Omo Baba Olowo
Omo Baba Olowo ni àwo-orin àkọ́kọ́ ti olórin ilẹ̀ Nàìjíríà, ìyẹn Davido máa gbé jáde.[1] HKN Music ló ṣe agbátẹrù orin yìí ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù Keje, ọdún 2012, tí ó sì jẹ́ àhunpọ̀ orin Afrobeats àti hip hop. Àwọn tó gbé àwo-orin yìí jáde ni Jay Sleek, Maleek Berry, GospelOnDeBeatz, Spellz, Dokta Frabz, Mr. Chidoo, Theory Soundz àti Shizzi. Lára àwọn olórin tí ó farahàn nínú àwo-orin Omo Baba Olowo ni Naeto C, Sina Rambo, B-Red, Kayswitch, Ice Prince, May D àti 2 Face Idibia. Lára àwọn orin inú àwo-orin náà ni "Back When", "Dami Duro", "Ekuro", "Overseas", "All of You", "Gbon Gbon", àti "Feel Alright".
Omo Baba Olowo gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbẹnuàtẹ́lù láti ọwọ́ àwọn ènìyàn tí wọ́n ní àríwísí sí ìgbórinkalẹ̀ orin náà, tí wọ́n sì bu ẹnu àtẹ́ lu ìṣọwọ́kọrin Davido. Àwo-orin náà gba àmì-ẹ̀yẹ fún ìsọ̀rí Àwo-orin tó dára jù lọ ní, ìyẹn Best R&B/Pop Album ní The Headies 2013. Bákan náà ni wọ́n yàn án fún àwo-orin tó dára jù lọ ní Nigeria Entertainment Awards, ní ọdún 2013.
Ayẹyẹ ìfilọ́lẹ̀
àtúnṣeNí ọjọ́ kejìlélógún oṣù Keje ọdún 2012, wọ́n ṣe ayẹyẹ ìfilọ́lẹ̀ àwo-orin náà ní Expo Hall ti Eko Hotels and Suites ní Victoria Island, Lagos.[2] Bàbá Davido, ìyẹn Adedeji Adeleke àti Aliko Dangote fi ìjókòó wọn yẹ àyẹyẹ náà sí.[3] Àwọn gbajúgbaja olórin àti òṣèré bí i D'banj, Naeto C, Toke Makinwa, Daddy Freeze, àti Funke Akindele, náà farahàn níbi ayẹyẹ náà.[4]
Àhunpọ̀ orin
àtúnṣeOrin àkọ́kọ́ inú àwo-orin náà ni "All of You", èyí tó jẹ́ orin tí gbẹ̀du rẹ̀ ń lọ lẹ́sẹẹsẹ. Nínú orin "Dollars in the Bank", Davido sọ̀rọ̀ nípa àwọn olójúkòkòrò ènìyàn tó fẹ́ràn òun nítorí owó tí òun ní. Nínú "Video", ó fi ète sọ fún ọ̀kan lára àwọn afẹ́nifẹ́rere rẹ̀ kí ó ṣe fọ́nrán kan pẹ̀lú òun. "Mary Jane" ní ìtumọ̀ méjì. Ní èrèfẹ́, orin náà dá lórí "ọmọbìnrin burúkú kan" tó máa ń jẹ́ kí orí Davido laná, àmọ́ ní kúnlẹ̀kúnlẹ̀, ó jẹ́ àdàpè fún igbó. Nínú orin àlùjó "Gbon Gbon", olùṣàgbéjáde orin náà, ìyẹn Shizzi ṣe ẹ̀da "Dami Duro". "No Visa" jẹ́ àhunpọ̀ Europop àti Azonto. "All of You", "Feel Alright", "New Skul Tinz" , àti "Enter the Center", wà nínú àwo-orin náà.
