Ìfipá Gba Maersk Alabama

Ìfipá Gba Maersk Alabama jẹ́ àtẹ̀léra ìṣẹ̀lẹ̀ orí omi tì ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ajalèlókun mẹrin tí wọ́n fi ipá gba ọkọ̀ ojú omi ẹ̀lẹ́rù, MV Maersk Alabama igbalélógójì máìlí (440 km; 280 mi) gúúsù-ìlàoòrùn Eyl, Somalia. Ìdíwọ́ yìí parí lẹ̀yin akitiyan  Ológun Ojú Omi fún Àwọn Ìpínlẹ̀ Aṣọ̀kan Amẹ́ríkà lati gbàwọn sílẹ̀.[1] Ó jẹ́ àkọkọ́ àṣeyọrí ìfipá gba ọkọ̀ ojú omí tí yio ṣelẹ̀́̀ lati bíi ọ̀kànlélógun ọgọrún ọdún sẹ́yìn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìyábọ̀ ìròyìn jẹ́ kó di mímọ̀ wípé irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ tó ṣẹlẹ̀ kẹ́yìn wáyé ní ìgbà Ogun Barbary Kejì ní ọdún 1815, b́ótilẹ̀jẹ́ wípé irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ti wáyé bí ọdún 1821 sẹ́yìn.[2]  Ó jẹ́ ìkẹfà ọkọ̀ ojú omi ẹ̀lẹ́rù, tí àwọn ajalèlókun tí wọ́n ṣẹ̀sẹ̀ gba owó ìdásílẹ̀  rọgùrọ́gù mílíọnù dọ́là máa dojú kọ.

Ìfipá Gba Maersk Alabama

Ọkọ̀ ojú-omi agbanilà lati Maersk Alabama lórí ọkọ̀ ojú omi fún ẹ̀ri
Ìgbà Ọjó kẹjọ sí Ọjó kejìlá Oṣù kẹrin Ọdún 2009
Ibùdó máìlì ogójìlénígba kúrò sí Somalia
Àbọ̀ Améríkà ṣẹ́gun
  • wọ́n ṣẹ́gun ajalèlókun
  • ọwọ́ tẹ Abduwali Muse
  • wọ́n gba ènìyàn tí wọ́n mú fún pàṣípààrọ̀ sílẹ̀
Àwọn agbógun tira wọn
àwọn ajalèlókun Somalia
Àwọn apàṣẹ
Abduwali Muse Àdàkọ:Surrendered
Agbára
Òfò àti ìfarapa
None
  • àwọn mẹta kú
  • wọ́n mú ènìyàn kan
  • wọ́n mú ènìyàn kan fún pàṣípààrọ̀

Ìtàn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí di àkọsílẹ̀ ní 2010 nínú ìwé  A Captain's Duty: Somali Pirates, Navy SEALs, and Dangerous Days at Sea tí Stephan Talty àti Captain Richard Phillips tí wọ́n jẹ́ ọ̀gá nínú ọkọ̀ yìí nígbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀ kọ́. ìfipá gbà ọkọ̀ yìí tún jẹ́ ìwúrí fún eré Captain Phillips tí wọ́n ṣe ní ọdún 2013.

 
MV Maersk Alabama ní Oṣù kẹrin Ọdún 2009.

Ìfipá gba náà

àtúnṣe

Ọkọ̀ náà pẹ̀lú àwọn atukọ mẹ́tàlélógún gbé ẹrù tí ó tó tọ́ọ̀nú 17,000 kọrí sí Mombasa, Kenya lẹ́yìn tí wọ́n dúró níDjibouti Ní Ọjọ́ kẹjọ Oṣù kẹrin Ọdún 2009, àwọn ajalèlókun mẹrin tí ó dá lórí FV Win Far 161 dojúkọ ọkọ̀ yìí.[3][4][5] Ọjọ́ orí gbogbo àwọn ajalèlókun mẹ́ẹ̀rin wà láàrín mẹ́tàdínlógún sí ọ̀kàndínlógún, gẹ́gẹ́ bí Akọ̀wé  olùgbèjà U.S. Robert Gates ti ṣàlàyé.[6] Àwọn ẹgbẹ́ atukọ̀  Maersk Alabama yìí ti gba ẹ̀kọ́ tẹ́lẹ́ lórí bí aṣelè dojú kọ àwọn ajalèlókun tí wọ́n t sì ti ṣe ìdárayá ológun kí wón tó bọ́ sínú ọkọ̀ ní ọjọ́ kan tẹ́lẹ̀. Ẹ̀kọ́ tí wọ́n fún wọn pẹ̀lú bí wọ́n ṣe lè lo ohun ìjà kékeré, ìdojúkọ ìbẹ̀rù, ẹ̀kó nípa ewu ìrànlọ́wọ́ àkọ́kọ́ fún ẹni tí ó bá farapa, àtí àwọn ẹ̀kó tó jẹmọ́ ààbò.[7][8] Nígbà tí ìtanijí àwọn ajalèlókun yìí dún ní Ọjọ́ kẹjo Oṣù kẹrin, Olóyè Ẹlẹrọ Mike Perry kó àwọn atukọ̀ mẹ́rìnlá sí "yàrá ààbò" tí àwọn àwọn ẹlẹrọ tí ń gbìyànjú àti ṣètò fún irú nkan bẹ́ẹ̀. Bí àwọn ajalèlókun yìí ṣe súmọ́ wọn, àwọn atukọ̀ tókù yin àwọn iná kan sí wọn. Pẹ̀lú èyí, Perry àti A/E Àkọ́kọ́ (Olùrànlọ́wọ́ Ẹlerọ) Matt Fisher yí nkan lára ọkọ̀ ojú yìí tí o sí fẹ́ si ojú ọkọ̀ ajalèlókun yìí dé.[9] Láìfòtápè, wọ́n wọnú ọkọ̀ náà. Perry tí kọ́kọ́ wà ní ìṣàkóso yàrá ẹ̀rọ àti pé A/E Àkọ́kọ́ Matt Fisher ti wà ní ìṣàkóso ìdarí jíà. Perry panọ́ mọ́ ọkọ̀ lẹ́nu gbogbo ọkọ̀ náà "sí ṣókùnkùn". Àwọn ajalèlókun yìí mú Captain Richard Phillips àti ọ̀pọ̀lọpọ àwọn ẹgbẹ́ atukọ̀ láìpẹ́ sí ìgbàtí àwọn ajalèlókun wọnú ọkọ̀ náà, ṣùgbọ́n wón ri wípé wọn kó lè darí ọkọ̀ náà mọ́.

