Àwọn Ẹ̀gbá
Àwọn Ẹ̀gbá jẹ́ ẹ̀ka ẹ̀yà Yorùbá ní apá Ìwọ̀-oòrùn ilẹ̀ Nàìjíríà, ọ̀pọ̀ nínú wọn ni wọn wá láti àárín ìpínlẹ̀ Ògùn tí í ṣe Ogun Central Senatorial District.
Àpapọ̀ ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́fà ni ó parapọ̀ di Ogun Central Senatorial District ni ìpínlẹ̀ Ògùn. Àwọn wọ̀nyí ni: Agbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀ Àríwá Abẹ́òkúta, Agbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀ Gúúsù Abẹ́òkúta, Agbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀ Ewekoro, Ifo, Obafemi-Owode àti Odeda.
Ìṣẹ̀dálẹ́
àtúnṣeÌpilẹ̀ṣẹ̀ ọ̀rọ̀ Ẹ̀gbá ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àriyànjiyàn nínú. Ìtumọ̀ àkọ́kọ́ rẹ̀ le wáyé látara ọ̀rọ̀ Ẹ̀gbálugbó, tó túmọ̀ sí alárìnkiri rìn sínú igbó. Èyí sì lè jẹ mọ́ ìtàn tó fi yé wa pé àwọn ará Ẹ̀gbá wá láti Ilú-ọba Ọ̀yọ́, sínú igbó Ègbá, tí ó sì bí ìlú Abẹ́òkúta lónìí. Àwọn "Egbalugbo" wà ní ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn Ẹ̀gbáluwẹ tàbí Ẹ̀gbálodó, tí ó túmọ̀ sí alárìnkiri rìn sẹ́bàá odò, tí wọ́n sì padà gẹ́ kúrú sí "Ẹ̀gbádò", èyí tó jẹ́ ẹ̀yà mìíràn ní ilẹ̀ Yorùbá. Ìtumọ̀ mìíràn tó tún rọ̀ mọ́ ìlú Ẹ̀gbá yìí tún le jẹ́ Ẹsẹ̀gbá, èyí tí ń ṣe orúkọ olóyè tó darí àwọn ará Ẹ̀gbá sí agbègbè tí wọ́n wà lọ́wọ́lọ́wọ́.[1][2]
Ìtàn
àtúnṣeÀwọn ọmọ ẹ̀gbá tó fìgbà kan wà lábé Ilú-ọba Ọ̀yọ́ gba òmìnira lẹ́yín tí Ọ̀yọ́ pín ní ìbẹ̀rẹ̀ sẹ́ńtúrì kọkàndínlógún.[3] Ogun tí wọ́n jà pẹ̀lú àwọn ará Dahomey, tí wọ́n sì jẹ́ olúborí latàri ìdábòbò tí wọ́n rí gbà lọ́wọ́ Òkè Olúmọ ló bí ìṣẹ̀dálè ìlú Abẹ́òkúta, èyí tó túnmọ̀ sí "abẹ́ òkuta".
Ẹ̀gbá pín sí ẹ̀ka mélọ̀ó kan, àwọn ni; Ake, Owu, Oke Ona, àti Gbagura, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ló ní ọba tirẹ̀. Lásìkò ìṣèjọba àwọn aláwọ̀ funfun, àwọn aláwọ̀-funfun yìí mọ Alake gẹ́gé bíi olórí gbogbo ìletò tó wà ní Ẹ̀gbá. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, oyè náà ti di oyè Aláké ti ìlú Ẹ̀gbá. Oyè àwọn ọba ẹ̀ka yòókù ní Ẹ̀gbá ni Alake ti ìlú Egba, Osile ti Oke Ona, Agura ti Gbagura, àti Olowu ti Owu.
Ó pọn dandan láti ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ pé ìlú náà wà ní agbègbè òkè Olúmọ tẹ̀lẹ̀, tí ó wà ní agbègbè Ikija/Ikereku ti Oke Ona, ní Ẹ̀gbá. Jagunna ará Itoko, tó jé ọ̀kan lára àwọn olóyè Oke Ona, ni olú-awo òkè Olúmọ.
Ìlú Ègbá ni Henry Townsend fìgbà kan gbé, ibẹ̀ sì ni ilé ìwé-ìròyìn àkọ̀kọ̀ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ìlú yìí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìlú ní Nàìjíríà tó ní orin ìyìn.
