Aderounmu Adejumoke
Adéjùmọ̀kẹ́ Adéróunmú jẹ́ òṣèré ọmọ Nàìjíríà kan, tí a bí ní Abẹ́òkúta, Ìpínlẹ̀ Ògùn Nàìjíríà, níbití ó ti ní ilé-ìwé alákọ́bẹ̀rẹ̀ àti ilé-ìwé gíga. Orúkọ rẹ́ tàn dáada jùlọ fún ṣíṣeré ipa gẹ́gẹ́ bi Esther àti Kelechi nínu àwọn gbajúmọ̀ eré Tẹlifíṣọ́nù Nollywood tí n ṣe Jenifa's Diary àti Industreet. Bákan náà, ó kópa gẹ́gẹ́ bi Jummy Adams nínu eré Nollywood aláṣeyọrí kan tí n se Alákadá 2 lówun pèlú Fúnkẹ́ Akíndélé, Tóyìn Abraham, Odúnladé Adékólá, Linda Ejiofor, Falz, Juliana Oláyọ̀dé, Ọmọ́túndé Adébọ̀wálé David (Lolo) àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.
Adejumoke Aderounmu | |
---|---|
Ìbí | Abeokuta, Ipinle Ogun, Nàìjíríà |
Iṣẹ́ | Osere Itage, Olugberejade |
Ó kọ́kọ́ rí ìdánimọ̀ gẹ́gẹ́ bi "Yéjídé" nínu fiimu Túndé Kèlání, Dazzling Mirage ti ọdún 2014 pèlú àjọsepọ̀ Kúnlé Afọláyan, Kémi Lala Akíndójú, Taiwo Ajai-Lycett, Ṣeun Akíndélé àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.
Ìbẹ̀rẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀
àtúnṣeA bí Adéjùmọ̀kẹ́ sínu ìdílé èléyàn máàrún ní Oṣù Kẹẹ̀ta, Ọjọ́ kerìndínlọ́gbọ̀n, ní àwọn ọdún 80 ní ilé-ìwòsàn tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ "Sacredhearts" ní ìlu Abẹ́òkúta, Ìpínlẹ̀ Ògùn, Nàìjíríà.
Adéjùmọ̀kẹ́ lọ sí àwọn ilé-ìwé aládáni St Banerdettes ní ìlú Ibara, Abẹ́òkúta; Abeokuta Girls 'Grammar School, Onikolobo, Abẹ́òkúta; ṣáájú kí ó tó lọ láti gba Oyè ẹ̀kọ́ nínu ìmọ international relations láti Yunifásitì Obáfẹ́mi Awólọ́wọ̀, Ilé-Ífẹ̀, Ìpínlẹ̀ Ọ̀sun. Ó tún gba ìfọwọ́sí nínu ṣíṣe fiimu láti La Cinefabrique multimedia Cine ní ìlu Lyon, òrílẹ̀-èdè Faransé ní ọdún 2017 lẹ́hìn tí ó gba ẹ̀bun síkọ́láṣípù ti Ford Foundation ní bi ayẹyẹ Africa International Film Festival ní ìpaŕi ìkẹ́ẹ̀kọ́ rẹ fún filmu ṣíṣe, èyí tí DSLR ṣe fún àwọn ọ̀dọ́ oní fiimu ti Nàìjíríà ní ọdún 2016. Ó bẹ̀rẹ̀ eré ṣíṣe gẹ́gẹ́ bi akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ lẹ́hìn àyẹ̀wò Túndé Kèlání fún fiimu Arugbá ní ọdún 2008 níbi tí ó ti kó ipa Ọmọọba Mobándélé pèlú àjọṣepọ̀ Bukky Wright, Bùkọ́lá Awóyẹmí, Sẹ́gun Adéfilá àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.[1]
Iṣẹ-iṣe
àtúnṣeAdéjùmọ̀kẹ́ rí ìdánimọ̀ ní ọdún 2016 fún aṣíwájú ipa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi Esther nínu eré Tẹlifíṣọ́nù aláwàdà kan tí àkọ́lé rẹ̀ n jẹ́ Jenifa's Diary.[2] Adéjùmọ̀kẹ́ Adéróunmú ti kópa nínu fiimu tó lé ní méwa (lédè Gèésì àti lédè Yorùbá) gẹ́gẹ́bi òṣèré. O ṣiṣẹ ìgbóhùn sáfẹ́fẹ́ ní ilé-iṣẹ́ ìdánilárayá "Goldmyne Presenter" fún eré Tẹlifíṣọ́nù aláṣeyọrí kan lábẹ́ ìṣàkóso Daniel Ademinokan ní ọdún 2010/2011. Bákan náà, ó ṣiṣẹ́ ní Radio Concert (ilé-iṣẹ́ Rédíò orí ayélujára kan ní Nàìjíríà ) láti ọdún 2012 títí di 2015. Lẹ́hìn náà, Ó tẹ̀síwájú láti ṣe apá kíní eré rẹ̀ tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ The Lounge with Jumoke, eŕe ìdárayá kan tí ó ní àwọn ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò àti àwọn ìmọ̀ràn ìtúnrase, ní ọdún 2012.[3]
Àwon àṣàyàn eré rẹ̀
àtúnṣe- Industreet (2017)[4]
- The Ex (2015)
- Jenifa's Diary (2016)
- Alakada 2 (2013)
- Wings of My Dreams (2013)
- Dazzling Mirage (2014)
- The Unwritten 1&2 (2009)
- Patriots TV series (2008)
- Arugbá (2008)
Àwọn ẹ̀bùn àti àwọn yíyàn
àtúnṣe- A yàn fún òṣèré tí ó dára jùlọ ní bi ayẹyẹ fiimu káríayé ti Afíríkà ní Dallas, ìlu Texas (2016)
- A yàn fún Ìfihàn ọdún, níbi àwọn ẹ̀bun BON, Nàìjíríà (2015)
- Olúborí ti ẹ̀bun MayaAfrica 4.0 Ojú tuntun ti Nollywood (2016)
- Olúborí ti ẹ̀bun Scream Ojú tuntun ti Nollywood (2017)
Ìgbésí ayé ara ẹni
àtúnṣeAdéróunmú kò lọ́kọ kò sì tíì ní àfẹ́sọ́nà tàbí kó lọ́kọ rí.[1]
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ 1.0 1.1 "My stature prevents me from getting roles – Jumoke Aderounmu" (in en-US). Punch Newspapers. http://punchng.com/stature-prevents-getting-roles-jumoke-aderounmu/.
- ↑ "Esthers in Jenifa's Diary". onobello.com. Archived from the original on 2020-10-24.
- ↑ Aderounmun, Adejumoke (7 October 2017). "Consistency, hard work and talent have brought me where I am today – Adejumoke Aderounmun" (Interview). Interview with Tobi Awodipe. The Guardian Nigeria. Archived from the original on 19 May 2018. Retrieved 18 May 2018.
- ↑ "Industreet Full Cast and Crew" (in en-GB). https://nlist.ng/title/industreet-703/credits/.