Orin àdákọ
àtúnṣe"Back When", tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn orin àdákọ inú àwo-orin náà jáde ní ọjọ́ keje oṣù Karùn-ún, ọdún 2011.[5] Nínú orin yìí, ó ṣàfihàn Naeto C tó kọ ẹsẹ kan nínú orin náà, èyí tí wọ́n gbà sílẹ̀ ní Old Kent Road ní ìlú London.[6] Clarence Peters ya fọ́nrán orin fún "Back When" ní Nàìjíríà tí wọ́n sì gbé síta ní ọjọ́ kẹsàn-án oṣù Karùn-ún ọdún 2011 sí orí YouTube.[7] Orin àdákọ kejì inú àwo-orin náà ni "Dami Duro", tí wọ́n gbé síta ní ọjọ́ ọgbọ́n oṣù Kẹwàá ọdún 2011.[8] Peters ló ya fọ́nrán orin náà ní Èkó.[9]
Orin àdákọ ẹlẹ́ẹ̀kẹta inú àwo-orin náà ni "Ekuro", tí wọ́n gbé jáde ní ọjọ́ karùndínlọ́gbọ̀n oṣù Kìíní ọdún 2012. Olórin ilẹ̀ Nàìjíríà, ìyẹn Aramide ṣe àdákọ orin náà.[10] Antwan Smith ló ya fọ́nrán orin "Ekuro" ní Miami.[11] Wọ́n gbé "Overseas" jáde ní ọjọ́ kẹfà oṣù Karùn-ún ọdún 2012. Ó ṣàfihàn Sina Rambo, tí Shizzi sì gbé orin náà jáde.[12]
Ìtẹ́wọ́gbà
àtúnṣeOmo Baba Olowo gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àríwísí. Ayomide Tayo ti Nigerian Entertainment Today fún àwo-orin náà ní àmì mẹ́ta àti àbọ̀ nínú àmì márùn-ún, tí ó sì fi ìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé "ìṣọwọ́kọrin Davido ní láti dára si, bẹ́ẹ̀ sì ni ohùn rẹ̀ nílò àtúnṣe".[13] Tayo tún bu ẹnu àtẹ́ lu aṣagbátẹrù orin náà tí ò bo kùdìẹ̀kudiẹ Davido.[13]
Àwọn olórin mìíràn tó farahàn nínú àwo-orin náà
àtúnṣeCredits adapted from the album's back cover.
- David "Davido" Adeleke – primary artist, writer, executive producer, mastering
- Adewale Adeleke – executive producer
- Dr. Adedeji Adeleke – executive producer
- Asa Askia – co-executive producer
- Sharon Adeleke – co-executive producer
- Kamal Ajiboye – co-executive producer
- Shizzi – producer, mastering
- Jerry "Jay Sleek" Shelika – producer
- Maleek Berry – producer
- Gospel "OnDeBeatz" Obi – producer
- Mr. Chidoo – producer
- Spellz – producer
- Dokta Frabz – producer
- Theory Soundz – producer, mixing, mastering
- Naetochukwu Chikwe – featured artist, writer
- Kehinde Oladotun Oyebanjo – featured artist
- Shina "Rambo" Adeleke – featured artist, writer
- Bayo "B-Red" Adeleke – featured artist, producer, writer
- Panshak Zamani – featured artist, writer
- Akinmayokun "May D" Awodumila – featured artist, writer
- Innocent Ujah Idibia – featured artist, writer
- TCD Photography – cover art photography
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Batte, R Edgar (23 December 2013). "Davido takes on Jose Chameleone". Daily Monitor. Archived from the original on 8 February 2014. Retrieved 19 March 2014. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "Davido breaks out". Vanguard. 14 July 2012. Archived from the original on 11 August 2014. Retrieved 19 March 2014. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "Billionaire's club at Davido's album launch: Dangote and Adeleke share a table!". OMG. 24 July 2012. Archived from the original on 14 August 2014. Retrieved 19 March 2014. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ Aiki, Damilare (23 July 2012). "BN Red Carpet Fab: Davido's "Omo Baba Olowo – O.B.O – The Genesis" Album Launch". Bellanaija. Archived from the original on 2 May 2014. Retrieved 19 March 2014. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "Davido Feat Naeto C 'Back When' – by Nwadiogo Quartey-Ngwube". Fab Magazine. 10 May 2011. Archived from the original on 3 November 2013. Retrieved 19 March 2014. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ Orakwue, Nonny (25 September 2012). "The Wrap Up Home INTERVIEW: DAVIDO". MTV. Archived from the original on 29 October 2012. Retrieved 19 March 2014. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ L, Jibola (10 May 2011). "New Video: Davido Feat. Naeto C". Bellanaija. Archived from the original on 7 April 2014. Retrieved 19 March 2014. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ Adeyemo, Adeola (4 February 2012). "BN Saturday Celebrity Interview: "You Can't Stop Me!" 2012′s Hottest Star, Davido – The Music, The Fame, The Fans & More!". Bellanaija. Archived from the original on 23 September 2015. Retrieved 19 March 2014. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ Okiche, Wilfred (10 January 2012). "#InCaseyouMissedIt Hot Stuff: Davido drops video for 'Dami Duro'". YNaija. Archived from the original on 26 September 2017. Retrieved 19 March 2014. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "Aramide Drops R&B Cover Of Davido's 'Ekuro'". Channels TV. 20 May 2013. Archived from the original on 9 July 2013. Retrieved 19 March 2014. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "NEW VIDEO: DAVIDO - Ekuro". Nigerian Eye. 25 May 2012. Archived from the original on 15 December 2019. Retrieved 19 March 2014. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ Alonge, Osagie (5 July 2012). "VIDEO: Davido releases fourth video 'Overseas' feat Sinarambo". Nigerian Entertainment Today. Archived from the original on 20 March 2014. Retrieved 19 March 2014. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ 13.0 13.1 Tayo, Ayomide (18 July 2012). "Davido – 'Omo Baba Olowo' [Album review]: Money can solve everything except perfection". Nigerian Entertainment Today. Archived from the original on 11 August 2017. Retrieved 18 March 2014. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help)