Perry dúró sí iwájú yàrá ààbò pẹ̀lú ọbẹ lọ́wọ́, tí ó sì ń dúró de àwọn ajalèlókun tí wọ́n n wá àwọn ẹgbẹ́ atukọ̀ lati gba ṣakóso ọkọ̀ lọ̣́wọ́ wọ́n pẹ̀lú ìgbàgbọ́ pé wọn á wa ọkọ̀ náà lọ sí Somalia. Perry dojú ìjà kọ ọ̀gá àwon ajalèlókun lẹ́yìn tí ó lée mú nínú òkùnkùn ní yàrá ẹ̀rọ. Ọ̀gá àwon ajalèlókun yìí, Abduwali Muse gé ara rẹ̀ lọ́wọ́ nibi tí ó ti n gbìyànjú lati yọ ọ̀bẹ tí Perry fi síi lọ́rùn. Wọ́n di ajalèlókun yìí, Second Mate Ken Quinn sì tọ́jú egbò rẹ̀.[10] Láìpẹ́, lẹ́yìn tí ó jìyà nínú yàrá ààbò tó móoru yìí fún wákàtí púpọ̀, àwọn atukọ̀ gbìyànjú àti ṣe pàṣípààrọ̀ ajalèlókun tí wọ́n mú pẹ̀lú ọ̀gá ọkọ̀ tí ajalèlókun mú ṣùgbọ́n pàṣípààrọ̀ yìí jásí pàbó, lẹ́yìn tí àwọn atukọ̀ fí ajalèlókun tí wọ́n mú sílẹ̀, àwọn ajalèlókun kọ lati tẹ̀lé àdéhùn. Captain Phillips sin àwọn ajalèlókun wọ ọkọ̀ ojú-omi agbanilà lati fi bí wọ́n ṣe ń wàá hàn wọ́n, ṣùgbọ́n àwọn ajalèlókun fúò sínú ọkọ̀ ojú-omi agbanilà pẹ̀lú Phillips fún owó ìdásilẹ̀

Àwọn àkíyèsí

àtúnṣe
  1. Sanders, Edmund; Barnes, Julian E. (9 April 2009). "Somalia pirates hold U.S. captain". Los Angeles Times. http://articles.latimes.com/2009/apr/09/world/fg-somali-pirates9. Retrieved 12 April 2009. 
  2. McShane, Larry (8 April 2009). "Americans take back cargo ship Maersk Alabama after it was hijacked by Somali pirates". New York Daily News. http://www.nydailynews.com/news/us_world/2009/04/08/2009-04-08_somali_pirates_seize_usflagged_cargo_ship_with_21_american_sailors_says_diplomat.html. Retrieved 8 April 2009. 
  3. Huang-chih, Chiang (7 September 2009). "Does the Ministry of Foreign Affairs care about 'Win Far'?". Taipei Times. http://www.taipeitimes.com/News/editorials/archives/2009/09/07/2003452966. 
  4. "Somali pirates hijack Danish ship". BBC news. 8 April 2009. http://news.bbc.co.uk/2/hi/africa/7989474.stm. Retrieved 8 April 2009. 
  5. "Ship carrying 20 Americans believed hijacked off Somalia". CNN. 9 April 2009. http://www.cnn.com/2009/WORLD/africa/04/08/ship.hijacked/index.html. Retrieved 9 April 2009. 
  6. "Somalian pirate suspect arrives in New York to be tried in U.S. court". CBC News. 20 April 2009. http://www.cbc.ca/news/world/story/2009/04/20/us-somaliapirate.html. Retrieved 12 August 2013. 
  7. Another Miracle Brought to You By America's Unions (This Time With Pirates!
  8. "AFL-CIO NOW BLOG | Union Crew Avoids Pirate Takeover, But Ship's Captain Held Hostage". Archived from the original on 2009-04-14. Retrieved 2016-06-07. 
  9. Cummins, Chip; Childress, Sarah (16 April 2009). "On the Maersk: 'I Hope if I Die, I Die a Brave Person'". The Wall Street Journal. http://online.wsj.com/article/SB123984674935223605.html. Retrieved 16 April 2009. 
  10. "Don't Give Up the Ship! Quick Thinking and a Boatload of Know-How Saves the MAERSK ALABAMA". The Marine Officer. Summer 2009. http://mebaunion.org/WHATS-NEW/The_Real_Story_of_the_MAERSK_ALABAMA.pdf. Retrieved April 2009.