Kàbà jẹ́ ìlú kan tí ó wà ní inú ìpínlẹ̀ Kogi ní apá ìwọ̀ Oòrùn orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ìlú yí wà ní ẹ̀bá odò Ọ̀sẹ́ tí ó súnmọ́ ojú ọ̀nà tí ó ń bọ̀ láti ìlú Lọ́kọ́ja, Okene, Ogidi, Ado-Ekiti àti ìlú Ẹ̀gbẹ̀. [1] It is 511 kilometers from Lagos.[2]

Kabba
Kabba is located in Nigeria
Kabba
Kabba
Kabba shown within Nigeria
Coordinates: cities7°50′00″N 6°04′00″E / 7.83333°N 6.06667°E / 7.83333; 6.06667Coordinates: 7°50′00″N 6°04′00″E / 7.83333°N 6.06667°E / 7.83333; 6.06667
CountryNàìjíríà Nàìjíríà
StateKogi State
Area
 • Total330 km2 (130 sq mi)
Time zoneUTC+1 (WAT (UTC+1))
National languageYorùbá

Ìtàn Ìwàṣẹ̀ àti ìmú lẹ́rú

àtúnṣe

Nígbà ìwáṣẹ̀, ìlú kàbà jẹ́ ìlú amọ́nà Bida Emirate, lábẹ́ ìṣàkóso àwọn Fúlàní, Àwọn ọmọ ogun Bida lábẹ́ àkóso àwọn Fúlaní a máa kógun ja àwọn ẹ̀yà míràn tí wọn a sì ma mú wọn lẹ́rú. Lásìkò tí àwọn òyìnbó àmúnisìn ṣì ń jẹ gàba, wọ́n pín kàbà sí ọ̀nà mẹ́rin, tí wọ́n sì gbé ilé-ẹjọ́ ti ìgbàlódé ti ìjọba gẹ̀ẹ́sì àti ti ìbílẹ̀ náà kalẹ̀ fún ètò ìdájọ́ tó pinmirin. Ìjọba gẹ̀ẹ́sì dá àgọ́ ọlọ́pá sí ibi tí ó di ojúnà Lokoja lónìí.[3]

Bí ìlú náà ṣe rí

àtúnṣe

Kàbà jẹ́ ojúkò fún kọfí, kòkó, iṣus, ẹ̀gẹ́, àgbàdo, ọjà bàbà, òrí, ẹ̀pà, ẹ̀wàs, òwú àti aṣọ híhun ilẹ̀ Yorùbá àti Ebira. Àwọn ènìyàn Kàbà a màá ń sọ ẹ̀ka èdè Yorùbá tí wọ́n ń pè ní Owé.

Ìlú Kàbà ni ó ń ṣe akóso ìjọba ìbílẹ̀ Kabba/Bunnu ní Ìpínlẹ̀ Kogi. Ẹni tí ó jẹ́ adarí fún ìjọba ìbílẹ̀ náà ni Hon.E. O. Olorunleke Moses. Ìjọba alákòóso Kàbà pín sí mẹ́ta, àwọn: Obaro, Obadofin àti Obajemu. Obaro ni ó jẹ́ alákòóso tí ó wà nípa Ọba. Obaro tí ó wà nipò lọ́wọ́ yii ni Oba Solomon Owoniyi (Obaro Oweyomade 1), ẹni tí ó gorí àpèrè ní ọdún 2018 lẹ́yìn tí Oba Michael Olobayo (Obaro Ero Il) wàjà.[4] Ààfin rẹ̀ ni ó wà ní ibi tí wọ́n ń pè ní Odo-Aofin.

Àwọn ìletò tí ó wà ní Kàbà

àtúnṣe
  1. Aiyeteju,
  2. Odi-olowo,
  3. Kajola,
  4. Odo-ero,
  5. Odolu,
  6. Fehinti,
  7. Surulere,
  8. Ikowaopa
  9. Iyah,
  10. Otu,
  11. Egbeda,
  12. Gbeleko,
  13. Okedayo,
  14. Kakun,
  15. Ohakiti,
  16. Obele,
  17. Ogbagba,
  18. Ayonghon,
  19. Ayedun,
  20. Ayetoro Egunbe ti Obangogo,
  21. Iduge,
  22. Adesua,
  23. Asanta,
  24. Korede,
  25. Okekoko,
  26. Katu,
  27. Apanga àti bbl.

Ìpínsísọ̀rí Kàbà

àtúnṣe

Wọ́n pín kàbà sí ọ̀nà mẹ́ta tí àwọn ìdílé tó wà níbiẹ̀ jẹ́ mẹ́rìnlá, àwọn ni:

  • Kabba – ìdílé mẹ́fà.
  • Katu – ìdílé mẹ́ta
  • Odolu – ìdílé márùn ún.[5]

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "Distance Kabba – Abuja". cutway.net. Cutway. 
  2. "Distance Kabba – Lagos". cutway.net. Cutway. 
  3. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named EB1911
  4. "Ooni of Ife to Grace 2018 Kabba Day, Congratulates New Obaro". Kogi Reports. October 25, 2018. 
  5. Reporter (November 4, 2017). "Kabba day 2017 records landmark success". City People Magazine. Retrieved 2021-01-15. 


Àdàkọ:Kogi-geo-stub