-08-03. 
  33. "Mapping out the Global Muslim Population" (PDF). The Pew Forum. October 2009. Archived from the original (PDF) on 2010-01-13. Retrieved 2011-04-27.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  34. "Eidel-Kabir: FG declares Tuesday, Wednesday Public Holidays". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2021-07-15. Retrieved 2021-08-03. 
  35. "Muslims in Nigeria Celebrate Ed-el-Fitri". Channels TV. September 10, 2010. Archived from the original on July 20, 2011. Retrieved 2011-04-26.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  36. "Happy Eid-El-Kabir". Vanguard. 17 November 2010. Retrieved 2011-04-26. 
  37. "The meaning behind Eid al-Fitr and how it is celebrated". inews.co.uk (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2021-05-12. Retrieved 2021-08-03. 
  38. "Eidul-Fitr: Kano Emirate to hold Sallah durbar". Daily Trust (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 10 May 2021. Retrieved 2021-08-03. 
  39. "The Durbar Festival". World Reviewer. Archived from the original on 2011-04-05. Retrieved 2011-04-26. 
  40. "Gani-Durbar Festival". Borgu Kingdom. Archived from the original on 2011-03-11. Retrieved 2011-04-26.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  41. "COVID-19: Kano suspends Durbar during Sallah". Latest Nigeria News, Nigerian Newspapers, Politics (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2021-07-19. Retrieved 2021-08-03. 
  42. "Eid-el-Kabir: Kwara Govt bans 2021 durbar in Ilorin" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2021-07-21. Retrieved 2021-08-03. 
  43. "Insecurity: Daura Emirate Cancels Sallah Durbar Celebration". Channels Television. Retrieved 2021-08-03. 
  44. "Jigawa suspends Sallah durbar". Daily Trust (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 19 July 2021. Retrieved 2021-08-03. 
  45. "Culture feast in Epe as Kayokayo Festival holds". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2019-09-25. Retrieved 2021-08-31. 
  46. "Kayokayo Festival begins in Epe". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2017-10-16. Retrieved 2021-08-31. 
  47. "Culture feast in Epe as Kayokayo Festival holds". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2019-09-25. Retrieved 2021-08-30. 
  48. "Ambode to open Epe's famous Kayokayo festival". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2016-10-14. Retrieved 2021-08-31. 
  49. Rapheal (2022-09-08). "Kayokayo Festival… Epe re-enacts Oba Kosoko's arrival, 171 years after". The Sun Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-12-30. 
  50. "Everything You Need To Know About the Ojude-Oba Festival". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2017-09-01. Retrieved 2021-08-31. 
  51. 51.0 51.1 Anifowose, Titilayo (2020-05-01). written at Lagos, Nigeria. "Cultural Heritage and Architecture: A Case of Ojude Oba in Ijebu Ode South-West, Nigeria". International Journal of Advances in Scientific Research and Engineering (University of Lagos Akoka Nigeria) 6 (5): 74–81. doi:10.31695/IJASRE.2020.33808. 
  52. People, City (2018-07-30). "IJEBU Age Grade Groups Prepare For 2018 OJUDE OBA". City People Magazine (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2021-08-31. 
  53. "Ojude Oba Festival". Ogun State Government Official Website (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2021-08-02. Retrieved 2021-08-31.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
Àṣìṣe ìtọ́kasí: <ref> tag with name "ArgentEmbassy" defined in <references> is not used in prior text.

Àdàkọ:Music festivals