Don Jazzy

(Àtúnjúwe láti Don jazzy)

Michael Collins Ajereh (tí a bí ní ọjọ́ 26, oṣù kọkànlá, ọdún 1982), tí a mọ̀ mọ́ iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i Don Jazzy,jẹ́ aṣàgbéjáde rẹ́kọ́ọ̀dù ní Nàìjíríà , aṣojú fún àwọn ilé-iṣẹ́ , onímọ̀ ẹ̀rọ ohùn , ọ̀gá ilé-iṣẹ́ orin, olórin , olókòwò, olùsọdimímọ̀ àti adẹ́rínpòṣónú. Òun ni olùdásílẹ̀ àti ọ̀gá ilé iṣẹ́ Mavin Records.[1] Don Jazzy jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn tí wọ́n ni ilé-iṣẹ́ orin tí ó ti kógbá wọlé Mo' Hits Records pẹ̀lú Dbanj. Àbúrò rẹ̀ lọ́kùnrin ni D'Prince.

Don Jazzy
Background information
Orúkọ àbísọMichael Collins Ajereh
Ọjọ́ìbí26 Oṣù Kọkànlá 1982 (1982-11-26) (ọmọ ọdún 42)
Umuahia, Abia State, Nigeria
Irú orin
Occupation(s)
  • Record producer
  • singer
  • executive
  • entrepreneur
Years active2002–present
Labels
Associated actsD'banj

Dr SID

D'Prince

Wande Coal

Tiwa Savage

Reekado Banks

Korede bello

Di'Ja

Rema

Johnny Drille

Ladipoe

Ayra Starr

Burna Boy
Websitemavinrecords.com
Don Jazzy
Olólùfẹ́
Michelle Jackson
(m. 2003; div. 2005)

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀

àtúnṣe

A bí Don Jazzy gẹ́gẹ́ bí Micheal Collins Ajereh ní Umuahia, Abia State, ní ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n, oṣù kọkànlá, ọdún 1982,[2] ọmọ ọkùnrin tí Collins Enebeli Ajereh àti Mrs Ajereh bí . Bàbá rẹ̀ wá láti Isoko ní Delta State. Ìyá rẹ̀ jẹ́ Ọmọọba Igbo láti Ìpínlẹ̀ Abia nígbà tí bàbá rẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ará Isoko .[3] D'Prince ni àbílẹ́yìn Don Jazzy lọ́kùnrin. Ìdílé Don Jazzy kó lọ sí Ajegunle, Èkó Ní ibi tí wọ́n ti tọ́ Don Jazzy.[4]

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀ àti ẹ̀kọ́

àtúnṣe

Ìdílé Ajereh kó lọ sí Ajegunle, Èkó, níbi tí wọ́n ti tọ́ Don Jazzy .[5] Ó kàwé ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga takọtabo, Federal Government College Lagos. Ìfẹ́ tí Don Jazzy ní sí orin bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà kékeré, nígbà tí ó sì pé ọdún méjìlá, ó bẹ̀rẹ̀ sí ni ta gìtá, ó sì ń tẹ dùùrù. Ó tún kọ́ nípa àwọn ohun èlò orin tiwantiwa àti àwọn èyí tí ó ní okùn. Don Jazzy lọ kọ́ ẹ̀kọ́ nípa ìmọ̀ ìmójútó okòwò ní Yunifásítì Ambrose Alli , Ekpoma, Ìpínlẹ̀ Ẹdó.

Ní ọdún 2000, ìbátan Jazzy pè é kí ó wá lu ìlù fún ìjọ agbègbè ní London, èyí sì jẹ́ ìrìn àjò kìíní rẹ̀ lọ sí London.[6] Don Jazzy rí iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí i abániṣọ́lé ní McDonald's. Ó tẹ̀ síwájú nínú ìfẹ́ rẹ̀ sí orin , ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Solek, JJC Skillz, Kas, Jesse Jagz, The 419 Squad ati D'banj.

