Ìbàdàn

olúìlú ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní Nàìjíríà
(Àtúnjúwe láti Ibadan, Naijiria)

Ìbàdàn jẹ́ olú-ìlú Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ìlú Ìbàdàn ni ìlú tí ó tóbí jùlọ ní apá ìwọ̀òrùn Afríkà, bẹ́ẹ̀ sì ni ó jẹ́ olú ìlú ìjọba fún ìpínlè Ọ̀yọ́. Ìbàdàn jẹ́ ilú àwon jagunjagun tí wọ́n dá sílẹ̀ lẹ́yìn tí ìjọba Ọ̀yọ́ Kàtúnga túká nígbà tí Àwọn Fúlàní ṣe ìkọlù sí ìjọba Ọ̀yọ́ nígbà náà. Orúkọ tí wọ́n ń pe ilú yí (Ìbàdàn) ní ó túmọ̀ sí ẹ̀bá ọ̀dàn.

Ìbàdàn
Fọ́rán àwòrán èdè Ilẹ̀ Ìbàdàn
Nickname(s): 
Ile Oluyole
Ìbàdàn is located in Nigeria
Ìbàdàn
Ìbàdàn
Ibùdó ní Naijiria
Coordinates: 7°23′47″N 3°55′0″E / 7.39639°N 3.91667°E / 7.39639; 3.91667Coordinates: 7°23′47″N 3°55′0″E / 7.39639°N 3.91667°E / 7.39639; 3.91667
Orílẹ̀-èdè Naijiria
Ìpínlẹ̀Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́
Government
 • GominaAbiola Ajimobi
 • Alaga, AriwaAdemola Kamil Omotoso
 • Alaga, Ariwa-Ila OorunOlugbenga Ayinde Adewusi
 • Alaga, Ariwa-Iwo OorunAderemi Ayodele
 • Alaga, Guusu-Ila OorunAbiodun Bolarinwa Adedoja
Area
 • Total1,190 sq mi (3,080 km2)
Population
 (2005)
 • Total2,550,593
 • Density2,140/sq mi (828/km2)
 • Metro density600/sq mi (250/km2)
 • Awon eya eniyan
Yoruba
Time zoneUTC+1 (WAT)
Websitehttp://www.oyostate.gov.ng/


Ìtàn Ilẹ̀ Ìbàdàn

àtúnṣe

Ìtàn fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wí pé wọ́n dá ìlú Ìbàdàn sílẹ̀ ní nǹkan bí ọdún 1829 látàrí àwọn ogun àti rògbòdìyàn tí ó ń ṣẹlẹ̀ ní ilẹ̀ Yorùbá nígbà náà. Àsìkò yí ni àwọn ìlú tí wọ́n ṣe pàtàkì ní Ilẹ̀ Yorùbá nígbà náà bíi: Ọ̀yọ́ ilé, Ìjàyè àti Òwu ń kojú ogun lọ́tùn-ún lósì, nígbà tí àwọn ìlú tuntun mìíràn náà ń dìde. Lára àwọn ìlú tí wọ́n ń dìde ni: Abẹ́òkúta, Ọ̀yọ́ Àtìbà àti Ìbàdàn. Ibadan dide lati dípò wọn. Gẹ́gẹ́ bí àwọn onítàn Lágelú tí ó jẹ́ Jagun ìlú Ifẹ̀ ló da Ìbàdàn sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àgọ́ fún àwọn jagunjagun tí wọ́n bá ń bọ̀ láti Ọ̀yọ́, Ifẹ̀ àti Ìjẹ̀bú.[1] NÍ ọdún 1852, àwọn Church Missionary Society rán David àti Anna Hinderer láti tán ìhìnrere àti láti kọ́ ilé ìjọsin ní Ìbàdàn tí wọ́n bá dé ní ọdún 1853. Ibadan bẹ̀rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ìpínlẹ̀ jagunjagun tí ó sì wà bẹ́ẹ̀ títí di ọdún kẹ́wàá tí ó gbẹ̀yìn sẹ́ńtúrì kọkàndínlógún.

Ní ọdún 1893, Ìbàdàn di ìlú àmọ́nà/ìlú tí ó wà lábẹ́ àṣẹ bírítéènì lẹ́yìn tí Fìjàbí tí ó jẹ́ baálẹ̀ ìlú Ìbàdàn fí ọwọ́ sí ìwé àdéhùn pẹ̀lú ẹni tí ó ń ṣe iṣé gómìnà ìlú àmọ́nà George C. Denton ní ọjọ́ Kàrúndínlógún oṣù kẹjọ

Àwọn Bírítéénì ṣe àgbékalẹ̀ ìlú àmọ́nà láti ṣe àkóso ètò ọrọ̀ ajé ní agbègbè Ìbàdàn tí ó ṣí gbòrò láìpẹ́ gbòógì ilẹ̀ ètò ọrọ̀ ajé. Ìlú Ìbàdàn ní ó gba àlejò Ilé ẹ̀kọ́ gíga àkọ́kọ́, Yunifásítì ti Ibadan tí wọ́n kọ́kọ́ dá sílẹ̀ gẹ́gẹ́ kọ́lẹ̀jì tí Yunifásítì Lọ́ńdọ̀nì ni ọdún 1948 tí ó padà di Yunifásítì tí ó dá dúró ní ọdún 1962. Ó wà lára àwọn ilé ẹ̀kọ́ àkọ́kọ́ tí wọ́n dá mọ̀ ní orílẹ̀ Áfíríkà. Àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga mìíran tí ó wà ní ìlú Ìbàdàn ní politẹ́kíníkì ìlú Ibadan, Lead City Yunifásítì, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn ilé ẹ̀kọ́ àkọ́bẹ̀rẹ̀ àti girama náà pọ̀ káàkiri ìlú Ìbàdàn àti agbègbè rẹ̀.

