Oṣù Ṣẹ̀rẹ́
(Àtúnjúwe láti Oṣù Ṣẹ́rẹ́)
Oṣù Ṣẹ̀rẹ́ tàbí oṣù Kìíní jẹ́ oṣù àkọ́kọ́ nínú Kàlẹ́ńdà Gregory. Ọjọ́ mọ́kànlélọ́gbọ̀n ni ó wà nínú oṣù yìí. Ọjọ́ kìíní ti oṣù Ṣẹ̀rẹ́ ni a ṣe ayẹyẹ ọdún títun. Ní ìpíndọ́gba, oṣù yìí sì jẹ́ oṣù tí ó máa ń tutú jù lọ ní ìdajì ayé àríwá (nítorí pé ó jẹ́ oṣù kejì ti ìgbà òtútù níbẹ̀); ó sì jẹ́ oṣù tí ooru máa ń mú jù lọ ní ìdajì ayé gúúsù (nítorí pé ó jẹ́ oṣù kejì ti ìgbà sọ́mà níbẹ̀). Ní èdè Gẹ̀ẹ́sì, wọ́n pè é ní "January"; orúkọ yìí wá láti ọ̀rọ̀ èdè Látínì "iānuārius" (oṣù ti Janus). Nítorí èyí, ní èdè Yorùbá náà a sì máa ń pe oṣù yìí ní "oṣù Jánúárì" ní ìgbà mìíràn, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ènìyàn máa ń wí pé kò yẹ́ kí a lò ó nítorí jíjẹ́ ọ̀rọ̀-àyálò tí ó jẹ́.
Oṣù Kínní | ||||||
Àìkú | Ajé | Ìsẹ́gun | Ọjọ́rú | Ọjọ́bọ̀ | Ẹtì | Àbámẹ́ta |
1 | 2 | 3 | 4 | |||
5 | 6 | 7 | 8 | 9 | 10 | 11 |
12 | 13 | 14 | 15 | 16 | 17 | 18 |
19 | 20 | 21 | 22 | 23 | 24 | 25 |
26 | 27 | 28 | 29 | 30 | 31 | |
2025 |
Osù:| Kínní | Kejì | Kẹta | Kẹrin | Kàrún | Kẹfà | Keje | Kẹjọ | Kẹ̀sán | Kẹ̀wá | Kọkànlá | Kejìlá |