Ìgbé-ayé lọ́kọláya

àtúnṣe

Don Jazzy fẹ́ Michelle Jackson ní ọdún 2003. Ó jẹ́ kí ó di mímọ̀ pé àwọn ní àwọn ìṣòro nípasẹ̀ bí òun ṣe jẹ́ alákínkanjú ènìyàn tí ó ń lé iṣẹ́, wọ́n sì pínyà lẹ́yìn ọdún méjì tí wọ́n ṣe ìgbéyàwó. Ṣùgbọ́n ṣá, kò sí nínú ètò rẹ̀ láti fẹ́ ìyàwó mìíràn ní kíákíá nítorí ìbẹ̀rù rẹ̀ pé ìfẹ́ àti ìfinjì rẹ̀ fún orin lè tún dá ègbodò fún ìfẹ́ ẹlòmíràn sí í. [7][8]

Iṣẹ́

àtúnṣe
 
Don Jazzy níbi tí ó ti ń ṣeré ní 2014

Mo' Hits records àti GOOD music

àtúnṣe

Ní 2004, Don Jazzy fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú D'banj láti dá Mo' Hits Records sílẹ̀ . Ní ọdún méjì tí ó tẹ̀le , Don Jazzy gbé àwo No Long Thing àti Rundown/Funk You Up jáde . "Thunder fire" you náà sì ti bẹ̀rẹ̀ ní àkókò náà . Ní àkókò yìí , Don Jazzy bẹ̀rẹ̀ ìfarahàn tí ó jẹ́ tirẹ̀ nìkan, "It's Don Jazzy Again!"

Ní ọdún 2008, Don Jazzy náà ní àfikún nínú àgbéjáde The Entertainer láti ọwọ́ D'Banj. Ó tún ní àfikún nínú àgbéjáde àwo Wande Coal Mushin 2 MoHits, àwo tí wọ́n ṣe àpèjúwe gẹ́gẹ́ bí i ọkàn lára àwọn àwo ti ó dáńtọ́ jù tí ó ti jáde láti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà .[9]

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àfikún Don Jazzy kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí i olórin, ó máa ń ṣe elégbè fún àwọn olórin tí ó gbé jáde . Àwọn iṣẹ́ tí ó ti ṣe ni ègbè fún àwọn olórin bí i D'banj Sauce Kid, Dr SID, Ikechukwu, Kween, D'Prince, Jay-Z. Don Jazzy ṣe ègbè fún orin Kanye West, "lift up" pẹ̀lú Beyoncé nínú àwo "Watch the Throne".

Ní ọdún 2011, Kanye West gba Don Jazzy síṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí i aṣàgbéjáde ohùn ní. Don Jazzy ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Jay-Z àti Kanye West lórí àgbéjáde "lift up" tí wọ́n pe Beyoncé sí nínú àwo "Watch the Throne" tí wọ́n fi síta ní ọjọ́ kẹjọ, oṣù kẹjọ, ọdún 2011.

Ní oṣù kẹta, ọdún 2012, Don Jazzy àti D'Banj fìdí ìpínyà wọn múlẹ̀ pẹ̀lú ìdí ìyàtọ̀ nínú iṣẹ́-ọnà .[10]

Mavin Records

àtúnṣe

Ní ọjọ́ keje, oṣù karùn-ún, ọdún 2012, Don Jazzy kéde ilé-iṣẹ́ rẹ́kọ́ọ̀dù tuntun, Mavin Records. Ó ní , "Mo rí Mavin Records pé yóò jẹ́ ilé agbára orin ní Áfíríkà ní ìwọ̀nba àsìkò tí ó kéré jù tí ó ṣeéṣe ."[11] Ní ọjọ́ kẹjọ, oṣù karùn-ún, ọdún 2012, ó gbé àwo tí ó ní àwọn olórin tí wọ́n tọwọ́bọ̀wé pẹ̀lú ilé-iṣẹ́ orin rẹ̀ jáde. Àwọn orin tí wọ́n wà lórí àwo náà ni: IAmarachi, Forever, Oma Ga, Take Banana and Chocolate, YOLO àti orin I'm a MAVIN. Mavin gba àwọn olórin bí i, Tiwa Savage. Don jazzy gbé ìtagbà ibánidọ́ọ̀rẹ̀ tí ó pè ní "Marvin League" dìde láti gbé ilé-iṣẹ́ rẹ̀ jáde àti láti polówó ilé-iṣẹ́ orin rẹ̀.[12]

Ní ọjọ́ karùn-ún, oṣù kọkànlá, ọdún 2013, Ajereh ní èdè àìyedè pẹ̀lú olórin rẹ̀ kan, Wande Coal tí ó fi ilé-iṣẹ́ náà sílẹ̀ lẹ́yìn ọjọ́ méjì.[13]

