Ilà kíkọ nílẹ̀ Yorùbá

Ilà kíkọ nílẹ̀ Yorùbá jẹ́ kíkọ tàbí fífa ìlà sí ojú, orí, apá tàbí itan gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà kan pàtàkì tí àwọn Yorùbá ń gbà láti ṣe ọ̀ṣọ́, dá ara wọn mọ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ gẹ́gẹ́ bí àṣà àti ìṣe. [1]

Èère Ọọ̀ni Ifẹ̀ ní sẹ́ńtúrì kejìlá/kẹtàlá tó kọlà
Arákùnrin tó kọlà ní ọdún 1940

Ìwúlò Ilà

àtúnṣe

Kókó ilà kíkọ nílẹ̀ Yorùbá ni kí wọ́n lè mọ ènìyàn mọ́ ìdílé rẹ̀ ní gbogbo ibi tí ó bá lọ.[2][3] Ilà yí lè jẹ́ ti ìdílé Ìyá tàbí ti Bàbá àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, ti ìdílé bàbá ni wọ́n sábà ba ń kọ fún ọmọ.[4][5] Lára Ìwúlò Ilà tún ni láti fi ṣe ọ̀ṣọ́ tàbí ṣe ara lóge àti lọ́jọ̀.[6][7] Wọ́n tún máa ń lo Ilà láti fi so ẹ̀mí ẹ̀mí ọmọ àbíkú ró kí ó má ba kú tàbi padà sọ́dọ̀ àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ mọ́. Bí ó bá tilẹ̀ gbìyànjú láti padà, tàbí àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ wá mu tipá-tipá ilà yí ni yóò jẹ́ kí wọ́n kọ̀ọ́ sílẹ̀, nítorí ilà náà yóò dúró gẹ́gẹ́ bí àmì tí yóò jẹ́ kí irúfẹ́ ọmọ náà ó yàtọ̀.[8]

Àwọn Orílẹ̀-èdè tí ilà kíkọ ti wọ́pọ̀

àtúnṣe

Àṣà ilà kíkọ wọ́pọ̀ láàrin àwọn ènìyàn

Oríṣi ìlà

àtúnṣe
 
Oríṣi ilà

Ilà pélé ni ilà mẹ́ta-mẹ́ta sórí ẹ̀kẹ́ kọ̀ọ̀kan. [9]

Pélé pé oríṣi mẹ́ta, àwọn ni ; Pele Ife, èyí wọ́pọ̀ láàárín àwọn ará Ilé-Ifẹ̀. Pélé Ìjẹ̀bú àti Pélé Ìjẹ̀ṣà. Gbogbo rẹ̀ pátá ló rí bákan náà.[10]

Òwu ni ilà mẹ́fà lórí ẹ̀kẹ́ kọ̀ọ̀kan, tó sì wọ́pọ̀ láàárín àwọn ará Òwu, tó jẹ́ ọ̀kan lára ìlú tó gbajúmọ̀ ní Abẹ́òkúta, ẹ̀ka Ìpínlẹ̀ Ògùn. Olóyè Olúṣẹ́gun Ọbásanjọ́ kọ ilà Owu

Gò̩mbó̩

àtúnṣe

Ilà Gọmbọ ni a tún mọ̀ sí kẹkẹ. Kẹkẹ ni ilà bíi ókan àti ilà tó wọ́ tí wọ́n kọ sí ẹ̀kẹ́ kọ̀ọ̀kan. Àwọn ará Ògbómọ̀ṣọ́Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ni ó sáábà máa ń kọ ilà yìí.

Àbàjà

àtúnṣe

Àbàjà máa ń jẹ́ ilà méjìlá, mẹ́fà ló máa ń wà ní ẹ̀kẹ́ kọ̀ọ̀kan. Èyí máa ń wọ́pọ̀ láàárín àwọn Oyo. [11] Òun sì ni ọba Lamidi Adeyemi III, tó fìgbà kan jẹ́ Aláàfin Ìlú Ọ̀yọ́ [12] Àwọn ilà mìíràn ta ní ní èdè Yorùbá ni Ture, Mande, Bamu àti Jamgbadi.[13][14]

Orúkọ àwọn èèyàn ìlú-mọ̀n-ọ́n-ká tí wọ́n kọlà

àtúnṣe

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. Lefèber, Yvonne; Henk W. A. Voorhoeve (1998). Indigenous Customs in Childbirth and Child Care. Guinevere Van Gorcum. p. 53. ISBN 9023233662. https://books.google.co.uk/books?id=7Y0bCWpg-U8C&pg=PA53. 
  2. Orie (2011), p. 1.
  3. Chioma, Gabriel (18 October 2014). "Marked for life? Are your tribal marks attractive or repulsive?". Vanguard News. Retrieved 3 June 2015. 
  4. Orie (2011), p. 1.
  5. Chioma, Gabriel (18 October 2014). "Marked for life? Are your tribal marks attractive or repulsive?". Vanguard News. Retrieved 3 June 2015. 
  6. Usman, A., & Falola, T. (2019). The Nineteenth Century: Wars and Transformations. In The Yoruba from Prehistory to the Present (pp. 159-240). Cambridge: Cambridge University Press.
  7. "Nigeria Country of Origin Information (COI) Report" (PDF). 2013. 
  8. Lefèber, Yvonne; Henk W. A. Voorhoeve (1998). Indigenous Customs in Childbirth and Child Care. Guinevere Van Gorcum. p. 53. ISBN 9023233662. https://books.google.com/books?id=7Y0bCWpg-U8C&pg=PA53. 
  9. "Killed by modernity". realnewsmagazine.net. Retrieved 12 April 2016. 
  10. Abraham Ajibade Adeleke Ph. D.; Abraham Ajibade Adeleke (February 2011). Intermediate Yoruba: Language, Culture, Literature, and Religious Beliefs. Trafford Publishing. pp. 174–. ISBN 978-1-4269-4909-8. https://books.google.com/books?id=DSwJCton8GgC&pg=PA174. 
  11. Hucks, Tracey E. (16 May 2012). Yoruba Traditions and African American Religious Nationalism. UNM Press. ISBN 978-0826350770. https://books.google.com/books?id=T5v11UywUbwC&pg=PT198. 
  12. Ibironke, Amanda (23 January 2014). "The Yoruba Tibal Marks". The Voice. Archived from the original on 21 May 2015. Retrieved 19 May 2015.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  13. Mayaki, Victoria Ozohu (5 March 2011). "Nigeria: Tribal Marks – Our Lost Heritage". All Africa. Retrieved 19 May 2015. 
  14. Nigeria, Hyve (2017-12-29). "‘Tribal marks, our identity, our pride’". News, Live-Stream and Amusement - Hyve Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-07-18. 

Àwọn orísun

àtúnṣe