Olúṣọlá Ìṣọ̀lá Ògúnṣọlá
Olúṣọlá Ìṣọ̀lá Ògúnṣọlá, tí ọ̀pọ̀ ènìyàn mọ̀ sí Isho Pepper ni wọ́n bí ní ọjọ́ Kẹrìnlá oṣù kọkanlá ọdún 1942 sí ìdílé ọ̀gbẹ́ni Sámúẹ́lì Ògùnṣọlá, ní agbolé Baàlà Dáṣàolú lẹ́yìn Mọ́sálásí Ìta Ìgbẹ̀yìn ládùúgbò Òkè Ìtokú ní ìlú Abẹ́òkúta ní Ìpínlẹ̀ Ògùn.
Ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀
àtúnṣeOlúṣọlá gẹ́gẹ́ bí àbígbẹ̀yìn nínú ọmọ mẹ́rin tí àwọn òbí rẹ̀ bí, abúlé Olókuta, ní ẹ̀bá Aláhọ̀ tó wà ní ìjọba ìbílẹ̀ Olúyọ̀lé nílú Ìbàdàn ló ti lo ìgbà èwe rẹ̀, bákan náà ló lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ti Christ School, ti ìlú Olókúta.
Iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Òṣèré tíátà
àtúnṣeLẹ́yì ìwé mẹ́fà, ó padà sí Abẹ́òkúta níbi tí ó i bẹ̀rẹ̀ ilé-ẹ̀kọ́ Abeokuta Grammar School, ilé-ẹ̀kọ́ yí náà ló wà tí ó ti ń ṣe ṣàfihàn ìfẹ́ rẹ̀ sí eré tíáà. Lásìkò tí a ń wí yìí, ọ̀pọ̀ ènìyàn ló kórìíra iṣẹ́ yí nítorí wípé wọ́n ka àwọn tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ yí sí alágbe lásán. Fúndí èyí, inírúurú ìpèníjà ló dijú kọ Olúṣọlá nídí iṣẹ́ tí ó yàn láàyò, débi wípé àwọn ẹbí òun ọ̀rẹ́ ló kẹ̀yìn si àyà fi ìyá rẹ̀ Abigail ló ṣúgbàá rẹ̀, tí ó sì fẹ̀yìn pọ̀n ọ́n kí ó lè ṣorí ire. Olúṣọlá dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèré tí gbajú-gbajà òṣèré Akin Ògúngbè dá sílẹ̀ ní ìlú Abẹ́òkúta ní ọdún 1959, lẹ́yìn tí ó parí ilé-ẹ̀kọ́ girama rẹ̀. Ó kúrò lọ́dọ̀ ọ̀ gá rẹ̀ lọ́dún 1965, láti lọ dá ẹgbẹ́ òṣèré tíátà tirẹ̀ sílẹ̀, tí ó sì ma ń kọrin, lùlù pẹ̀lú ijó bí ó bá fẹ́ bẹ̀rẹ̀, láàrín àti ìparí eré rẹ̀. Olúṣọlá jẹ́ ọ̀kan lára àwọn òṣèré tíátà tó kọ́kọ́ ṣeré lórí ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán tí ó sì kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọ gbajúmọ̀ òṣèré bíi:
- Hubert Ògúndé Mosis Adéjùmọ̀ ( Bàbá Sàlá), Bàbá Mèró, Kọ́lá Ògúnmọ́lá, Oyin Adéjọbí àti Adéyẹmí Afọláyan. [1]
Lára àwọn tí wọ́n jọ kọ́ iṣẹ́ tíátà lọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ̀ Akin Ògúngbè ni: Jimoh Aliu, Charles Olúmọ (Agbako), Afọlábí Afọláyan (Jagua), Fẹ́mi Adéyẹmọ (Bàbá ń gbá life).
Ìṣọwọ́ gbé eré rẹ̀ kalẹ̀
àtúnṣeOlúṣọlá ma ń ṣe eré pàá pàá jùlọ àwọn eré tí a lè rí kà lákà gbádùn nínú àwọn ìwé eré oníṣe, tabí eré onítàn bí:
- Fẹrẹ bí Ẹkùn
- Aláàfin Aganjù,
- Agbà lọ́wọ́ Méèrí,
- Kóṣéégbé,
- Àjalólẹrù
- Ìyàwó Alálùbọ́sà
- Ẹfúnṣetán Aníwúrà
- Ibú Olókun àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Bákan náà ni ó jẹ́ òṣèré tíátà ẹlẹ́kẹrin tó ya eré sinimá àgbéléwà lẹ́yín tí Hubert Ogunde, jẹ́ ẹni akọ́kọ́ tó kọ́kọ́ ṣe bẹ́ẹ̀, eyi to gbe lọ si orílẹ̀-èdè United Kingdom
Ipa rẹ̀ nínú ẹgbẹ́ òṣèré tíátà
àtúnṣeOlúṣọlá jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára àwọn àgbà ọ̀jẹ̀ òṣèré tíátà tó dá ẹgbẹ́ ANTP sílẹ̀ lọ́dún 1976. Òun ni akọ̀wé owó àkọ́kọ́ fún ẹgbẹ́ náà ní ọdún 1976 sí 1989.
Àwọn òṣèré tí òun náà kọ́ níṣẹ́ ni
àtúnṣeLára àwọn tí Olúṣọlá kọ́ ní iṣẹ́ ni: Samson Elúwọlé (Jinadu Ewele), Adéníyì Òrofó (Ewéjókó) àti Gbọ́lágadé Adédèjì (Àró Oní fìla gogoro).
Àwọn ẹbí rẹ̀
àtúnṣeṢọlá fẹ́ ìyàwó tí ó tó Márùn ún tí wọ́n sì ń ba á ṣeré kiri gbogbo ibi tó bá ń lọ. Bákan náà ló fàwọn ọmọ [2] sáyé lọ̀. Àwọn ìyàwó rẹ̀ ni:
- Mojísọ́lá Ògúnṣọlá (ìyá alákàra).
- Ìyábọ̀dé Ògúnṣọlá (Ẹfúnṣetán Aníwúrà)
- [[Fúnmiláyọ̀ Ògúnṣọlá (Ìjẹwùrù)
- Yétúndé Ògúnṣọlá (Ìyàwó Alálùbọ́sà)
- [[Bọ́látitó Ògúnṣọlá (À8ná Òrosùn)
Okú rẹ̀
àtúnṣeÓ kú ní ọjọ́ Kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù Kejìlá, ọdún 1992, ní ọmọ àádọ́ta ọdún, lẹ́yìn àìsàn ránpẹ́. Kí Ọlọ́run ó dẹlẹ̀ fun. [3]
Àwọn Ìtọ́ka sí
àtúnṣe- ↑ Barber, K.; Collins, J.; Ricard, A. (1997). West African Popular Theatre. Drama and Performance Studies. Indiana University Press. p. 190. ISBN 978-0-253-02807-5. https://books.google.com.ng/books?id=Tx6wDQAAQBAJ&pg=PA190. Retrieved 2020-06-07.
- ↑ "My dad didn’t think a girl should have a male friend - Bola Akande, Isho Pepper’s daughter » Tribune Online". Tribune Online. 2018-12-02. Retrieved 2020-06-07.
- ↑ "What Really Killed I SHO PEPPER 27 Yrs Ago, His 3rd Wife, YETUNDE Opens Up". City People Magazine. 2019-09-22. Retrieved 2020-06-07.