Ní oṣù kẹsàn-án, ọdún 2014, Ajereh gbé orin ajàfẹ́tọ̀ọ́ àwùjọ Nàìjíríà kan jáde pẹ̀lú Reekado Banks àti Di'Ja tí wọ́n pè ní Arise.[14]

Níbi tí wọ́n ti ń gba àmì ẹ̀yẹ Headies Awards 2015, Ajereh jiyàn pẹ̀lú Olamide. Àwọn méjèèjì jiyàn lórí ẹni tí ó yẹ kí ó gba àmì ẹ̀yẹ "Next Rated". Ó bọ́ lọ́wọ́ Lil Kesh ti YBNL records lọ sí ọwọ́ Reekado Banks, tí ó jẹ́ olórin ní abẹ́ Ajereh'. Ẹni tí ó gba àmì ẹ̀yẹ náà gba ọkọ̀ bọ̀gìnnì. Àwọn apá méjèèjì ni wọ́n fi ẹ̀bẹ̀ má bínú léde lẹ́yìn náà.[15][16]

Lẹ́yìn ìpínyà Reekado Banks kúrò ní ilé-iṣẹ́ Mavin Records label, Don Jazzy sọ pé ó ṣì jẹ́ ọ̀kan lára ẹbí náà, ó sì gba èróńgbà àṣeyọrí fún un bí ó ṣe ń dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún àsìkò tí ó lò pẹ̀lú Mavin Records.[17]

Ní ọdún 2019, ó gba Rema, ó sì tẹ̀ síwájú láti gba Ayra Starr ní ọdún 2020 sí ilé-iṣẹ́ orin Mavins Record Label. Ní ọdún 2021, ó kéde olórin tuntun, Magixx.[18]

Àfihàn nínú fíìmù

àtúnṣe

Ní ọdún 2012, Don Jazzy hàn nínú fíìmù Moses Inwang, The Last 3 Digits in Nollywood. Inwang tún lo àwọn òṣèré bí i Ali Baba, A.Y., Nonso Diobi àti Dr SID.[19][20][21][22]


Àwọn àmì-ẹ̀yẹ

àtúnṣe

Ní ọjọ́ keje, oṣù kẹrin, ọdún 2021, ó ṣàlàyé ìdí tí kò fi gba Davido sí ilé-iṣẹ́ orin rẹ̀.