Orin ìyìn Ẹ̀gbá
àtúnṣe- Lori oke o'un petele
- Ibe l'agbe bi mi o
- Ibe l'agbe to mi d'agba oo
- Ile ominira
- Egbè: Maa yo, maa yo, maa yo o; l'Ori Olumo; Maa yo, maa yo, maa yo o; l'Ori Olumo
- Abeokuta ilu Egba
- N ko ni gbagbe e re
- N o gbe o l'eke okan mi
- Bii ilu odo oya
- Emi o f'Abeokuta sogo
- N o duro l'ori Olumo
- Maayo l'oruko Egba ooo
- Emi omoo Lisabi
- E e
- Egbè: Maa yo, maa yo, maa yo o; l'Ori Olumo; Maa yo, maa yo, maa yo o; l'Ori Olumo
- Emi o maayo l'ori Olumo
- Emi o s'ogoo yi l'okan mi
- Wipe ilu olokiki o
- L'awa Egba n gbe
- Egbè: Maa yo, maa yo, maa yo o; l'Ori Olumo; Maa yo, maa yo, maa yo o; l'Ori Olumo
Aṣọ ìbílẹ̀
àtúnṣe- Ọkùnrin:
- Bùbá, kẹ̀m̀bẹ̀ tàbí ṣòkòtò
- Bùbá àti Agbádá.
- Fila Abeti Aja.
- Obìnrin:
- Ìró
- Bùbá
- Gèlè
- Ìpèlé (èyí tí wọ́n ń ró mọ́ ìbàdí)
Àwọn ìlú-mọ̀ọ́-ká tó jẹ́ ọmọ Ẹ̀gbá
àtúnṣe- Adegboyega Edun, òjíṣẹ́ Ọlọ́run, olùkọ́, ọ̀gá-àgbà ilé-ìwé àti akọ̀wé fún ẹgbẹ́ àwọn ọmọ Ẹ̀gbá.
- Olóyè M. K. O. Abíọ́lá, oníṣòwò àti olóṣèlú
- Akin Fayomi, afọ̀rọ̀wérò, aṣojú ìjọba sí France, Monaco, àti Liberia.
- Olóyè Olusegun Obasanjo, Ààrẹ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti ọdún 1999 wọ 2007
- Chief Ebenezer Olasupo Obey-Fabiyi, olórin àti ajíhìnrere.
- Olufela Olusegun Oludotun Ransome-Kuti, olórin àti ajà-fẹ́tọ̀ọ́-ọmọnìyàn.
- Olóyè Olufunmilayo Ransome-Kuti, ajà-fẹ́tọ̀ọ́-ọmọnìyàn
- Reverend Oludotun Israel Ransome-Kuti, òjíṣẹ́ Ọlọ́run, olùkọ́ àti ọ̀gá-àgbà ilé-ìwé(láti oṣù kẹrin ọdún 1891 wọ oṣù kẹrin, ọdún 1955)
- Professor Olikoye Ransome-Kuti, ajà-fẹ́tọ̀ọ́-ọmọnìyàn, àti mínísítà fún ètò-ìlera (30 December 1927 – 1 June 2003)
- OlóyèErnest Shonekan, adelé Ààrẹ̀ (26 August 1993 – 17 November 1993)
- Prof. Wole Soyinka, òǹkọ̀wé, ajà-fẹ́tọ̀ọ́-ọmọnìyàn
- Chief F. R. A. Williams S.A.N., adájọ́
- Adewale Oke Adekola, onímọ̀-ẹ̀rọ̀, ọ̀mọ̀wé, òǹkọ̀wé
- Pastor Tunde Bakare, adájọ́ àti Pásítọ̀
- Mr. Kolawole Banmeke
- Tunde Kelani
- Segun Odegbami, afẹ̀yìntì agbábọ́ọ̀lù
- Dimeji Bankole
- Àṣá Bukola Elemide, olórin
- Olu Jacobs, òṣèrékùnrin
- Shina Peters, olórin
- Àyìnlá Ọmọwúrà, olórin
- Prince Bola Ajibola, adájọ́
- Chief Simeon Adebo, adájọ́
- Fela Sowande, olórin
- Olóyè Joseph Okefolahan Odunjo, òǹkọ̀wé gbajúgbajà ìwé Alawiye
- Tunde Lemo, igbákejì gómínà CBN
- John Fashanu, olórin
- Femi Kuti, olórin
- Seun Kuti, olórin
- Made kuti, olórin
- Clarence Peters, adarí fọ́nrán orin
- Ebun Oloyede Olaiya Ebun Oloyede, òṣèré
- Sẹ́netọ̀ Ibikunle Amosun, gómínà Ìpínlẹ̀ Ògùn láti ọdún 2011 wọ 2019
- Olóyè Olusegun Osoba, ònkọ̀wé àti olóṣèlú, gómínà Ìpínlẹ̀ Ògùn láti ọdún 1999 wọ 2003
- Zainab Balogun, òṣèrébìnrin
- Professor Adeoye Lambo, igbákejì Ààrẹ̀ World Health Organization (WHO) nígbà kan rí
- Professor Saburi Biobaku, igbákejì Ààrẹ̀ University of Lagos nígbà kan rí
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Egba:A History". 16 February 2017.
- ↑ Biobaku, S. O. (1952). "An Historical Sketch of Egba Traditional Authorities". Africa: Journal of the International African Institute 22 (1): 35–49. doi:10.2307/1157085. JSTOR 1157085. https://www.jstor.org/stable/pdf/1157085.pdf.
- ↑ "Egba People". LitCaf Encyclopedia. 18 January 2016.