Níyì Akínmọláyàn
Níyì Akínmọláyàn jẹ́ olùgbéré-jáde, adarí eré ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó di ìlú-mòọ́ká látàrí eré kan tí ó darí rẹ̀ tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ The Wedding Party 2, ní èyí tí àwọn òṣèré bíi: Banky Wellington, Adesua Etomi àti Enyinna Nwigwe ti kópa tó lààmì-laaka ní ọdún (2016).[1] Òun ni olùdásílẹ̀ àti adarí ilé-iṣẹ́ Anthill Productions, tí wọ́n ti ń gbé eré ọlọ́kan-ò-jọkan jáde.
Níyì Akínmọláyàn | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 3 Oṣù Kọkànlá 1982 |
Iṣẹ́ | Olùgbéré-jáde, Media Consultant |
Ìgbà iṣẹ́ | 2010–present |
Olólùfẹ́ | Victoria Akujobi |
Website | www.niyiakinmolayan.com |
Ìbẹ̀rẹ̀ ayé rẹ̀
àtúnṣeAkínmọláyàn jẹ́ Yorùbá ọmọ bíbí Ìpínlẹ̀ Òndó ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó kọ́ nípa ìmọ̀ ẹ̀rọ ní ilé-ẹ̀kọ́ gbogbonìṣe ti Yaba College of Technology,[2]
Iṣẹ́ rẹ̀
àtúnṣeAkínmọláyàn kọ́kọ́ ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ olùṣètò àwòrán, alábójútó wẹ́bùsṣmáìtì àti ọmọlẹ́yìn olùgbéré-jáde kan ní ilé-iṣẹ́ Nollywood, láwọn àsìkò yí, ó bẹ̀rẹ̀ sí mọ́ nípa ṣíṣatúnṣe sí fọ́rán fídíò, animéṣàn aafter effect and vissusal effect lọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ̀. [2] Eré tí ó sọọ́ di ìlú-mòọ́ká ni Kájọlà tí wọ́n gbé jàde ní ọdún 2010 ni ó jẹ́ àyẹ̀wò nípa ìlò ìlò Visual edfect láti fi gbé eré jàde, [3] àmọ́ wọ́n gbẹ́sẹ̀ lé eré yí látàrí wípé eré yí lùgbàdì ìlàn òfin ìgbéré jáde .[4] Akinmolayan had set up his production company, Anthill Productions in 2008, which provided the visual effects for the movie Kajola.[3]
Iṣẹ́ rẹ̀ míràn
àtúnṣeNí ọdún 2014, Akínmọláyàn darí eré oníjó kan tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Make a Move, eré tí àwọn òṣèré bíi: Ivie Okujaye, Tina Mba, Beverly Naya, Wale Adebayo, Victor Godfery, Helga Sosthenes and Eno Ekpenyong ti kópa. Wọ́n yan eré náà fún àmì-ẹ̀yẹ 2015 Africa Magic Viewers Choice Awards fún Eré oníṣẹ́ tí peregedé jùlọ.[5]
Ní ọdún 2015, ó tún darí eré kan tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Falling , tí àwọn òṣèré bíi: Adesua Etomi, Desmond Elliot àti Blossom Chukwujekwu ti kópa. Ó tún darí eré Out of Luck tí Linda Ejiofor, Tọpẹ́ Tedela àti Jídé Kòsọ́kọ́ kópa nínú rẹ̀. Eré yí ni ó jẹ́ kí wọ́n yan Akínmọláyàn fún àmì-ẹ̀yẹ ti Adarí eré tó peregedé jùlọ níbi ayẹyẹ amì-ẹ̀yẹ ti 2016 Nigeria Entertainment Award. Níyì gbé eré kan tí ó pè ní Plaything eré tí ó jẹ́ ní ọdún 2016. Wọ́n ṣàfihàn eré yí ní gbọ̀gàn FilmOne IMAX cinema ní Ìpínlẹ̀ Èkó. [6] Nígbà tí ó di ọdún 2017, ó tún gbé eré kan káde tí ó pe àkọ́lé rẹ̀ ní The Arbitration, àwọn òṣèré jànkàn-jànkàn bíi O.C Ukeje ni wọ́n kópa , tí wọ́n sì fara hàn nínú ayẹyẹ Àpèjẹ̀ ọdún eré oníṣe tí ó wáyé ní ìlú Toronto.[7] Ìwúrí àṣeyọrí rẹ̀ lórí eré The Arbitration ni ó mú u gbé eré míràn jáde pẹ̀lú Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ilé-iṣẹ́ FrieslandCampina WAMCO Nigeria Plc, ni ó fi gbé eré "Adventures of Lola and Chuchu" jáde ní ọdún 2017. [8]
Àwọn àṣàyàn eré rẹ̀
àtúnṣeỌdún | Àkọ́lé | Àwọn olùkópa | Ipa tí wọ́n kó | Àríwísí |
---|---|---|---|---|
2010 | Kajola | Keira Hewatch, Desmond Elliot, Adonijah Owiriwa | Adarí | Feature Film |
2014 | Make a Move | Ivie Okujaye, Tina Mba, Beverly Naya, Wale Adebayo, Victor Godfery, Helga Sosthenes and Eno Ekpenyong | Adarí | Feature film; nominated for the 2015 Africa Magic Viewers Choice Awards for Best Movie (Drama) |
2015 | Falling | Adesua Etomi, Desmond Elliot and Blossom Chukwujekwu | Adarí | Feature Film |
2016 | Plaything | Executive Producer | 3D animated Short film | |
2017 | The Arbitration | OC Ukeje, Adesua Etomi, Iretiola Doyle and Somkele Iyamah | Adarí | Feature Film, available on Netflix |
2017 | The Wedding Party 2 | Banky Wellington, Adesua Etomi, Iretiola Doyle, Richard Mofe-Damijo, Patience Ozokwor, Enyinna Nwigwe | Adarí | Feature Film |
2017 | Adventures of Lola and Chuchu | Adarí | 3D animated series - 13 episodes | |
2018 | Chief Daddy | Taiwo Obileye, Joke Silva, Rachel Oniga and Funke Akindele | Adarí | Feature film |
We Don't Live Here Anymore | Osas Ighodaro, Omotunde Adebowale David, Francis Sule, Temidayo Akinboro, Funlola Aofiyebi, Katherine Obiang | Editor | Feature film | |
2019 | The Set Up | Adesua Etomi, Kehinde Bankole, Joke Silva, Jim Iyke, Dakore Egbuson, Tina Mba | Adarí | Feature film |
Elevator Baby | Toyin Abraham, Timini Egbuson, Yemi Solade, Sambasa Nzeribe, Broda Shaggi | Executive producer | Feature film | |
2021 | Prophetess | Toyin Abraham, Kehinde Bankole, Stan Nze, Waliu Fagbemi, Deyemi Okanlawon | Adarí, writer | Sports comedy film |
Progressive Tailors Club | Beverly Osu, Uzor Arukwe, Funnybone, and Blessing Jessica Obasi | Producer | Satirical film | |
2023 | Mikolo | Pamilerin Ayodeji, Fiyinfoluwa Asenuga, Yvonne Jegede, Ayo Mogaji, Daniel Etim Effiong, Femi Adebayo | Adarí, screenwriter | Family fantasy adventure film (on Amazon Prime) |