Production discography

àtúnṣe

Àwọn Àwo

àtúnṣe
  • D'banj – No Long Thing (2005)
  • D'banj – Rundown Fuck U Up (2006)
  • D'banj – The Entertainer (2008)
  • Mo' Hits All Stars – Curriculum Vitae (2007)
  1. Anaconda 3:34
  2. Booty Call 5:13
  3. Close To You 3:43
  4. Hey Girl 5:08
  5. Igbe Mi 5:40
  6. Masquerade 4:02
  7. No Long Thing 3:15
  8. Ololufe (Club Mix) 4:21
  9. Stop The Violence 6:37
  10. Why Me (Remix) 5:16
  11. Jasi 2:50
  • Wande Coal – Mushin2Mohits (2008)
  1. I Know U Like It 3:10
  2. You Bad 4:05
  3. Se Na Like This 4:12
  4. Kiss Ur Hands 3:54
  5. Confused 4:20
  6. Se Ope 3:22
  7. Now It's All Gone 4:24
  8. Bumper 2 Bumper 3:44
  9. Who Born The Maga 3:04
  10. That's Wots Up 4:42
  11. Bananas 3:59
  12. Taboo 4:24
  13. Jehovah 4:02
  14. Ololufe 4:56
  15. Ten Ten 3:47
  16. My Grind 4:48
  17. Been long you saw me
  18. Private trips
  19. Go low 3:50
  20. The kick 3:10
  21. Rotate 3:20
  • Dr SID Turning Point (2010)
  1. When This Song Comes On
  2. Over the Moon (pẹ̀lú . K-Switch)
  3. Something About You
  4. Winchi Winchi (pẹ̀lú . Wande Coal)
  5. Pop something (pẹ̀lú D'banj)
  6. a Mi Jo (pẹ̀lú . Ikechukwu, M.I & eLDee)
  7. Baby
  8. E Je Ka Jo (pẹ̀lú D'banj)
  9. Pillow
  10. Something About You (Silva Stone Remix)
  11. Winchi Winchi (pẹ̀lú . Wande Coal, Sway DaSafo & Dotstar)
  1. Intro láti ọwọ́ MAVINS (Michael Ajereh, Sidney Esiri)
  2. I'm A MAVIN láti ọwọ́ MAVINS (Michael Ajereh, Tiwatope Savage, Sidney Esiri, Wande Ojosipe, Charles Enebeli)
  3. Oma Ga láti ọwọ́ Tiwa Savage (Michael Ajereh, Tiwatope Savage, Sidney Esiri, Wande Ojosipe)
  4. YOLO láti ọwọ́ Dr SID (Michael Ajereh, Sidney Esiri)
  5. See Me Ri láti ọwọ́ Wande Coal (Michael Ajereh, Sidney Esiri, Wande Ojisipe, Towa Ojosipe)
  6. Take Banana láti ọwọ́ D'PRINCE (Michael Ajereh, Charles Enebeli)
  7. CPR láti ọwọ́ Dr SID (Michael Ajereh, Sidney Esiri)
  8. Forever láti ọwọ́ Wande Coal (Michael Ajereh, Sidney Esiri, Wande Ojosipe, Towa Ojosipe)
  9. Why You Over There láti ọwọ́ D'PRINCE (Michael Ajereh, Charles Enebeli)
  10. Chocolate láti ọwọ́ Dr SID (Michael Ajereh, Sidney Esiri, Charles Enebeli)
  11. Pretty Girls láti ọwọ́ Wande Coal (Michael Ajereh, Wande Ojosipe)
  12. Amarachi láti ọwọ́ D'PRINCE (Michael Ajereh, Charles Enebeli)
  13. Outro láti ọwọ́ MAVINS (Michael Ajereh, Sidney Esiri)

Singles with Mo' Hits artists

àtúnṣe
  • D'Prince
  1. Omoba
  2. I like What I See (pẹ̀lú . Wande Coal)
  3. Ooze (pẹ̀lú .D'banj)
  4. Give It To me (pẹ̀lú . D'banj)
  • D'banj
  1. Tongolo (2005)
  2. Soko (2005)
  3. Mobolowowon (2005)
  4. Why Me (2006)
  5. Run Down (2006)
  6. Kimon (2008)
  7. Olorun Maje (2008)
  8. Gbono Feli (2008)
  9. Entertainer (2008)
  10. Suddenly (2008)
  11. Fall in Love (2008)
  12. Igwe (2008)
  13. Mr Endowed (2010)
  14. I do This
  15. Scape Goat (2010)
  16. ashanti (2010)
  17. Mr Endowed (Remix) (pẹ̀lú . Snoop Dogg) (2010)
  18. Oliver Twist (2011)
  • Wande Coal
  1. Bumper 2 Bumper
  2. You Bad
  3. Kiss Your Hand
  4. Who Born the Maga
  5. Been Long You Saw Me (pẹ̀lú . Don Jazzy) (2011)
  6. Go Low (2011)
  • Dr SID
  1. Something About You (2009)
  2. Winchi winchi (2009)
  3. Pop Something(pẹ̀lú. D'banj)
  4. Over The Moon (2010)
  5. Chocolate
  6. Y.O.L.O
  7. C.P.R
  8. Afefe
  9. Chocolate West African Remix (pẹ̀lú. Ice Prince Sarkodie Elom Adablah Lynxxx)
  10. Chocolate East African Remix (pẹ̀lú. Musik Maestro)
  11. Lady Don Dada
  12. Love Mine
  13. Talented
  14. Baby Tornado
  15. Baby Tornado Remix (pẹ̀lú. Alexandra burke)
  16. Surulere (pẹ̀lú. Don Jazzy)
  • Mo'Hits Allstars
  1. Ten Ten

Singles with other artists

àtúnṣe
  • Darey – Escalade part 2
  • Darey – Stroke Me
  • Shank – Never Felt
  • Naeto C – Asewo
  • Ikechukwu – Like You (pẹ̀lú. Wande Coal)
  • Ikechukwu – Wind am well (pẹ̀lú. Don Jazzy and D'banj)
  • Ikechukwu – Do (pẹ̀lú. D'banj)
  • Ikechukwu – All on Me
  • Ikechukwu – Critical (pẹ̀lú. D'banj)
  • Ikechukwu – Now is the time (pẹ̀lú. Don Jazzy)
  • Sauce Kid – Under G
  • Kanye West & Jay-Z – Lift Off (pẹ̀lú. Beyoncé)
  • Weird MC – Ijoya
  • Burna Boy – Question (2021) [27]

