Ogun Kírìjí

Ogun ní ilé Yorùbá

Ogin Kírìjí, tí a tún ń mọ̀ sí ogun Èkìtì-Parapọ̀ ni ogun abẹ́lé tí ó wáyé láàrín ẹ̀yà Yorùbá fún odidi ọdún Mẹ́rìndínlógún gbáko. Ogun yí wáyé lààrín ilẹ̀ Ìbàdàn tí ó wà ní apá àríwá ilẹ̀ Yorùbá ati ilẹ̀ ìjẹ̀ṣà ati gbogbo Èkìtì pátá, tí wọ́n wà ní apá ìlà-Oòrùn ilẹ̀ Yorùbá.

Ogun Kírìjí
Ìgbà July 30, 1877-1893
Ibùdó Ilẹ̀ Yorùbá, tí ó jẹ́ Ìwọ̀-Oòrùn Nàìjíríà
Àbọ̀ Military Stalemate
  • Àwọn ènìyàn Èkìtì gba òmìnira ní September 23, 1886
  • British-Ijebu War
  • Capture of Ilorin by Royal Nigeria Company in 1897
  • Siege of Oyo
  • Subsequent colonization and annexation of Yorubaland
  • creation of British Nigeria
Àwọn agbógun tira wọn
Western Yoruba (Ìbàdàn) Eastern Yoruba (Èkìtì-Parapọ̀)
Àwọn apàṣẹ
Ọbádòkè Látòósà
Babalola Ajayi
Fábùnmi Òké-Ìmẹ̀sí
Saraibi Ogedengbe
Karara of Ilorin
Agbára
estimated 100,000 10,000 in 1879, 100,000 at end of the war
Òfò àti ìfarapa
unknown unknown

Ohun tí ó fa ogun náà

àtúnṣe

Ohun tí ó fa ogun yí ní pàtó ni ìlòdì sí bí ilẹ̀ Ìbàdàn ṣe ń jẹ gàba lé àwọn ìlú Yorùbá tó kù lórí, tí Ìbàdàn sì fẹ́ fi ara rẹ̀ dipò aláṣẹ wàá bí ìlú Ọ̀yọ́, bí Ìbadàn ṣe ń tẹ àwọn ọmọ ìyá rẹ̀ yókù lójú mólẹ̀, tí wọ́n sì sọ àwọn ìlú wọ̀nyí di ìlú amọ́nà. [1] Lára ohun tí ó tú ṣokùnfà ogun yí ni wípé ilẹ̀ Ìbàdàn ń fẹ́ kí gbogbo ilé Yorùbá wà ní ìṣọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà lásìkò tí ilẹ̀ Ọ̀yọ́ ń ṣe àkóso àti ìjọba lé ilẹ̀ Yorùbá lòrí. Ẹ̀wẹ̀, ilẹ̀ Èkìtì ń fẹ́ kí kálukú ó ma ṣe ìjọba ara rẹ̀, àmó kí ìṣòkan, ìrẹ́pọ̀ àti ìbòwọ̀ fúnra ẹni ò wà nínú ìṣèjọba ìlú kọ̀ọ̀kan. Èyí ni ó fa èdè àìyedè tí ogun Kírìjí fi bẹ́.sílẹ̀ ní ọdún 1877.

Ṣíṣubú tí Ìlú Ọ̀yọ́ ṣubú gẹ́gẹ́ bí ìlú tí ó ń ṣàkóso ilẹ̀ Yorùbá fún bí odidi ọ̀rùndínlẹ́gbẹ̀ta ọdún ti mú kí gbogbo àwọn ìlú amọ̀nà lábẹ́.ìṣèjọba Ọ̀yọ́ ó di olómìnira tí wọ̀n sì ti ń bá ìṣèjọba ara wọn lọ fún bí òpọ̀lọpò ọdún. Púpọ̀.nínú àwọn ìlú yí náà sì ti wàyàmì débi tí wọ́n le rọ́pò ìlú Ọ̀yọ́ níbi ìjẹ gàbà lé àwọn ìlú mìíràn lórí. Lára àwọn ìlú wọ̀nyí ni ilẹ̀ Ìbàdàn wà. Ìbàdàn ti jàgun ṣẹ́gun ogun Òṣogbo ní ọdún 1840, wọ́n sì ti jagun ṣẹ́gun ogun Ìjàyè ní ọdún 1862 bákan náà, tí wọ́n sì ti di alágbára gidi bí ti ilẹ̀ Ọ̀yọ́.