Jíógíráfì

àtúnṣe

Ojúọjọ́

àtúnṣe
Dátà ojúọjọ́ fún Ibadan
Osù Jan Feb Mar Apr May Jun Jul Aug Sep Oct Nov Dec Ọdún
Iye tógajùlọ °C (°F) 37.2
(99)
38.9
(102)
38.3
(100.9)
37.2
(99)
35.0
(95)
33.3
(91.9)
31.7
(89.1)
31.7
(89.1)
35.6
(96.1)
33.3
(91.9)
33.9
(93)
35.6
(96.1)
38.9
(102)
Iye àmúpín tógajùlọ °C (°F) 32.3
(90.1)
34.0
(93.2)
33.5
(92.3)
32.3
(90.1)
31.2
(88.2)
29.6
(85.3)
27.8
(82)
27.2
(81)
28.5
(83.3)
29.7
(85.5)
31.3
(88.3)
31.9
(89.4)
30.8
(87.4)
Iye àmúpín ojojúmọ́ °C (°F) 25.7
(78.3)
26.9
(80.4)
26.9
(80.4)
26.3
(79.3)
25.6
(78.1)
25.1
(77.2)
23.6
(74.5)
23.1
(73.6)
23.9
(75)
24.3
(75.7)
25.6
(78.1)
25.5
(77.9)
25.2
(77.4)
Iye àmúpín tókéréjùlọ °C (°F) 20.9
(69.6)
21.9
(71.4)
22.5
(72.5)
22.0
(71.6)
21.7
(71.1)
21.6
(70.9)
21.2
(70.2)
20.7
(69.3)
21.8
(71.2)
21.7
(71.1)
21.6
(70.9)
20.7
(69.3)
21.5
(70.7)
Iye tókéréjùlọ °C (°F) 10.0
(50)
11.1
(52)
15.0
(59)
18.3
(64.9)
17.8
(64)
17.8
(64)
16.1
(61)
15.6
(60.1)
17.2
(63)
17.8
(64)
15.6
(60.1)
11.1
(52)
10.0
(50)
Iye àmúpín ìrọ̀jò mm (inches) 10
(0.39)
25
(0.98)
91
(3.58)
135
(5.31)
152
(5.98)
188
(7.4)
155
(6.1)
86
(3.39)
175
(6.89)
160
(6.3)
46
(1.81)
10
(0.39)
1,233
(48.54)
Iye àmúpín àwọn ọjọ́ òjò (≥ 0.3 mm) 1 3 7 9 14 17 15 13 18 18 7 1 123
Iye àmúpín ìrì-omi (%) 76 73 77 82 85 87 89 88 88 87 83 79 83
Iye àmúpín wákàtí ìràn òrùn lósooòsù 198.4 197.8 186.0 180.0 195.3 147.0 86.8 65.1 93.0 164.3 207.0 220.1 1,940.8
Iye àmúpín wákàtí ìràn òrùn lójoojúmọ́ 6.4 7.0 6.0 6.0 6.3 4.9 2.8 2.1 3.1 5.3 6.9 7.1 5.3
Source: Deutscher Wetterdienst[2]

Ìjọba

àtúnṣe

Wọ́n pín Ìbàdàn sí àgbègbè ìjọba Ìbílẹ̀ mọ́kànlá. Márùn-ún wà ní ìgboro Ìbàdàn, mẹ́fà yòókù sì wà ní etílé.


Àwọn Agbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀

àtúnṣe

Àwọn àgbègbè ìjọba Ìbílẹ̀ ìgboro ìlú Ìbàdàn

  1. Agbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀ Àríwá Ìbàdàn
  2. Agbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀ Àríwá-Ìlàòrùn Ìbàdàn
  3. Agbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀ Gúúsù-Ìlàòrùn Ìbàdàn
  4. Agbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀ Àríwá-Ìwọòrùn Ìbàdàn
  5. Agbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀ Gúúsù-Ìwọòrùn Ìbàdàn

Àwọn àgbègbè ìjọba Ìbílẹ̀ àyíká etílé Ìbàdàn

  1. Agbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀ Akinyele
  2. Agbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀ Egbeda
  3. Agbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀ Ido
  4. Agbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀ Lagelu
  5. Agbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀ Olúyọ̀lé
  6. Agbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀ Ona Ara

Òkòwò

àtúnṣe

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "Ibadan History" (in en-US). Litcaf. 2016-02-12. https://litcaf.com/ibadan-history/. 
  2. "Klimatafel von Ibadan / Nigeria" (PDF). Baseline climate means (1961-1990) from stations all over the world (in German). Deutscher Wetterdienst. Retrieved 14 July 2016.