Awon Itokasi

àtúnṣe
  1. "The Don Jazzy Story". Vanguard. 15 October 2011. Retrieved 9 August 2015. 
    - "Don Jazzy blasts Ladies who mocked Banky W's car". Information Nigeria. 23 July 2018. Retrieved 16 July 2018. 
  2. "Don Jazzy, father share birth date as music producer clocks 39". Punch Newspapers (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2021-11-26. Retrieved 2022-03-15. 
  3. Amaechi, Stella (30 November 2020). "Don Jazzy's biography: How did he become famous?". Legit.ng – Nigeria news. 
  4. Tersoo, Andrella (1 May 2018). "Where is Don Jazzy from: Interesting facts about his hometown and state of origin". Legit.ng – Nigeria news. 
  5. "Don Jazzy Biography". nigerianfinder.com. Retrieved 2022-03-30. 
  6. Amoo T. Point Blank Don Jazzy Archived 31 July 2012 at the Wayback Machine. Hip Hop World Magazine 1 February 2010.
  7. "Don Jazzy Reveals Why he isn't Married". GYOnlineNG | All-Round News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 3 April 2021. Archived from the original on 3 April 2021. Retrieved 3 April 2021. 
  8. "Fans of Don Jazzy thinks D'Banj and Wande Coal Deserves Respect for Keeping His Troubled Marriage Away from Public for 18 Years". Naijabeat. Archived from the original on 2 March 2023. Retrieved 2 March 2023. 
  9. Wande Coal, Wizkid. Ynaija website.
  10. Breaking news, it's over, Don Jazzy confirms Mohits Break Up TheNETng 7 November 2013. Accessed 22 April 2015
  11. Naija B.From Mo'Hits to Mavin Records! The New Music PowerHouse Label Bellanaija company 7 June 2012. Accessed 22 April 2015.
  12. don Jazzy changes random boys life Archived 2015-05-22 at the Wayback Machine. View Nigeria newspaper.27 March 2015. Accessed 22 April 2015.
  13. Marvin Records released official statement over Wandel Coal Gist Yinka 7 November 2013. Accessed 22 April 2015.
  14. The Mavins – Arise Archived 2016-03-26 at the Wayback Machine. View Nigeria newspaper. 21 September 2014 Accessed 21 September 2014.
  15. Olamide apologises over fight with Don Jazzy, swearing on live TV DailyPost Nigeria 2 January 2016. Accessed 25 January 2016.
  16. Don Jazzy, Olamide settle rift, apologise over Headies 'wahala' Vanguard News January 2016. Accessed 25 January 2016.
  17. "Reekado Banks still part of Mavin Records – Don Jazzy". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 10 December 2018. Retrieved 26 February 2021. 
  18. "Mavin Records announces new artiste Magixx - P.M. News". Retrieved 2021-11-23. 
  19. The Last 3 Digits YouTube promotion. Accessed 27 October 2014
  20. The last 3 digits 9 Aija books and movies blog. 12 November 2012. Accessed 12 November 2012
  21. Audu J. New trailer alert: Moses Inwang's The last 3 Digits Judith Audu Blog 2014. Accessed 29 October 2014.
  22. Izuzu C. The Last 3 Digits Moses Inwang's movie wins Best International film award Archived 2016-06-10 at the Wayback Machine. Pulse Nigeria Accessed 4 June 2015.
  23. Headies prize giving event Archived 14 August 2012 at the Wayback Machine. Hip Hop World magazine 11 June 2012.
  24. Headies 2014 winners Archived 15 December 2014 at the Wayback Machine. Hip Hop World magazine 2014.
  25. Adunni A. List of Winners Naij.com 14 September 2015. Accessed 14 September 2015
  26. "Don Jazzy honoured with award". Sunnewsonline.com. 8 December 2019. Retrieved 21 October 2021. 
  27. "Burna Boy, Don Jazzy in new single 'Question'" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 24 August 2021. Retrieved 1 September 2021.