Nínú ogun yí, ilẹ̀ Ààrẹ Ọ̀nà Kakanfò ni ó jẹ́ aṣíwájú ogun wọn, tí Obadake Látòósà jẹ́ Balógun. Wọ́n gbìyànjú wọ́n sì rí àtìlẹyìn àwọn ìlú mìíràn bíi: Modákẹ́kẹ́, Ọ̀fà, àti Ìlú Ọ̀yọ́ Aláàfin. Àwọn Èkìtì-Parapọ̀ ní tiwọn ni Fábùnmi Òké-Ìmẹ̀sí jẹ́ aṣájú ogun fún, kí ó tó di wípé Saraibi Ògèdèngbé, tí ó jẹ́ Balógun fún ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà tó bọ́ rọ́pò Fábùnmi. Lára àwọn ilẹ̀ Yorùbá tí wọ́n ṣúgbàá àwọn Èkìtì ni: Ilẹ̀ Ìjẹ̀bú, Ilé-Ifẹ̀, ilẹ̀ Ẹ̀gbá, Akókó, Ìgbómìnà, Ìlọrin,àti Kàbà.[2]

Ọgbọ́n Ẹ̀wẹ́ àti Nǹkan Ìjà Ogun

àtúnṣe

Ogun yí ni ó kọ́kọ́ irúfẹ́ ogun abẹ́lé tí wọn yóò kọ́kọ́ jà ní ilẹ̀ Adúláwọ̀ tí wọn yóò lo àwọn nkan ìjà olóró tí wọ́n kó wọlẹ̀ Yorùbá láti Hamburg ní orílẹ̀-èdè Jẹ́mánì [3] Oríṣiríṣi nkan ìja ogun olóró ni wọ́n tún kó wọlẹ̀ Yorùbá láti orí omi Èkó ati Benin. Àwọn ọmọ ogun Èkìtì-Parapọ̀ tún lo ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ nípa gbígbẹ́ kòtò gìrìwò gba abẹ́ ilẹ̀ láti lè fi ṣe àkọlù sí àwọn ọmọ ogun Ìbàdàn. Wọ́n tún ṣamúlò alamí nípa fífi àwọn ènìyàn kan ṣe olófòófó ohun tí ó bá ń lọ tàbí ṣẹlẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn ọ̀tá kí wọ́n lè mọ ọ̀nà tí wọn yóò lò láti rẹ́bùrú wọn, ìlú Ìlárá-Mọ̀kín ni wọ́n fi ṣe ojúkò wọn. Bákan náà ni wọ́n tún lo oríṣiríṣi ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ láti ma fi bá ara wọn sọ̀rọ̀, pàápàá jùlọ nípa lílo ìwọ́hùn àwọn ẹranko oríṣiríṣi láti máa fi bá ara wọn jíròrò kí àwọn ọ̀tá ó má ba gbọ́ tabí mọ̀ ohun tí wọ́n tàkurọ̀sọ lé lórí, tí ó sì dúró gẹ́gẹ́ bí ọgbọ́n éwẹ́ ojú ogun.[4]

Bí àwọn Gẹ̀ẹ́sì ṣe mú òpin bá aáwọ̀ ogun

àtúnṣe

Ogun abẹ́lé yí parí ní ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù kẹsàán ọdún 1886. Dídópin ìjà òun ogun yí ni ó fún ilẹ̀ Èkìtì-Parapọ̀ ní òmìnira tí wọ́n ti ń pòngbẹ rẹ̀. Síbẹ̀, ogun kò tán bẹ̀ẹ́ ni kò wá sópin ní ilé Ìjẹ̀bú fún ìgbà pípẹ́, ogun kan tún bè sílẹ̀ láàrín ilẹ̀ Ìjẹ̀bú àti àwọn Gẹ̀ẹ́sì, kí ó tó di wípé àwọn Gẹ̀ẹ́sì wá borí tí wọ́n sì mú wọn lẹ́rú lábẹ́ àkóso ọ̀gbẹ́ni Robert Lister Bower. [5]Àwọn Gẹ̀èsì sọ apá Gúsù ilẹ̀ Yorùbá di ìlú amọ́nà fún ìjọba ilẹ̀ Bírítéènì. A kò rí pàtó iye àwọn tí wọ́n kú nínú ogun Kírìjí ní àsìkò tí a ń kọ nípa ogun yí lọ́wọ́, amọ́ wọ́n nípé wọn kò pa ọmọdé àti àwọn obìnrin ní àsìkò tí wọn ń ja ogun yí lọ́wọ́. A sì tún gbọ́ wípé iye àwọn ọmọ ogun tí wọ́n ja ogun yí lápapọ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọ̀rùndínlẹ́gbẹ̀ta.[6]

Ohun tí ìtàn sọ nípa Kírìjí

àtúnṣe

Wọ́n fún ogun yí ní orúkọ rẹ̀ Kírìjí látàrí ìró tí kẹ̀kẹ́ àdó olóró tí àwọn ọmọ ogun Èkìtì-Parapọ̀ lò láti fi kojú ọ̀tá wọn lójú ogun, tí ó sì jẹ́ wípé òun ni irú akọ́kọ́ rẹ̀ tí wọn yóò lò láti fi jagun ní ilẹ̀ Adúláwọ̀ ní àsìkò náà. [7][8]

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe